Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 2 2017 | Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Agbára Abàmì

Àwọn eré oṣó, àjẹ́ àti àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀ ló kún orí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fíìmù báyìí.

Kí ni èrò yín nípa ẹ̀? Ṣé ẹ rò pé eré lásán ni wọ́n àbí wọ́n léwu?

Ìwé ìròyìn “Jí!” yìí sọ ohun tó mú kí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí agbára abàmì àti òótọ́ tó yẹ ká mọ̀ nípa rẹ̀.

 

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Agbára Abàmì Ń Pọ̀ Sí I!

Àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú oṣó, àjẹ́, àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, emèrè àtàwọn ẹ̀mí àìrí mí ì ló wá pọ̀ níta báyìí. Kí ló fàá táwọn èèyàn fi ń nífẹ̀ẹ́ sírú àwọn nǹkan yìí?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ẹ̀mí Òkùnkùn?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣiyèméjì bóyá ẹgbẹ́ awo àti agbára abàmì léwu àbí kò léwu, Bíbélì ò fi ọ̀rọ̀ yìí ṣeré rárá. Kí wá ni ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ẹ̀, kí sì nìdí tó fi sọ ohun tó sọ?

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ọgbọ́n Tí Oyin Fi Ń Bà Lé Nǹkan

Kí ló mú kí ọgbọ́n tí oyin fi ń bà lé nǹkan láìfarapa wúlò fún àwọn tó ń ṣe rọ́bọ́ọ̀tì tó ń fò?

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Nígbà Tí Òbí Ẹnì Kan Bá Kú

Ohun tí kò bára dé ni kí èèyàn pàdánù òbí ẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn náà kì í sì kúrò lọ́kàn bọ̀rọ̀. Kí ló lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti tètè gbé ìbànújẹ́ náà kúrò lọ́kàn?

Tí Òbí Ọmọdé Kan Bá Kú

Báwo ni Bíbélì ṣe ran àwọn ọmọ mẹ́ta kan lọ́wọ́ láti fara da ìbànújẹ́ tí ikú mọ̀lẹ́bí wọn fà?

ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN

Ìbẹ̀wò sí Orílẹ̀-Èdè Sípéènì

Onírúurú nǹkan ló wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì, látorí àwọn èèyàn títí dorí ilẹ̀ wọn. Irú oúnjẹ kan wà tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè Sípéènì àmọ́ tí kò sí lórílẹ̀-èdè mí ì lágbàáyé.

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Àgbélébùú

Àmì ẹ̀sìn Kristẹni ni ọ̀pọ̀ èèyàn ka àgbélébùú sí. Ṣé orí àgbélébùú ni Jésù kú sí? Ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wọn?

Ṣé Ó Wù Ẹ́ Kó O Mọ Bíbélì Dáadáa?

Kà nípa àwọn ohun tó o nílò àti àwọn ohun tí kò pọn dandan kó o ní tí o bá fẹ́ ní òye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Àjálù Bá Dé Bá Mi?

Àwọn ọ̀dọ́ kan sọ ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Wà?

Àwọn wo ni ẹ̀mí èṣù? Ibo ni wọ́n ti wá?