Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdáríjì ló lè paná ìjà

TỌKỌTAYA

4: Ìdáríjì

4: Ìdáríjì

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Ìdáríjì kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé ká fojú kéré ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa tàbí ká ṣe bíi pé ẹni náà kò ṣẹ̀ wá rárá. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká gbójú fo gbogbo àìdáa tẹ́ni náà ṣe sí wa, ká má sì bínú sí i mọ́.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”​—Kólósè 3:13.

“Téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan lóòótọ́, ó yẹ kó lè gbójú fo àwọn àṣìṣe onítọ̀hún, kó sì mọyì bí ẹni náà ṣe ń gbìyànjú láti sunwọ̀n sí i.”​—Aaron.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Téèyàn bá ń di ẹlòmíì sínú, ó lè fa àìsàn síni lára, ó sì lè kó ìrònú báni, tó bá sì jẹ́ pé ọkọ àti ìyàwó ló ń di ara wọn sínú, ó lè da ìgbéyàwó wọn rú.

“Ìgbà kan wà tí ọkọ mi ṣe ohun tó dùn mí gan-an, ó sì bẹ̀ mí pé kí n má bínú. Ó kọ́kọ́ ṣòro fún mi láti dárí jì í, àmọ́ mo pa dà dárí jì í. Mo kábàámọ̀ pé mi ò tètè dàrí jì í, torí pé bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe ń pẹ́ sí náà ni nǹkan ń le sí i làárín wa.”​—Julia.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

DÁN ARA RẸ WÒ

Tí ẹnì kejì rẹ bá ṣe ohun kan tàbí ó sọ̀rọ̀ kan tó bí ẹ nínú, bi ara rẹ pé:

  • ‘Ṣé ọ̀rọ̀ yìí le tó bí mo ṣe ń rò ó?’

  • ‘Ṣé ọ̀rọ̀ náà le débi pé àfi dandan kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ mi, àbí ohun tí mo lè gbójú fò ni?’

Ẹ BÁ ARA YÍN SỌ̀RỌ̀

  • Sé a máa ń tètè dárí ji ara wa?

  • Kí la lè ṣe táá mú ká tètè máa dárí ji ara wa?

ÀBÁ

  • Tí ẹnì kejì rẹ bá ṣẹ̀ ẹ́, má ṣe ronú pé ó ti ní èrò tí kò dáa sí ẹ tẹ́lẹ̀.

  • Tí ẹnì kejì rẹ bá ṣe nǹkan tó dùn ẹ́, má ṣe tètè gbà á sí ìbínú, rántí pé “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.”​—Jákọ́bù 3:2.

“Ó máa ń rọrùn láti dárí ji ara wa tó bá jẹ́ pé àwa méjéèjì la jẹ̀bi, àmọ́ kì í rọrùn tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ló jẹ̀bi. Ká sòótọ́, téèyàn ò bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kò ní lè dárí jini tàbí tọrọ àforíjì.”​—Kimberly.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá.”​—Mátíù 5:25.

Téèyàn bá ń di ẹlòmíì sínú, ó lè fa àìsàn síni lára, ó sì lè kó ìrònú báni, tó bá sì jẹ́ pé ọkọ àti ìyàwó ló ń di ara wọn sínú, ó lè da ìgbéyàwó wọn rú