Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?

Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?

Àìbalẹ̀ ọkàn ni ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ara èèyàn bá fẹ́ kojú ewu tàbí ìpèníjà. Ọpọlọ èèyàn á mú kí èròjà kan tú jáde lọ sínú gbogbo ara. Èyí máa ń mú kí ọkàn máa yára lù kìkì, á sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ru sókè ní ìwọ̀n tó yẹ, á mú kí ẹ̀dọ̀fóró tóbi sí i tàbí kó sún kì, gbogbo iṣan ara á wá le. Kéèyàn tó mọ̀, ara ẹ̀ ti ṣe tán láti kojú ewu tàbí ìpèníjà náà. Tí ohun tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn náà bá ti lọ, ara èèyàn á wálẹ̀, á sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.

ÀÌBALẸ̀ ỌKÀN TÓ DÁA ÀTÈYÍ TÍ Ò DÁA

Àìbalẹ̀ ọkàn jẹ́ ọ̀nà tí ara èèyàn máa ń gbà kojú ewu tàbí ìpèníjà. Inú ọpọlọ ni àìbalẹ̀ ọkàn ti ń bẹ̀rẹ̀. Àìbalẹ̀ ọkàn tó mọ níwọ̀n máa ń mú kára èèyàn tètè ṣiṣẹ́. Àìbalẹ̀ ọkàn tó mọ níwọ̀n tún lè jẹ́ kéèyàn lé àfojúsùn rẹ̀ bá tàbí kéèyàn ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ kan. Ó lè jẹ́ nínú ìdánwò ilé ẹ̀kọ́, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò níbi téèyàn ti ń wáṣẹ́ tàbí nínú ìdíje eré ìdárayá.

Àmọ́, tí àìbalẹ̀ ọkàn bá lágbára gan-an, tí kò sì lọ bọ̀rọ̀, ó lè ṣàkóbá fún ẹ. Tí àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara bá ti pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ara rẹ á kọ̀ ọ́, inú lè máa bí ẹ, o ò sì ní lè ronú dáadáa mọ́. Ìwà rẹ lè yí pa dà, o sì lè máa kanra mọ́ àwọn èèyàn. Àìbalẹ̀ ọkàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ tún lè mú kéèyàn máa lo oògùn nílòkulò tàbí kó máa ṣe àwọn nǹkan míì tó lè pa á lára. Ó tiẹ̀ tún lè mú kéèyàn ní ìdààmú ọkàn, kó máa rẹni tẹnutẹnu tàbí kéèyàn máa ronú láti pa ara rẹ̀.

Bí àìbalẹ̀ ọkàn ṣe máa ń rí lára kálukú wa yàtọ̀, síbẹ̀ ó lè yọrí sí oríṣiríṣi àìsàn, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀yà ara wa ló lè ṣàkóbá fún.