BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN
Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ọkàn Gbogbo Èèyàn Máa Balẹ̀
Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀ ohun tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn. A ò lágbára láti yanjú gbogbo ohun tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn. Àmọ́ Ẹlẹ́dàá wa lè yanjú ẹ̀. Kódà, ó ti yan ẹnì kan tó máa ràn wá lọ́wọ́. Jésù Kristi ni ẹni náà. Láìpẹ́, ó máa ṣe àwọn ohun ìyanu tó máa ju gbogbo ohun tó ṣe nígbà tó wá sáyé lọ, kárí ayé sì ni. Bí àpẹẹrẹ:
JÉSÙ FI HÀN PÉ ÒUN MÁA MÚ ÀWỌN ALÁÌSÀN LÁRA DÁ.
Wọ́n “gbé gbogbo àwọn tí onírúurú àìsàn ń ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀ . . . , ó sì wò wọ́n sàn.”—MÁTÍÙ 4:24.
JÉSÙ MÁA PÈSÈ ILÉ ÀTI OÚNJẸ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN.
“Wọ́n [àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba Kristi] á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn. Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé, wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ.” —ÀÌSÁYÀ 65:21, 22.
ÌJỌBA JÉSÙ MÁA MÚ ÀLÀÁFÍÀ ÀTI ÀÀBÒ WÁ KÁRÍ AYÉ.
“Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀, àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀ títí òṣùpá kò fi ní sí mọ́. Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun àti láti Odò dé àwọn ìkángun ayé. . . . Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò sì lá erùpẹ̀.” —SÁÀMÙ 72:7-9.
JÉSÙ MÁA MÚ ÌRẸ́JẸ KÚRÒ.
“Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà, yóò sì gba ẹ̀mí àwọn tálákà là. Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”—SÁÀMÙ 72:13, 14.
JÉSÙ TÚN MÁA MÚ ÌYÀ ÀTI IKÚ PÀÁPÀÁ KÚRÒ.
“Ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—ÌFIHÀN 21:4.