Akitiyan Láti Tẹ Bíbélì Jáde Lédè Gíríìkì Òde Òní
Akitiyan Láti Tẹ Bíbélì Jáde Lédè Gíríìkì Òde Òní
Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé títúmọ̀ Bíbélì sí èdè tí gbogbo èèyàn ń sọ ti jẹ́ ìjàkadì ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó sì lágbára gan-an nílẹ̀ Gíríìsì, ìyẹn orílẹ̀-èdè tí wọ́n máa ń pè, nígbà mìíràn, ní ibi tí ìmọ́lẹ̀ òmìnira ìrònú ti mọ́ wá. Àmọ́ ta ló fẹ́ sọ pé kí wọ́n má tẹ Bíbélì èdè Gíríìkì tó rọrùn láti lóye jáde? Kí ló lè mú kí ẹnì kan sọ pé òun fẹ́ dá iṣẹ́ yìí dúró?
ẸNÌ kan lè ronú pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ làwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì ní, nítorí pé apá púpọ̀ lára Ìwé Mímọ́ la fi èdè wọn kọ níbẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, èdè Gíríìkì òde òní yàtọ̀ pátápátá sí èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ ìtumọ̀ Septuagint ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sì yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n fi kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ká sọ tòótọ́, láti ohun tó lé ní ọ̀rúndún mẹ́fà sẹ́yìn ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì ti rí i pé bí ẹní ń ka èdè àjèjì ni Bíbélì èdè Gíríìkì ṣe rí lójú àwọn. Àwọn ọ̀rọ̀ tuntun ti rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àkànlò èdè, gírámà, àti gbólóhùn ti yí padà.
Àkójọ àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kẹta sí ìkẹrìndínlógún jẹ́rìí sí ìsapá tí wọ́n ṣe láti túmọ̀ Septuagint sí èdè Gíríìkì tó dé kẹ́yìn. Ní ọ̀rúndún kẹta, Gregory, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù Neocaesarea (láti ọdún 213 sí 270 Sànmánì Tiwa), túmọ̀ ìwé Oníwàásù láti inú Septuagint sí èdè Gíríìkì tó túbọ̀ rọrùn. Ní ọ̀rúndún kọkànlá, Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tobias ben Eliezer tó ń gbé ní Makedóníà túmọ̀ àwọn apá kan lára ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ti Septuagint sí èdè Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ lójoojúmọ́. Ó tiẹ̀ lo àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù fún àǹfààní àwọn Júù ará Makedóníà tó jẹ́ kìkì èdè Gíríìkì ni wọ́n ń sọ àmọ́ tí wọ́n lè ka ìwé àdàkọ ti Hébérù. Wọ́n tẹ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì tó jẹ́ irú èyí jáde ní Constantinople lọ́dún 1547.
Ìmọ́lẹ̀ Fírífírí Láàárín Òkùnkùn
Lẹ́yìn tí àwọn Ottomans bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso àwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti ń sọ èdè Gíríìkì ní Ilẹ̀ Ọba Byzantium ní ọ̀rúndún karùndínlógún, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ibẹ̀ ló di ẹni tí kò mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní àwọn àǹfààní kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Ottoman, síbẹ̀ ó fi àìbìkítà jẹ́ kí àwọn àgùntàn òun di òtòṣì àti púrúǹtù. Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì nì, Thomas Spelios, kọ̀wé pé: “Ohun àkọ́kọ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ń lépa ni láti dáàbò bo àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ wàhálà ìpolongo èké ti Ìsìláàmù àti ti Ìjọ Kátólíìkì. Nítorí ìdí èyí, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Gíríìkì wá dà bíi pé kò kúrò lójú kan.” Irú àkókò ṣíṣókùnkùn biribiri bẹ́ẹ̀ làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Bíbélì rí i pé ó yẹ káwọn pèsè ìrànwọ́ àti ìtùnú látinú ìwé Sáàmù inú Bíbélì fáwọn tí wàhálà bá. Láàárín ọdún 1543 sí 1835, ìtumọ̀ méjìdínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà fún ìwé Sáàmù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ.
Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó jẹ́ àkọ́kọ́ pàá ni èyí tí Maximus Callipolites, ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó jẹ́ ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ní Callipolis, tẹ̀ jáde lọ́dún 1630. Èyí ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ìdarí Cyril Lucaris tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù Constantinople àti ẹni tí yóò di alátùn-únṣe fún Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Àmọ́, Lucaris ní àwọn alátakò láàárín ṣọ́ọ̀ṣì náà, a Ńṣe ni wọ́n yín in lọ́rùn pa bí ọ̀dàlẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ẹ̀dà lára ìtumọ̀ ti Maximus ni wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1638. Tìtorí ìtumọ̀ yìí ni ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Jerúsálẹ́mù ṣe polongo ní ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lẹ́yìn náà pé Ìwé Mímọ́ “kì í ṣe ohun tí gbáàtúù èèyàn lè máa kà, bí kò ṣe èyí tí kìkì àwọn tó ń wá inú ohun ìjìnlẹ̀ ti ẹ̀mí yóò máa kà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe ìwádìí tí ó yẹ.” Èyí túmọ̀ sí pé àwọn àlùfáà tó bá jẹ́ ọ̀mọ̀wé nìkan ló lè ka Ìwé Mímọ́.
ìyẹn àwọn tí kò fara mọ́ ìsapá láti ṣe àtúnṣe èyíkéyìí tàbí tí wọ́n kẹ̀yìn sí títúmọ̀ Bíbélì sí èdè èyíkéyìí táwọn èèyàn ń sọ.Ní 1703, Seraphim, ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé láti erékùṣù Lesbos gbìyànjú láti tẹ ìtumọ̀ Maximus tí wọ́n tún ṣe jáde ní London. Nígbà táwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ò fún un lówó tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn á fi ràn án lọ́wọ́, ó fi owó ara rẹ̀ tẹ àtúnṣe yìí jáde. Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé náà, Seraphim tẹnu mọ́ ọn pé ó pọn dandan pé kí “gbogbo Kristẹni tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run” máa ka Bíbélì, ó sì fẹ̀sùn kan àwọn àlùfáà tó wà nípò gíga nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà fún “fífẹ́ tí wọ́n fẹ́ bo ìwà búburú wọn mọ́lẹ̀ nípa sísọ àwọn èèyàn náà di aláìmọ̀kan.” Ohun táwọn alátakò rẹ̀ nínú ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ṣe fún un kò ṣàjèjì, wọ́n mú un ní Rọ́ṣíà wọ́n sì rán an lọ sí ìgbèkùn ní Siberia, níbi tó kú sí ní 1735.
Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí ní àlùfáà Gíríìkì kan sọ nípa ìtumọ̀ Maximus ti wọ́n tún ṣe kẹ́yìn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ebi tẹ̀mí tó ń pa àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Gíríìkì lákòókò yẹn, ó ní: “Àwọn Gíríìkì tẹ́wọ́ gba Bíbélì Mímọ́ yìí, àtàwọn mìíràn, pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìháragàgà. Wọ́n sì kà á. Wọ́n sì nímọ̀lára pé ìrora tí wọ́n ní rọlẹ̀, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run . . . sì pọ̀ sí i.” Àmọ́, ẹ̀rù ń ba àwọn aṣáájú wọn nípa tẹ̀mí pé bí àwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí lóye Bíbélì, a jẹ́ pé àṣírí ìgbàgbọ́ àwọn àlùfáà àti ìṣe wọn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu máa tú nìyẹn. Nítorí náà, nígbà tó di ọdún 1823 àti lẹ́yìn náà ní 1836, bíṣọ́ọ̀bù Constantinople lákòókò yẹn gbé òfin kan jáde pé kí wọ́n jó gbogbo ẹ̀dà irú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì bẹ́ẹ̀.
Atúmọ̀ Èdè Kan Tó Gbójúgbóyà
Lójú àtakò líle koko yìí, táwọn èèyàn sì ń yán hànhàn láti ní ìmọ̀ Bíbélì ni ògbóǹtagí kan wá yọjú, ẹni tó máa kó ipa pàtàkì nínú títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Gíríìkì òde òní. Ọkùnrin tó gbójúgbóyà yìí ni Neofitos Vamvas, tó jẹ́ onímọ̀ èdè púpọ̀ lọ́nà tó tayọ, tó sì tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹnì mowó, tí wọ́n sábà máa ń kà sí ọ̀kan lára “Àwọn Olùkọ́ Orílẹ̀-Èdè.”
Vamvas rí i kedere pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló jẹ̀bi àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà àwọn èèyàn náà nípa tẹ̀mí. Ó dá a lójú gidigidi pé káwọn èèyàn náà tó lè jí kúrò lójú oorun tẹ̀mí tí wọ́n ń sùn, ó di dandan láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gíríìkì tí wọ́n ń sọ lákòókò yẹn. Ní 1831, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn mìíràn tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ bíi tirẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gíríìkì tó ṣeé kà. Wọ́n tẹ odindi ìtumọ̀ tirẹ̀ jáde lọ́dún 1850. Nítorí pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kọ̀ láti tì í lẹ́yìn, ó dara pọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ilẹ̀ Òkèèrè kí wọ́n lè tẹ ìtumọ̀ rẹ̀ yìí jáde kí wọ́n sì pín in káàkiri. Ṣọ́ọ̀ṣì náà pè é ní “Pùròtẹ́sítáǹtì,” kò sì pẹ́ tí wọ́n fi kà á sí ẹni ìtanùlẹ́gbẹ́.
Ìtumọ̀ King James Version ni Vamvas gbé ìtumọ̀ tiẹ̀ kà látòkèdélẹ̀, gbogbo àṣìṣe tó wà nínú ẹ̀dà yẹn ló sì wà nínú ẹ̀dà tirẹ̀ nítorí ìmọ̀ Bíbélì àti ìmọ̀ èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nígbà yẹn. Síbẹ̀, fún ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé ẹ̀dà tirẹ̀ ni Bíbélì tí wọ́n fi èdè Gíríìkì òde òní kọ táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jù Jẹ́nẹ́sísì 22:14; Ẹ́kísódù 6:3; 17:15; Àwọn Onídàájọ́ 6:24.
lọ. Ó dùn mọ́ni pé, orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an fara hàn nínú rẹ̀ ní ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n pè é ní “Ieová.”—Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn sí èyí àti sí àwọn ẹ̀dà Bíbélì mìíràn tó rọrùn láti lóye? Inú wọn dùn kọjá ààlà! Inú ọkọ̀ ojú omi kan tó ń gba ọkàn lára àwọn erékùṣù náà kọjá ni ọkùnrin kan tó ń bá Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ilẹ̀ Òkèèrè ta Bíbélì wà nígbà tí “ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ojú omi tó kó àwọn ọmọ kéékèèké tó fẹ́ gba [Bíbélì] sọgbà yí i ka, débi pé ó di dandan fún un . . . láti sọ fún ọ̀gákọ̀ náà pé kó kúrò ní èbúté ọ̀hún kó má lọ jẹ́ pé ojú kan ni gbogbo Bíbélì tó ní lọ́wọ́ máa tán sí! Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí àtakò fi bẹ̀rẹ̀.
Àlùfáà Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé wọn ò gbọ́dọ̀ ra irú àwọn ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àwọn Bíbélì kan nílùú Áténì. Ní ọdún 1833, gbogbo “Májẹ̀mú Titun” tí bíṣọ́ọ̀bù Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Kírétè rí nílé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan ló sun níná. Àlùfáà kan fi ẹ̀dà tirẹ̀ pa mọ́, àwọn tó ń gbé ní abúlé kan tó wà nítòsí fi àwọn ẹ̀dà tiwọn náà pa mọ́ títí dìgbà tí bíṣọ́ọ̀bù náà fi kúrò ní erékùṣù ọ̀hún.
Ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn ni Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ka ìtumọ̀ Bíbélì ti Vamvas léèwọ̀ ní erékùṣù Corfu. Wọn ò gbà pé káwọn èèyàn tà á, wọ́n sì ba àwọn ẹ̀dà táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jẹ́. Inúnibíni àwùjọ àlùfáà ló sún wọn dórí sísun Bíbélì níná ní àwọn erékùṣù Chios, Síros, àti Mykonos. Àmọ́ títẹ Bíbélì rì síwájú sí i ṣì ń bẹ níwájú.
Ọbabìnrin Kan Nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì
Àárín àwọn ọdún 1870 ni Ọbabìnrin Olga ti ilẹ̀ Gíríìsì rí i pé àwọn èèyàn Gíríìkì ṣì ní ìmọ̀ díẹ̀ nínú Bíbélì. Nítorí ìdánilójú tó ní pé ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ yóò pèsè ìtùnú àti ìtura fún orílẹ̀-èdè náà, ó là kàkà láti rí i pé wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí èdè tó túbọ̀ rọrùn ju èyí ti Vamvas túmọ̀ lọ.
Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ilẹ̀ Áténì àti Prokopios, tó jẹ́ olórí Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn, fún ọbabìnrin náà níṣìírí lórí ohun tó dáwọ́ lé yìí. Àmọ́ nígbà tó wá kọ̀wé pé kí Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́ fọwọ́ sí ohun tó fẹ́ ṣe yìí, ńṣe ni wọ́n kọ̀ jálẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, kò sinmi, ó tún kọ ìwé mìíràn, àmọ́ pàbó ni ọ̀rọ̀ náà tún já sí, wọ́n tún kọ jálẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì ní 1899. Bó ṣe pa wọ́n tì nìyẹn, tó sì pinnu láti fi owó ara rẹ̀ tẹ ìwọ̀nba ẹ̀dá díẹ̀ jáde. Ó ṣe èyí láṣeparí ní ọdún 1900.
Àwọn Alátakò Tí Kì Í Jáwọ́ Bọ̀rọ̀
Ní 1901, ìwé ìròyìn The Acropolis, tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó ní Áténì, gbé Ìhìn Rere Mátíù jáde ní èdè Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ. Alexander Pallis, atúmọ̀ èdè tó ń ṣiṣẹ́ ní Liverpool,
ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ṣe ìtumọ̀ yìí. Ohun tó dìídì jẹ́ ète Pallis àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni láti ‘kọ́ àwọn Gíríìkì lẹ́kọ̀ọ́’ àti láti “ran orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́ kó lè bọ́ lọ́wọ́” kíkú tó ń kú lọ.Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àtàwọn ọ̀jọ̀gbọ́n wọn pe ìtumọ̀ náà ní “fífi ohun tí orílẹ̀-èdè náà ń júbà fún jù lọ ṣẹ̀sín,” ìyẹn ni sísọ Ìwé Mímọ́ di àìmọ́. Bíṣọ́ọ̀bù Joakim Kẹta ti Constantinople kọ ìwé kan jáde tó fi hàn pé wọn ò fara mọ́ ìtumọ̀ náà. Àríyànjiyàn náà wá di èyí tí wọ́n ki ọ̀ràn òṣèlú bọ̀, àwọn olóṣèlú tí wọ́n ń díje sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èyí hùwà iṣẹ́ láabi ọwọ́ wọn.
Apá kan tó lókìkí gan-an nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Áténì bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti ìtumọ̀ tí Pallis ṣe yìí, ó pe àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ní “aláìgbà-pọ́lọ́run-wà,” “ọ̀dàlẹ̀,” àti “aṣojú àwọn agbára àjèjì” tó múra tán láti da àwùjọ Gíríìkì rú. Ní ọjọ́ karùn-ún sí ìkẹjọ nínú oṣù kọkànlá lọ́dún 1901 ni ẹgbẹ́ tó jẹ́ arọ̀mọ́pìlẹ̀ gan-an nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì sún àwọn ọmọ ilé ìwé láti dàgboro rú ní Áténì. Wọ́n ba àwọn ọ́fíìsì ìwé ìròyìn The Acropolis jẹ́, wọ́n ṣe ìwọ́de dé ààfin ọba, wọ́n gba Yunifásítì Áténì, wọ́n sì sọ pé dandan ni kí àwọn tó ń ṣèjọba kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀. Nígbà tí ìjà ìgboro náà dé òtéńté rẹ̀, àwọn èèyàn mẹ́jọ ló kú níbi tí wọ́n ti ń bá àwọn sọ́jà fìjà pẹẹ́ta. Ní ọjọ́ kejì, ọba sọ pé kí Prokopios tó jẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀, ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà ló tún sọ pé kí gbogbo àwọn tó ń ṣèjọba fiṣẹ́ sílẹ̀.
Àwọn ọmọ ilé ìwé náà tún dàgboro rú ní oṣù kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n sì sun ẹ̀dà kan nínú ìtumọ̀ ti Pallis ṣe níná lójú gbogbo èèyàn. Wọ́n gbé ìpinnu kan jáde tí wọ́n fi ka pínpín ìtumọ̀ yìí káàkiri léèwọ̀, wọ́n sì sọ pé ìyà ńlá ni wọ́n máa fi jẹ ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Èyí ni wọ́n wá fi ráyè gbẹ́sẹ̀ lé lílo ẹ̀dà Bíbélì èdè Gíríìkì òde òní èyíkéyìí. Àkókò búburú gbáà nìyẹn lóòótọ́!
“Àsọjáde Jèhófà Wà Títí Láé”
Kíkà tí wọ́n ka lílo Bíbélì èdè Gíríìkì òde òní léèwọ̀ di èyí tí wọ́n yí padà ní ọdún 1924. Àtìgbà yẹn ni gbogbo ìsapá Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì láti má ṣe jẹ́ kí Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn èèyàn ti di èyí tó kùnà pátápátá. Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú ipò iwájú nínú fífi Bíbélì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nílẹ̀ Gíríìsì, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọ̀pọ̀ àwọn ilẹ̀ mìíràn. Láti 1905 ni wọ́n ti ń lo ìtumọ̀ ti Vamvas láti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Gíríìkì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì.
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àtàwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló ti sapá gidi gan-an láti tẹ Bíbélì jáde ní èdè Gíríìkì òde òní. Lónìí, wọ́n ti tẹ nǹkan bí ọgbọ̀n ìtumọ̀ Bíbélì táwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì lè kà kí wọ́n sì lóye rẹ̀ jáde yálà lódindi tàbí lápá kan. Èyí tó múná dóko jù lọ nínú wọn ni ẹ̀dà ti Gíríìkì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tá a mú jáde ní 1997, fún àǹfààní àwọn mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún èèyàn tó ń sọ èdè Gíríìkì jákèjádò ayé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde, ìtumọ̀ yìí mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jáde ní ọ̀nà tó rọrùn láti kà, àti láti lóye, ohun tó sì wà nínú ẹ̀dà ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ gan-an ló wà nínú rẹ̀.
Akitiyan láti mú Bíbélì lédè Gíríìkì òde òní jáde fìdí kókó pàtàkì kan múlẹ̀. Ó fi hàn kedere pé láìfi ìsapá àwọn èèyàn tó jẹ́ òkú òǹrorò pè, “àsọjáde Jèhófà wà títí láé.”—1 Pétérù 1:25.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa Cyril Lucaris, wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 2000, ojú ìwé 26 sí 29.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Cyril Lucaris ló darí odindi Ìwé Mímọ́ Kristẹni tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ sí èdè Gíríìkì lọ́dún 1630
[Credit Line]
Bib. Publ. Univ. de Genève
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ìtumọ̀ kan tí wọ́n ṣe sí èdè Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ: Àwọn Sáàmù tá a tẹ̀ jáde ní (1) 1828 látọwọ́ Ilarion, (2) 1832 látọwọ́ Vamvas, (3) 1643 látọwọ́ Julianus. “ Májẹ̀mú Láéláé” tá a tẹ̀ jáde ní : (4) 1840, látọwọ́ Vamvas
Ọbabìnrin Olga
[Àwọn Credit Line]
Àwọn Bíbélì: Ibi Ìkówèésí ti ilẹ̀ Gíríìsì; Ọbabìnrin Olga: Fọ́tò Culver
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Òrépèté: A tún un gbé jáde nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure The Trustees of the Chester Beatty Library, Dublin
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
Òrépèté: A tún un gbé jáde nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure The Trustees of the Chester Beatty Library, Dublin