Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ṣé àwọn èèyàn ló dá ẹ̀sìn sílẹ̀?
ÀWỌN KAN GBÀ GBỌ́ PÉ àwọn èèyàn ló bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ẹ̀sìn; àwọn míì sì gbà pé Ọlọ́run máa ń lo ẹ̀sìn láti fa àwọn èèyàn sún mọ́ ara rẹ̀. Kí lèrò rẹ?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí.” (Jákọ́bù 1:27) Èyí fi hàn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìjọsìn tí ó mọ́ ti wá.
KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?
Kí ìsìn kan tó lè múnú Ọlọ́run dùn, ó gbọ́dọ̀ gbé ẹ̀kọ́ rẹ̀ lórí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.—Jòhánù 4:23, 24.
Ẹ̀sìn tí wọ́n bá gbé karí èrò èèyàn kì í ṣe ẹ̀sìn gidi. —Máàkù 7:7, 8.
Ṣé ó pọndandan kéèyàn wà nínú ìsìn kan?
KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?
Bẹ́ẹ̀ ni
Bẹ́ẹ̀ kọ́
Mi ò mọ̀
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.” (Hébérù 10:24, 25) Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa pé jọ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan tó wà létòletò.
KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?
Ìgbàgbọ́ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn kan náà gbọ́dọ̀ bára mu.—1 Kọ́ríńtì 1:10, 11.
Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ ará kan tó kárí ayé.—1 Pétérù 2:17.