BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Inú Mi Kì Í Dùn, Mo Sì Máa Ń Hùwà Ìpáǹle
-
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1974
-
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: MẸ́SÍKÒ
-
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO MÁA Ń JÀ, MO SÌ Ń HÙWÀ ÌPÁǸLE NÍGBÀ TÍ MO WÀ LỌ́DỌ̀Ọ́
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú Ciudad Mante ní ìpínlẹ̀ Tamaulipas, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni wọ́n bí mi sí, àgbègbè yìí sì rẹwà. Àwọn aráàlú yìí lawọ́, wọ́n sì máa ń ṣoore. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé àwọn ọ̀daràn ti mú kí àdúgbò yìí léwu gan-an.
Nínú ọmọ ọkùnrin mẹ́rin tí àwọn òbí mi bí, èmi ni wọ́n bí ṣèkejì. Àwọn òbí mi mú kí n ṣèrìbọmi ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, mo sì di ọ̀kan lára ẹgbẹ́ akọrin wọn nígbà tó yá. Ó wù mí kí n ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ torí mi ò fẹ́ kó dá mi lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì títí láé.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún márùn-ún, bàbá mi filé sílẹ̀. Èyí bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an. Mi ò mọ ìdí tí wọ́n fi fiwá sílẹ̀ torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Èyí mú kí màmá mi máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ níta, kó lè gbọ́ bùkátà wa.
Àyè wá ṣí sílẹ̀ fún mi láti máa sá ní ilé-ìwé, kí n lè máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ tó dàgbà jù mí lọ. Ibẹ̀ ni mo ti kọ́ àṣàkaṣà, bíi èébú, sìgá mímú, olè àti ìjà. Torí pé mo fẹ́ràn kí n máa jẹ gàba láwọn èèyàn lórí, mo wá kọ́ oríṣiríṣi ìjà àti bí mo ṣè lè lo àwọn ohun ìjà. Bí mo ṣe di oníjàgídíjàgan láti kékeré nìyẹn. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń fi ìbọn jà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀jẹ̀ máa ń bò mí, tí màá sì sùn gbalaja bí òkú sẹ́gbẹ̀ẹ́ títí. Inú ìyá mi máa ń bàjẹ́ gan-an tó bá rí mi nírú ipò yìí, tó sì gbé mi dìgbàdìgbà lọ sílé ìwòsàn.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], ọ̀rẹ́ mi kan tá a jọ ṣe kékeré, tó ń jẹ́ Jorge wá kí mi nílé. Ó sọ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun àti pé òun máa fẹ́ láti sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan fún wa. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé àwọn ohun tó gbà gbọ́ fún wa nìyẹn látinú Bíbélì. Mi ò ka Bíbélì rí, inú mi sì dùn nígbà tí mo rí orúkọ Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Jorge sọ pé òun á kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A sì gbà.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Ńṣe lara tù mí nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì pé kò sí ọ̀run àpáàdì. (Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5) Àtìgbà yẹn ni mi ò ti bẹ̀rù pé Ọlọ́run máa dá mi lóró mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo wá gbà pé Ọlọ́run jẹ́ Baba tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tó sì fẹ́ kí nǹkan dáa fún wọn.
Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí i pé ó yẹ kí n yí ìwà mi pa dà. Ó yẹ kí n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kí n sì jáwọ́ nínú ìwà ìpáǹle. Ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:33 ló ràn mí lọ́wọ́. Ó sọ pé “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” Mo wá rí i pé àfi kí n fòpin sí àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn tí mò ń bá rìn tẹ́lẹ̀, kí n tó lè yíwà mi pa dà sí dáadáa. Torí náà, mo fi àwọn ará ìjọ Kristẹni tòótọ́ rọ́pò àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ní tẹ́lẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ tuntun yìí máa ń fi àwọn ìlànà Bíbélì yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé láàárín wọn dípò tí wọ́n á fi máa yọ ẹ̀ṣẹ́ síra wọn bíi tàwọn ọ̀rẹ́ tí mò ń kó tẹ́lẹ̀.
Ẹsẹ Bíbélì míì tó tún ṣiṣẹ́ fún mi ni Róòmù 12:17-19. Ó kà pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, . . . nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘ “Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’ ” Mo wá gbà pé Jèhófà máa wá ojútùú sí ìwà ìrẹ́jẹ fúnra rẹ̀, bó ṣe fẹ́ àti ní àsìkò tiẹ̀. Díẹ̀díẹ̀, mo jáwọ́ nínú ìwà ìpáǹle.
Mi ò ní gbà gbé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí mò ń pa dà sílé. Àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ẹgbẹ́ tó máa ń bá wa jà tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ mi. Bí olórí wọn ṣe gbá mi látẹ̀yìn nìyẹn, ó sì ń pariwo pé, “Ó yá, bá wa jà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo gbàdúrà nínú ọkàn mi sí Jèhófà pé kó jẹ kí n lè fara dà á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣe mí bíi kí n ṣe tèmi pa dà, ńṣe ni mo rọra fi wọ́n sílẹ̀. Lọ́jọ́ kejì mo rí olórí wọn yìí lóun nìkan. Ó ṣe mí bíi kí n gbẹ̀san lára ẹ̀, àmọ́ mo tún bẹ Jèhófà pé kí n lè ní sùúrù. Sí ìyàlẹ́nu mi, ọkùnrin yìí sún mọ́ mi, ó ní: “Dárí jì mí fún ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ àná. Ó wu èmi náà kí n máa ṣe bíi tìẹ. Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Inú mi mà dùn o pé mí ò ti lọ faraya tẹ́lẹ̀! Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ nìyẹn.
Ó ṣeni láàánú pé àwọn ará ilé mí tó kù ò tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nígbà yẹn. Àmọ́, mo pinnu pé màá máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi lọ, mi ò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun dá mi dúró. Mo mọ̀ pé bí mo ṣe ń bá àwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé máa tù mí nínú, á sì fún mi ní ìdílé tí mo fẹ́. Mò ń tẹ̀ síwájú, ọdún 1991 ni mo ṣèrìbọmi, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Tẹ́lẹ̀ inú mi kì í dùn, mo fẹ́ràn kí n máa jẹ gàba lé àwọn èèyàn lórí, mo sì ń hùwà ìpáǹle. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti yí ìgbésí ayé mi pa dà sí rere. Báyìí, mò ń sọ̀rọ̀ àlááfíà tó wà nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn tó bá fẹ́ gbọ́. Ó ti di ọdún mẹ́tàlélógún [23] báyìí tí mo ti ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù.
Nígbà kan, mo yọ̀ǹda ara mi láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé Claudia obìnrin àtàtà, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1999. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fi obìnrin olóòótọ́ yìí jíǹkí mi!
A jọ sìn ní ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Nígbà tó yá, wọ́n ní ká lọ sí orílẹ̀-èdè Belize láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní ọ̀pọ̀ nǹkan, síbẹ̀ a ní ohun tó ń fún wa láyọ̀. Kò sì sí ohun tá a lè fi rọ́pò rẹ̀.
Nígbà tó yá, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Bákan náà, ẹ̀gbọ́n mi àgbà, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀, tí mo wàásù fún ti ń sin Jèhófà báyìí.
Ó dùn mi pé àwọn kan lára àwọn ẹbí mi ti kú torí pé wọn ò fi ìwà jàgídíjàgan sílẹ̀. Tó bá jẹ́ pé èmi náà ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe kémi náà ti kú. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fà mí sọ́dọ̀ rẹ̀ àtàwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀, wọ́n fara balẹ̀ kọ́ mi láwọn ìlànà Bíbélì tó tún ìgbésí ayé mi ṣe.