Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Ọgbọ́n Tí Oyin Fi Ń Bà Lé Nǹkan
KÒKÒRÒ oyin lè bà sí ibikíbi láìfarapa. Báwo ló ṣe ń ṣe é?
Rò ó wò ná: Kí kòkòrò oyin tó lè bà lé nǹkan láìfarapa, ó gba pé kó dín eré tó fi ń fò bọ̀ kù gan-an. Ohun méjì ló máa ń ṣe. Àkọ́kọ́ ni pé ó máa wo bó ṣe yẹ kó sáré tó. Ìkejì ni pé ó máa ń fojú díwọ̀n ibi tó fẹ́ bà lé. Á wá dín eré rẹ̀ kù níwọ̀n tó yẹ. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo kòkòrò ló lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọn ò lè fójú díwọ̀n bí nǹkan ṣe jìnnà tó.
Ojú oyin tún yàtọ̀ sí tàwa èèyàn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwa èèyàn lè mọ bí nǹkan ṣe tóbi tó níbikíbi tá a bá dúró sí, àmọ́ ní ti àwọn oyin bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ nǹkan ni ohun náà á máa tóbi sí i lójú wọn. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe ní Australian National University fi hàn pé bí oyin bá fẹ́ bà lé nǹkan, ó máa ń dín eré rẹ̀ kù, kó lè mọ bí nǹkan náà ṣe tóbí sí bó ṣe ń sún mọ́ ọn. Tó bá fi máa fò débẹ̀, eré yẹn á ti dín kù pátápátá kó lè balẹ̀ láìfarapa.
Ìwé Proceedings of the National Academy of Sciences ròyìn pé: “Ọgbọ́n tí oyin ń dá tó fi ń bà lé nǹkan láìfarapa yìí . . . [lè] ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe rọ́bọ́ọ̀tì tó ń fò.”
Kí lèrò rẹ? Ṣé ọgbọ́n tí oyin fi ń bà lé nǹkan yìí kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?