Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìràpadà Túbọ̀ Fi Òdodo Ọlọ́run Hàn

Ìràpadà Túbọ̀ Fi Òdodo Ọlọ́run Hàn

Ìràpadà Túbọ̀ Fi Òdodo Ọlọ́run Hàn

LẸ́YÌN ìṣọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà, Jèhófà sọ ohun tí òun ní lọ́kàn láti ṣe, ìyẹn ni láti pèsè Irú Ọmọ kan tí Sátánì yóò pa ní gìgísẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Èyí nímùúṣẹ nígbà táwọn ọ̀tá Ọlọ́run ṣekú pa Jésù Kristi lórí òpó igi oró. (Gálátíà 3:13, 16) Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́ ni wúńdíá kan lóyún rẹ̀ lọ́nà ìyanu. Nítorí náà, ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀ ni Ọlọ́run wá lò gẹ́gẹ́ bí owó ìràpadà, kí ìran èèyàn tó ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ Ádámù lè rí ìtúsílẹ̀.—Róòmù 5:12, 19.

Kò sí ohunkóhun tó lè dá Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè dúró láti má ṣe mú ète rẹ̀ ṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí ìran èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé a ti san owó ìràpadà náà lójú Jèhófà, ó sì ṣeé ṣe fún un láti bá àwọn èèyàn kan lò, ìyẹn àwọn tó fi ìgbàgbọ́ hàn nínú ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀. Ìdí nìyẹn táwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù bí Énọ́kù, Nóà àti Ábúráhámù tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ fi lè bá Ọlọ́run rìn, àní tó tiẹ̀ tún bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́ pàápàá, tíyẹn ò sì kó àbàwọ́n bá jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni mímọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 5:24; 6:9; Jákọ́bù 2:23.

Àwọn kan lára àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an. Àpẹẹrẹ kan ni Ọba Dáfídì. Ìbéèrè kan tó lè máa wá sí ọ lọ́kàn ni pé ‘Báwo ni Jèhófà ṣe lè máa bù kún Dáfídì Ọba nìṣó lẹ́yìn tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú Bátíṣébà tó sì tún jẹ́ pé òun ló wà nídìí ikú tó pa Ùráyà, ọkọ obìnrin náà?’ Kókó pàtàkì kan tó mú kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé Dáfídì ronú pìwà dà tọkàntọkàn ó sì tún ní ìgbàgbọ́. (2 Sámúẹ́lì 11:1-17; 12:1-14) Nítorí ẹbọ Jésù Kristi tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì tó ronú pìwà dà jì í, síbẹ̀ ìyẹn ò sọ Ọlọ́run di aláìṣòdodo àti ẹni tí ń ṣojúsàájú. (Sáàmù 32:1, 2) Láti jẹ́rìí sí èyí, Bíbélì ṣàlàyé ohun tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ tí ìràpadà Jésù mú kó ṣeé ṣe, ìyẹn ni “láti fi òdodo [Ọlọ́run] hàn, nítorí òun ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá jì” àti “ní àsìkò ìsinsìnyí.”—Róòmù 3:25, 26.

Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ Jésù ṣeyebíye gan-an, ọ̀pọ̀ àǹfààní ńláǹlà laráyé ń rí gbà. Nítorí ìràpadà náà, àwọn èèyàn tó bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìyẹn nìkan kọ́, ẹbọ ìràpadà náà tún ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àjíǹde àwọn òkú sínú ayé tuntun Ọlọ́run. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n kú kó tó di pé Jésù san owó ìràpadà náà yóò wà lára wọn. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn tó kú sípò àìmọ̀kan tí wọn ò sì jọ́sìn Jèhófà yóò jí dìde. Bíbélì sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Nítorí ìràpadà náà, Jèhófà yóò fún gbogbo àwọn tó bá ṣègbọràn ní ìyè àìnípẹ̀kun lákòókò yẹn. (Jòhánù 3:36) Jésù fúnra rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Gbogbo àǹfààní yìí ni yóò jẹ́ ti aráyé nítorí ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè.

Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù nípa ìràpadà náà kì í ṣe àwọn àǹfààní tá a rí gbà látinú rẹ̀. Ohun tí ìràpadà Kristi ṣe fún orúkọ Jèhófà ló ṣe kókó jù. Ó jẹ́ kó hàn kedere pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí kì í ṣègbè rárá, tó lè bá àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ lò, síbẹ̀ kó ṣì jẹ́ ẹni mímọ́ àti ẹni tí kò lábàwọ́n. Ká ní Ọlọ́run kò ṣètò láti pèsè ìràpadà ni, kì bá máà sí àtọmọdọ́mọ Ádámù kankan tó máa lè bá Jèhófà rìn tàbí tó máa lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, kódà ì bá má ṣeé ṣe fún Énọ́kù, Nóà, àti Ábúráhámù pàápàá. Onísáàmù mọ èyí, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká fọpẹ́ fún Jèhófà gan-an fún rírán tó rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé, ká sì tún fọpẹ́ fún Jésù tó fínnúfíndọ̀ fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ láti fi ṣe ìràpadà fún wa!—Máàkù 10:45.