Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé Úrì ni Jèhófà ti bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú tàbí Háránì?

Àkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ pàá nípa májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá ni èyí tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3, tó kà pé: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Ábúrámù pé: ‘Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́; èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ . . . Gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ yóò sì bù kún ara wọn dájúdájú nípasẹ̀ rẹ.’” a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Ábúráhámù wà ní Úrì ni Jèhófà bá a dá májẹ̀mú yìí, tó sì wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà tí Ábúráhámù wà ní Háránì.

Ní ọ̀rúndún kìíní, Sítéfánù tọ́ka sí àṣẹ tí Jèhófà pa pé kí Ábúráhámù ṣí lọ sí Kénáánì. Nígbà tó sì ń bá Sànhẹ́dírìn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọlọ́run ògo fara han Ábúráhámù baba ńlá wa nígbà tí ó wà ní Mesopotámíà, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì, ó sì wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’” (Ìṣe 7:2, 3) Ilẹ̀ Úrì gan-an ni Ábúráhámù ti wá, ibẹ̀ ló sì ti kọ́kọ́ gbọ́ àṣẹ tó sọ pé kó lọ sí Kénáánì, gẹ́gẹ́ bí Sítéfánù ṣe sọ ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 15:7; Nehemáyà 9:7) Sítéfánù kò mẹ́nu kan májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá, àmọ́ nínú Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3, a mẹ́nu kan májẹ̀mú yẹn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àṣẹ tó sọ pé kó lọ sí Kénáánì. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé Úrì ni Jèhófà ti bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú náà.

Àmọ́, tá a bá fara balẹ̀ ka ìtàn inú Jẹ́nẹ́sísì dáadáa, a óò rí i pé ó dà bíi pé Jèhófà tún májẹ̀mú rẹ̀ sọ fún Ábúráhámù ní Háránì, gẹ́gẹ́ bí ó ti tún un sọ, tó sì fi àwọn nǹkan kan kún un láwọn ìgbà bíi mélòó kan ní Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5; 17:1-5; 18:18; 22:16-18) Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 11:31, 32 ti wí, Térà, baba Ábúráhámù, fi Úrì sílẹ̀ lọ sí Kénáánì, Ábúráhámù, Sárà, àti Lọ́ọ̀tì sì tẹ̀ lé e lọ. Wọ́n wá sí Háránì, wọ́n sì dó síbẹ̀ títí dìgbà tí Térà fi kú. Àkókò tí Ábúráhámù lò ní Háránì gùn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi ṣeé ṣe fún un láti kó ọ̀pọ̀ ọrọ̀ jọ. (Jẹ́nẹ́sísì 12:5) Nígbà tó sì tó àkókò kan, Náhórì, arákùnrin Ábúráhámù, náà tún kó wá síbẹ̀.

Lẹ́yìn àkọsílẹ̀ nípa ikú Térà, Bíbélì ròyìn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Ábúráhámù sọ, ó sì ń bá a lọ pé: “Látàrí ìyẹn, Ábúrámù lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún un.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:4) Nítorí náà, Jẹ́nẹ́sísì 11:31–12:4 jẹ́ kó dà bíi pé ẹ̀yìn ikú Térà ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Ábúráhámù kúrò ní Háránì, ó sì ṣí lọ sí ilẹ̀ tí Jèhófà ní kó ṣí lọ, ní ṣíṣègbọràn sí àṣẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́, ní àfikún sí èyí tó ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ ní Úrì ní ọdún mélòó kan ṣáájú ìyẹn.

Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 12:1 ti wí, Jèhófà pàṣẹ fún Ábúráhámù pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ.” Ìgbà kan wà tí Úrì jẹ́ “ilẹ̀” Ábúráhámù, tí “ilé” baba rẹ̀ sì wà níbẹ̀. Àmọ́, baba Ábúráhámù wá kó agbo ilé rẹ̀ lọ sí Háránì, ibẹ̀ sì ni Ábúráhámù wá ń pè ní ìlú òun. Lẹ́yìn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún ní Kénáánì, ó rán ìríjú rẹ̀ lọ sí ‘ilẹ̀ rẹ̀ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ̀’ pé kí ó lọ wá aya fún Ísákì, ìríjú náà sì lọ sí “ìlú ńlá ti Náhórì” (yálà Háránì tàbí ibì kan nítòsí). (Jẹ́nẹ́sísì 24:4, 10) Ibẹ̀ ni ìríjú náà ti rí Rèbékà láàárín àwọn ìbátan Ábúráhámù, ìyẹn nínú ìdílé ńlá ti Náhórì.—Jẹ́nẹ́sísì 22:20-24; 24:15, 24, 29; 27:42, 43.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù bá Sànhẹ́dírìn sọ, ó sọ nípa Ábúráhámù pé: “Lẹ́yìn tí baba rẹ̀ kú, Ọlọ́run mú kí ó yí ibùgbé rẹ̀ padà sí ilẹ̀ yìí tí ẹ ń gbé nísinsìnyí.” (Ìṣe 7:4) Èyí fi hàn pé Jèhófà bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ ní Háránì. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé àkókò yẹn ni Jèhófà tún májẹ̀mú rẹ̀ sọ fún Ábúráhámù, báa ṣe ròyìn rẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbà tí Ábúráhámù ṣí wá sí Kénáánì ni májẹ̀mú náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Nítorí ìdí èyí, ṣíṣàgbéyẹ̀wò gbogbo kókó wọ̀nyí lè sún wa parí ọ̀rọ̀ náà sí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Úrì ni Jèhófà ti bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú rẹ̀, kó sì wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní Háránì.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jèhófà yí orúkọ Ábúrámù padà sí Ábúráhámù ní Kénáánì nígbà tí Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún.—Jẹ́nẹ́sísì 17:1, 5.