Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé Róòmù orí kejìlá ẹsẹ ìkọkàndínlógún pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú,” ṣé ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ bínú?
Ká kúkú sọjú abẹ́ níkòó, ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn. Ìrunú Ọlọ́run ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí níhìn-ín. Àmọ́, kò wá túmọ̀ sí pé bí Kristẹni kan bá tiẹ̀ fàbínú yọ kò já mọ́ nǹkankan o. Bíbélì kìlọ̀ fún wa ní kedere pé ká yàgò fún ìrunú. Gbé àwọn ìmọ̀ràn àtọ̀runwá bíi mélòó kan yẹ̀ wò.
“Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sáàmù 37:8) “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a lọ ní kíkún fún ìrunú sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́.” (Mátíù 5:22) “Àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú.” (Gálátíà 5:19, 20) “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Síwájú sí i, léraléra ni ìwé Òwe gbà wá nímọ̀ràn lórí rírunú tàbí fífa ìbínú yọ lórí àwọn àṣìṣe kéékèèké àti àwọn ìkùdíẹ̀ káàtó ẹ̀dá ènìyàn.—Òwe 12:16; 14:17, 29; 15:1; 16:32; 17:14; 19:11, 19; 22:24; 25:28; 29:22.
Àyíká ọ̀rọ̀ ìwé Róòmù orí kejìlá, ẹsẹ ìkọkàndínlógún bá irú àwọn ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ mu. Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa ni pé kí a jẹ́ kí ìfẹ́ wa jẹ́ èyí tí kò ní àgàbàgebè, kí a máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wa, kí a gbìyànjú láti máa ro ire àwọn ẹlòmíràn, kí a má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan, kí a sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ó wá rọni pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”—Róòmù 12:9, 14, 16-19.
Dájúdájú, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbínú sún wa láti fi ìgbónára gbẹ̀san. Ìmọ̀ táa ní nípa bípò nǹkan ṣe rí àti ọgbọ́n táa ní láti dáni lẹ́jọ́ jẹ́ ti aláìpé. Táa bá jẹ́ kí ìbínú sún wa débi tí ara wa wá gbóná sódì, ọ̀pọ̀ ìgbà la ó máa ṣe àṣìṣe. A ó wá jẹ́ kí inú Èṣù máa dùn, ẹni tó jẹ́ Elénìní Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé níbòmíràn pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.”—Éfésù 4:26, 27.
Ohun tó dára jù, tó sì bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé kí a jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ pinnu ìgbà tí òun ó gbẹ̀san àti ẹni tí òun ó gbẹ̀san lára rẹ̀. Òun lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa ọ̀ràn náà, ẹ̀san èyíkéyìí tó bá sì san padà yóò fí hàn pé pípé ni ìdájọ́ òdodo rẹ̀. A lè rí i pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú Róòmù orí kejìlá ẹsẹ ìkọkàndínlógún nìyí, nígbà táa bá kíyè sí ibi tí atọ́ka rẹ̀ wà nínú Diutarónómì orí kejìlélọ́gbọ̀n, ẹsẹ ìkarùndínlógójì àti ìkọkànlélógójì, tó ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú pé: “Tèmi ní ẹ̀san, àti èrè iṣẹ́.” (Fi wé Hébérù 10:30.) Nípa bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohun tó jọ gbólóhùn náà “ti Ọlọ́run” nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti Gíríìkì, àwọn bíi mélòó kan lára àwọn atúmọ̀ èdè lóde òní ti fi wọ́n kún Róòmù orí kejìlá ẹsẹ ìkọkàndínlógún, tó wá jẹ́ kí ó kà pé, “jẹ́ kí Ọlọ́run gbẹ̀san” (The Contemporary English Version); “ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run” (American Standard Version); “ẹ jẹ́ kí Ọlọ́run jẹni níyà tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀” (The New Testament in Modern English); “ẹ fàyè sílẹ̀ fún ẹ̀san ti Ọlọ́run.”—The New English Bible.
Kódà nígbà tí àwọn ọ̀tá òtítọ́ bá ń bú wa, tàbí tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àpèjúwe tí Mósè gbọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, ṣùgbọ́n lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà.”—Ẹ́kísódù 34:6, 7.