Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé ọmọ inú oyún tó kú sínú ìyá rẹ̀ máa ní àjíǹde?

Téèyàn ò bá tíì bí òkú ọmọ rí tàbí tí oyún ò tíì bà jẹ́ lára rẹ̀ rí, ó lè ṣòro fún un láti mọ bó ṣe máa ń rí lára àwọn tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí. Ìbànújẹ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa ń kó bá àwọn kan máa ń pọ̀ lápọ̀jù. Obìnrin kan wà tó lóyún lẹ́ẹ̀ẹ́márùn-ún, àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ni oyún náà ń bà jẹ́ tàbí kó máa bí i lókùú. Nígbà tó yá, ó rí ọmọkùnrin méjì gbé jó, ó sì tọ́ àwọn méjèèjì dàgbà. Síbẹ̀, ìbànújẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn oyún tó ń bà jẹ́ lára rẹ̀ yẹn kò kúrò lọ́kàn rẹ̀. Títí tó fi kú ló ń rántí bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ náà ì bá ti dàgbà tó ká ní òun bí wọn tí wọ́n sì yè ni. Ǹjẹ́ irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ ní ìdí láti máa retí àjíǹde irú àwọn ọmọ tí wọ́n pàdánù náà?

Ní kúkúrú, ìdáhùn ìbéèrè náà ni pé, a kò mọ̀. Bíbélì kò sọ ohun kan ní tààràtà nípa àjíǹde ọmọ tí wọ́n bí lókùú tàbí tí oyún wọn bà jẹ́ nínú ìyá wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìlànà kan wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run téèyàn lè gbé yẹ̀ wò lórí ìbéèrè yìí, tó sì lè tuni nínú dé ìwọ̀n àyè kan.

Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè méjì tó jẹ mọ́ ọ̀ràn yìí. Èkíní, lójú Jèhófà, ìgbà wo ni èèyàn kan di ẹ̀dá alààyè, ìgbà tí wọ́n lóyún rẹ̀ ni àbí ìgbà tí wọ́n bí i? Èkejì, ojú wo ni Jèhófà fi ń wo oyún inú, ṣé èèyàn gidi ni àbí ẹ̀jẹ̀ lásán tí kò tíì dọmọ àti ìjàǹjá ẹran lásán tó wà nínú ilé ọlẹ̀ obìnrin kan? Àwọn ìlànà Bíbélì jẹ́ ká rí ìdáhùn tó ṣe kedere sáwọn ìbéèrè méjèèjì yìí.

Òfin Mósè fi hàn kedere pé ọmọ ti máa ń di ẹ̀dá alààyè ṣáájú kí wọ́n tó bí i, kì í ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá bí i. Báwo ló ṣe fi hàn bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé ẹni tó bá ṣekú pa ọmọ inú oyún ní láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ dí i. Òfin náà sọ pé: “Kí ìwọ fi ọkàn fún ọkàn.” a (Ẹ́kís. 21:22, 23) Èyí fi hàn pé alààyè ọkàn kan ni ọmọ inú oyún yẹn, odindi èèyàn sì ni. Òye tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwa Kristẹni ní lórí ọ̀ràn yìí ti mú ká lòdì sí ṣíṣẹ́ oyún, tórí a mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni lójú Ọlọ́run.

Ó dáa, a mọ̀ pé alààyè ni ọmọ tó wà nínú oyún, àmọ́ báwo ni ẹ̀mí ọmọ náà ti ṣe pàtàkì tó lójú Jèhófà? Òfin tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan yẹn sọ pé wọ́n ní láti pa àgbàlagbà tó bá fa ikú ọmọ inú oyún. Ó hàn kedere nígbà náà pé ẹ̀mí ọmọ inú oyún ṣe pàtàkì púpọ̀ lójú Ọlọ́run. Yàtọ̀ sí èyí, ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ló jẹ́ ká rí i pé ojú odindi èèyàn kan ni Jèhófà fi ń wo ọmọ tó ṣì wà nínú ìyá rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìmísí Jèhófà mú kí Dáfídì Ọba sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi. . . . Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀, ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn.”—Sm. 139:13-16; Job 31:14, 15.

Jèhófà tún máa ń rí àwọn ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn ọmọ inú oyún ní, ó sì lè mọ̀ bóyá wọ́n máa dẹni táá gbé nǹkan ńlá ṣe lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí Rèbékà ìyàwó Ísákì lóyún ìbejì, Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tó ń bá ara wọn jìjàkadì nínú Rèbékà, èyí sì fi hàn pé Jèhófà ti rí àwọn ànímọ́ kan nínú àwọn ọmọ yẹn tó máa ṣe nǹkan kan fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn lọ́jọ́ iwájú tó ṣì jìnnà réré.—Jẹ́n. 25:22, 23; Róòmù 9:10-13.

Ọ̀ràn Jòhánù Oníbatisí náà tún gbé kókó yìí yọ. Ìwé Ìhìn rere sọ pé: “Tóò, bí Èlísábẹ́tì ti gbọ́ ìkíni Màríà, ọmọ inú ilé ọlẹ̀ rẹ̀ sọ; Èlísábẹ́tì sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.” (Lúùkù 1:41) Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí Lúùkù lò láti ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lè fi ṣàpèjúwe ọmọ inú oyún tàbí ọmọ tí wọ́n ti bí. Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ló fi ṣàpèjúwe Jésù nígbà tó jẹ́ ọmọ tuntun tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.—Lúùkù 2:12, 16; 18:15.

Tá a bá wá pa gbogbo ohun tá a sọ yìí pọ̀, ǹjẹ́ a lè sọ pé Bíbélì fìyàtọ̀ sáàárín ọmọ inú aboyún àti ọmọ tí wọ́n ti bí síta tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í mí fúnra rẹ̀? Kò jọ bẹ́ẹ̀ o. Èyí sì wá bá ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ti ṣàwárí mu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé ọmọ inú aboyún lè mọ ohun tó ń lọ níta ikùn ìyá rẹ̀, ó sì máa ń mira nígbà míì. Torí náà, kò yani lẹ́nu pé aláboyún ti máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ tó ń dàgbà níkùn rẹ̀ tọ́rọ̀ wọn sì máa ń yé ara wọn.

Ọjọ́ ìkúnlẹ̀ abiyamọ kọ̀ọ̀kan máa ń pẹ́ ju ara wọn lọ kó tó pé, nítorí oṣù ni aboyún mọ̀, kò mọ ọjọ́. Wo àpẹẹrẹ yìí: Ká sọ pé obìnrin kan bí ọmọ rẹ̀ ní kògbókògbó, àmọ́ tí ọmọ náà sì kú lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tó bí i. Obìnrin míì tún wà tí ọmọ inú rẹ̀ gbó, àmọ́ tí ọmọ náà kú nígbà tó kù díẹ̀ kó bí i. Ṣé a lè sọ pé obìnrin àkọ́kọ́ lè máa retí pé ọmọ òun á jíǹde torí pé ó ti bí i láàyè ní kògbókògbó kó tó kú, tí obìnrin kejì kò sì lè retí pé ọmọ òun á jíǹde torí pé òkú ọmọ ló bí?

Àkópọ̀ gbogbo ohun tá à ń sọ yìí ni pé Bíbélì jẹ́ kó yé wa pé ìgbà tí oyún ọmọ kan bá ti dúró sí ìyá rẹ̀ lára ló ti dẹni tó wà láàyè àti pé Jèhófà ka ọmọ inú oyún sí odindi èèyàn kan tó dá yàtọ̀ tó sì wúlò. Pẹ̀lú òye tá a rí nínú Bíbélì yìí, àwọn kan lè rò pé tá a bá sọ pé kò sí àjíǹde fọ́mọ tó kú kí wọ́n tó bí i, ṣe là ń ta ko òtítọ́ tí Bíbélì fi kọni nípa ọmọ inú oyún. Kódà, wọ́n lè sọ pé irú ẹ̀kọ́ yẹn máa ta ko ìgbàgbọ́ wa pé ṣíṣẹ́ oyún kò bá Ìwé Mímọ́ mu, bẹ́ẹ̀ sì rèé orí òtítọ́ yẹn pé ọmọ inú oyún jẹ́ odindi èèyàn lójú Ọlọ́run la gbé ìgbàgbọ́ wa yẹn kà.

Láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti béèrè àwọn ìbéèrè kan tó lè fẹ́ mú kéèyàn máa rò pé bóyá ni àjíǹde máa wà fáwọn ọmọ tó kú kí wọ́n tó bí wọn. Bí àpẹẹrẹ, ṣé Ọlọ́run máa wá fi ọlẹ̀ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà sínú ilé ọlẹ̀ obìnrin kan ní Párádísè ni? Àmọ́ bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń tẹpẹlẹ mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́, àṣàrò àti àdúrà, wọ́n ti wá rí i pé gbogbo irú èrò yẹn ò ní nǹkan kan ṣe nínú ọ̀ràn àjíǹde. Ohun tí Jésù sọ ni pé: “Ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:27) Ọ̀nà tí wọ́n gbà bí Jésù fúnra rẹ̀ fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ńṣe ni Jèhófà mú ìwàláàyè rẹ̀ lọ́run, ó sì fi í sínú ilé ọlẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó jẹ́ wúńdíá láyé. Ó dájú pé lójú ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà ṣe yẹn dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe.

Ṣé ìtumọ̀ gbogbo ohun tá a sọ yìí ni pé Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ tó ti kú kí wọ́n tó bí wọn máa ní àjíǹde? Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Bíbélì ò dáhùn ìbéèrè yìí ní tààràtà. Ìdí nìyẹn tẹ́nikẹ́ni ò fi lè fi gbogbo ẹnu sọ pé wọ́n á jíǹde tàbí wọn ò ní jíǹde. Àìmọye ìbéèrè ló lè jẹ yọ lórí ọ̀ràn yìí. Àmọ́ ohun tó ti dáa jù lọ ni pé ká má ṣe máa méfò lórí ọ̀ràn yìí. Ohun tá a mọ̀ ni pé: Ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó pọ̀ nínú àánú àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni ọ̀ràn náà wà. (Sm. 86:15) Ó dá wa lójú pé ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni láti fi àjíǹde pa oró ikú. (Jóòbù 14:14, 15) Ọkàn wa balẹ̀ pé ohun tó tọ́ ló máa ń ṣe nígbà gbogbo. Ó máa wo gbogbo ọgbẹ́ ọkàn tá a ti ní nígbèésí ayé wa nínú ètò nǹkan búburú ti ìsinsìnyí sàn, nígbà tó bá fìfẹ́ pàṣẹ fún ọmọ rẹ̀ pé kó “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.”—1 Jòh. 3:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan máa ń túmọ̀ ẹsẹ yìí lọ́nà tó fi jọ pé ikú aboyún nìkan ló lè mú kí wọ́n pa ẹni tó fa jàǹbá náà. Àmọ́ nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ikú aboyún tàbí ọmọ inú rẹ̀ ni òfin yẹn ń sọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Jèhófà yóò wo gbogbo ìbànújẹ́ ọkàn wa sàn