Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Fẹ́ Kó O Wà ní “Àlàáfíà” àti Láìséwu

Jèhófà Fẹ́ Kó O Wà ní “Àlàáfíà” àti Láìséwu

Jèhófà Fẹ́ Kó O Wà ní “Àlàáfíà” àti Láìséwu

NÍGBÀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó léwu jù lọ nínú ìtàn bá wáyé, Ọlọ́run Olódùmarè máa rí i dájú pé gbogbo àwọn tó bá jèrè ojú rere òun “yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:32) Àmọ́, òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fẹ́ láti pa àwọn èèyàn mọ́ kúrò nínú ewu. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà,” ó ka gbogbo èèyàn sí ẹni tó ṣeyebíye, tó yẹ kí òun dáàbò bò.—Sm. 36:9.

Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí, ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ìgbà àtijọ́ náà fi ń wò ó. Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 33:18 ṣe sọ, Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ gúnlẹ̀ ní ayọ̀ àti “àlàáfíà” lẹ́yìn tí wọ́n ti rin ìrìn-àjò kan tó léwu. Jékọ́bù ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà máa dáàbò bo òun, àmọ́ ó tún ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu kó lè dáàbò bo gbogbo àwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò. (Jẹ́n. 32:7, 8; 33:14, 15) Ìwọ náà lè túbọ̀ máa pa ara rẹ àtàwọn míì mọ́ lọ́wọ́ ewu, bó o bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn tó ń kópa nínú irú àwọn iṣẹ́ míì bẹ́ẹ̀, àtàwọn tó ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù, ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ewu.

Ọ̀ràn Ààbò Lábẹ́ Òfin Mósè

Lábẹ́ Òfin Mósè, ó pọn dandan fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti máa pa ìlànà tó wà fún ààbò mọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá kọ́ ilé, ó gbọ́dọ̀ ṣe ìgbátí, ìyẹn ògiri tí kò ga, tàbí ohun tó ṣeé dáwọ́ lé, yí etí òrùlé náà ká. Torí pé àwọn èèyàn sábà máa ń wà ní orí ilé wọn, ìgbátí tí wọ́n ṣe yí òkè ilé ká yìí ni kò ní jẹ́ kí wọ́n já bọ́ láti ibẹ̀. (1 Sám. 9:26; Mát. 24:17) Bí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ torí pé ẹni tó ni ilé kùnà láti tẹ̀ lé òfin ààbò yìí, Jèhófà máa mú kó dáhùn fún un.—Diu. 22:8.

Lábẹ́ òfin, ìjìyà tún wà fún ẹni tí ẹranko agbéléjẹ̀ rẹ̀ bá ṣe èèyàn léṣe. Bí màlúù bá kan ẹnì kan pa, ẹni tó ni màlúù náà gbọ́dọ̀ pa á kó má bàa tún ṣe àwọn míì ní jàǹbá. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran màlúù náà tàbí kó tà á fún jíjẹ, àdánù ńlá ni pípa ẹranko náà máa jẹ́ fún un. Àmọ́, ká sọ pé ẹni tó ni màlúù náà kò sé e mọ́ lẹ́yìn tó ti ṣe ẹnì kan léṣe ńkọ́? Kí ló máa tìdí ẹ̀ yọ? Bí màlúù kan náà yẹn bá pa ẹnì kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, pípa ni wọ́n máa pa màlúù náà àti olówó rẹ̀. Òfin yìí mú kó pọn dandan fún olúkúlùkù láti fọwọ́ pàtàkì mú àbójútó ohun ọ̀sìn rẹ̀.—Ẹ́kís. 21:28, 29.

Òfin Mósè tún rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa lo irinṣẹ́ bó ṣe yẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi àáké gé igi ìdáná. Bí irin bá ṣèèṣì fò yọ lára ẹ̀rú àáké tó sì pa ẹni tó wà nítòsí ibẹ̀, ẹni tó ń gé igi náà gbọ́dọ̀ sá lọ sí ìlú ààbò. Ó sì gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀ títí di ìgbà ikú àlùfáà àgbà, èyí tó já sí pé ó ṣeé ṣe kí ẹni tó ṣèèṣì pànìyàn náà má fojú kan àwọn èèyàn rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ìṣètò yìí kọ́ àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè náà lẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ka ẹ̀mí sí mímọ́. Ẹni tó bá ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí wò ó, á máa tún àwọn irinṣẹ́ rẹ̀ ṣe, á sì máa lò wọ́n lọ́nà tí kò léwu.—Núm. 35:25; Diu. 19:4-6.

Jèhófà ń lo irú àwọn òfin yìí láti mú kó ṣe kedere pé òun fẹ́ káwọn èèyàn òun máa ṣe ohun tí kò fi ẹ̀mí èèyàn sínú ewu, yálà wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú ilé tàbí ní ìta. Àwọn tí ẹ̀mí èèyàn bá ti ọwọ́ wọn bọ́ tàbí tí wọ́n ṣe ẹlòmíì léṣe, máa dáhùn fún un, yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀ọ́mọ̀. Ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn ààbò kò tíì yí pa dà. (Mál. 3:6) Kò fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe ara wọn tàbí àwọn ẹlòmíì léṣe, pàápàá jù lọ tá a bá ń kọ́ àwọn ibi ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn tòótọ́ tàbí tá a bá ń tún irú àwọn ibi ìjọsìn bẹ́ẹ̀ ṣe.

Pípa Òfin Ààbò Mọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ilé Kíkọ́

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ilé tá à ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àti títún irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ ṣe. Àǹfààní ńlá ló sì tún jẹ́ láti máa lọ́wọ́ nínú ṣíṣe àtúnkọ́ ibùgbé àwọn tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀ sí. Ní gbogbo ìgbà, a fẹ́ láti máa ṣe iṣẹ́ wa lọ́nà jíjá fáfá torí pé béèyàn ò bá dáńgájíá lẹ́nu iṣẹ́ tó ń ṣe, kódà kó jẹ́ iṣẹ́ kékeré, ó lè ṣèpalára fún ara rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì. (Oníw. 10:9) Bí a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ṣiṣẹ́ láìséwu, a ó lè sá fún àwọn ohun tó lè pa wá lára.

Bíbélì sọ pé: “Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn, ọlá ńlá àwọn arúgbó sì ni orí ewú wọn.” (Òwe 20:29) A nílò okun ọ̀dọ́ láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ tó gba agbára. Àmọ́, àwọn àgbà òṣìṣẹ́ tó ti hewú lórí, tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ilé kíkọ́, máa ń fi ọwọ́ wọn àti irinṣẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ ọnà ara ilé. Àwọn tó sì ti dàgbà báyìí ti lo okun ìgbà ọ̀dọ́ wọn láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó gba agbára nígbà kan rí. Bó bá jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ̀ǹda ara rẹ fún iṣẹ́ ni, máa kíyè sí ọ̀nà táwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ń gbà ṣe iṣẹ́ wọn, kó o sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n bá fún ẹ. Bó o bá múra tan láti kẹ́kọ̀ọ́, àwọn arákùnrin tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ilé kíkọ́ máa kọ́ ẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. Lára ohun tí wọ́n máa kọ́ ẹ ni ọ̀nà tó o lè gbà máa bójú tó àwọn ohun èlò tó lè pani lára àti bí wàá ṣe máa gbé àwọn nǹkan tó wúwo. Èyí á jẹ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ náà lọ́nà tó gbéṣẹ́, láìséwu, tí wàá sì láyọ̀.

Ipò àwọn nǹkan tètè máa ń yí pa dà níbi tí wọ́n bá ti ń ṣiṣẹ́ ilé kíkọ́, torí náà, àwọn tó bá ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ gbọ́dọ̀ máa wà lójú fò nígbà gbogbo. Wọ́n ti lè gbẹ́ ihò sí ibi tí kò sí ihò tẹ́lẹ̀. Àwọn míì lára àwọn òṣìṣẹ́ lè ti sún àkàbà, pákó tàbí ike ọ̀dà kúrò níbi tó wà. Tí o kò bá kíyè sára, o lè ṣubú kó o sì ṣèṣe. Àwọn ìlànà tó wà fún ààbò sábà máa ń béèrè pé káwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìkọ́lé máa lo àwọn ohun tó lè dáàbò bò wọ́n. Lílo awò tó ń dáàbò bo ojú, akoto àti bàtà tó yẹ lè dáàbò bò ẹ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ohun tó máa ń wu àwọn èèyàn léwu níbi tí wọ́n ti ń kọ́lé. Àmọ́, kí wọ́n tó lè dáàbò bò ẹ́, o gbọ́dọ̀ rí i pé wọn kò bà jẹ́, o sì gbọ́dọ̀ wọ̀ wọ́n.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè jọ pé àwọn irin iṣẹ́ kan kò ṣòro láti lò, kéèyàn tó lè lò wọ́n lọ́nà tó já fáfá, tí kò sì léwu, ó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti kéèyàn máa lò wọ́n déédéé. Bí o kò bá mọ irin iṣẹ́ kan lò, sọ fún ẹni tó ń bójú tó iṣẹ́ náà. Ó máa ṣètò pé kí wọ́n kọ́ ẹ bí wọ́n ṣe ń lò ó. Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni jẹ́ ànímọ́ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kòṣeémánìí sì ni ànímọ́ yìí bí o kò bá fẹ́ ṣe ara rẹ àti àwọn míì léṣe níbi iṣẹ́ ìkọ́lé.—Òwe 11:2.

Ohun tó máa ń fa ìpalára fáwọn èèyàn jù lọ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé ni pé kí wọ́n já bọ́ látòkè. Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí gun àkàbà tàbí igi tàbí irin tí wọ́n tò kalẹ̀, rí i dájú pé ibi tó yẹ kó wà ni wọ́n gbé e sí, wọ́n sì tò ó dáadáa. Bó o bá ní láti gun igi tàbí irin tí wọ́n tò sílẹ̀ tàbí tó o bá fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí òrùlé, ó lè gba pé kó o lo bẹ́líìtì ààbò tàbí kí wọ́n to nǹkan tí kò ní jẹ́ kó o já bọ́ yí ká ibi tó o fẹ́ gùn. Bí o bá ní láti ṣiṣẹ́ ní ibi tó ga, tí ohun kan ò sì yé ẹ tó nípa iṣẹ́ náà, béèrè lọ́wọ́ alábòójútó iṣẹ́. a

Bí iye àwọn tó ń sin Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i kárí ayé, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń pọn dandan sí i pé ká kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé mìíràn tá à ń lò fún mímú kí ìjọsìn tòótọ́ gbòòrò síwájú. Ojúṣe àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé lílò míì ni láti rí i pé ohunkóhun kò ṣèpalára fún àwọn àgùntàn ṣíṣeyebíye Jèhófà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí wọn. (Aísá. 32:1, 2) Bó o bá láǹfààní láti darí àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé, má ṣe gbàgbé pé ọ̀ràn ààbò ṣe pàtàkì. Rí i dájú pé ibẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní àti pé kò sí ẹrù jánganjàngan níbẹ̀. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, fi pẹ̀lẹ́tù ṣàlàyé ètò tó wà fún ààbò fún àwọn tó bá nílò ìránnilétí. Má ṣe jẹ́ káwọn ọmọdé tàbí àwọn tí kò nírìírí ṣiṣẹ́ lápá ibi tó léwu gan-an. Fojú inú wòye ohun tó ṣeé ṣe kó fa jàǹbá fún àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́, kó o sì ṣètò bí wọ́n á ṣe ṣiṣẹ́ láìséwu. Má sì ṣe gbàgbé pé àfojúsùn wa ni pé kí ẹnikẹ́ni má ṣèṣe títí tí a ó fi parí iṣẹ́ náà.

Bí Ìfẹ́ Ṣe Lè Ṣèrànlọ́wọ́

Kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé míì tá à ń lò fún ìjọsìn máa ń gba pé ká ṣe àwọn iṣẹ́ kan tó léwu. Torí náà, àwọn tó ń lọ́wọ́ nínú irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra gidigidi. Bó o bá mọyì àwọn ìlànà Bíbélì, tó ò ń ṣègbọràn sáwọn ìlànà tá a gbé kalẹ̀ fún ṣíṣe iṣẹ́ náà, tó o sì ń fọgbọ́n ṣiṣẹ́, wàá yẹra fún ewu, wàá sì dáàbò bo àwọn míì pẹ̀lú lọ́wọ́ ewu.

Kí ló fà á tá a fi fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn ààbò? Ìfẹ́ ni. Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ fún Jèhófà mú ká ka ẹ̀mí sí pàtàkì bí Ọlọ́run ṣe kà á sí pàtàkì. Ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn kì í jẹ́ ká fi àìbìkítà ṣe ohunkóhun tó lè pa wọ́n lára. (Mát. 22: 37-39) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa kí àwọn tó wà ní ibi tí a ti ń kọ́lé lè máa wà ní “àlàáfíà” àti láìséwu.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Fi Àkàbà Ṣiṣẹ́ Láìséwu,” ní ojú ìwé 30.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Bó O Ṣe Lè Fi Àkàbà Ṣiṣẹ́ Láìséwu

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] òṣìṣẹ́ tó ṣèṣe torí pé wọ́n já bọ́ látorí àkàbà. Ní àfikún sí ìyẹn, nǹkan bí àádọ́jọ [150] èèyàn míì ló tún já bọ́ látorí àkàbà tí wọ́n sì kú. Ibi yòówù kó o máa gbé, iṣẹ́ yòówù kó o máa ṣe, àwọn ìlànà díẹ̀ nìyí tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa já bọ́ látorí àkàbà.

◇ Má ṣe lo àkàbà tó ń mì jẹ̀gẹ̀jẹ̀gẹ̀ tàbí èyí tó ti bà jẹ́, má sì ṣe tún irú àkàbà bẹ́ẹ̀ ṣe. Ńṣe ni kó o ṣíwọ́ lílò ó.

◇ Gbogbo àkàbà ló ní ìwọ̀n ohun tí wọ́n lè gbé. Rí i dájú pé ìwọ àti ohun èlò tó o fẹ́ gbé gun àkàbà kò tẹ̀wọ̀n ju ohun tí àkàbà náà lè gbé lọ.

◇ Orí ilẹ̀ pẹrẹsẹ, tó le dáadáa ni kó o gbé àkàbà rẹ lé. Má ṣe gbé e sí ibi tí á ti máa mì, bí orí igi tí wọ́n tò kalẹ̀ tàbí orí korobá àtàwọn àpótí.

◇ Ńṣe ni kó o dojú kọ àkàbà tó o bá ń gùn ún tàbí tó o bá ń sọ̀ kalẹ̀ látorí rẹ̀.

◇ Má ṣe dúró sórí ìdásẹ̀lé méjì tó wà lókè pátápátá lára àkàbà èyíkéyìí, má sì ṣe jókòó lé e.

◇ Bó o bá máa lo àkàbà láti gun orí òrùlé, láti sọ̀ kalẹ̀ láti orí òrùlé tàbí láti ṣiṣẹ́ ní ibì kan tó ga, rí i pé àkàbà náà fi mítà kan, ìyẹn nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta, ga ju ibi tó ti fara ti òrùlé tàbí ibi tí o ti máa sọ̀ kalẹ̀ láti orí àkàbà náà. Kí ẹsẹ̀ àkàbà náà má bàa yẹ̀ kúrò nílẹ̀, gbìyànjú láti fi okùn so ó mọ́lẹ̀ tàbí kó o kan igi mọ́lẹ̀ níwájú ibi tó dúró lé. Bí o kò bá lè ṣe èyíkéyìí nínú méjèèjì, jẹ́ kí ẹnì kan bá ẹ dì í mú nígbà tó o bá wà lórí rẹ̀. Fi nǹkan so àkàbà náà lókè kó má bàa yẹ̀ ṣubú.

◇ Má ṣe lo ìdásẹ̀lé àkàbà gẹ́gẹ́ bí ibi tó o máa to pákó sí láti lè dúró lé e lórí bó o bá ń ṣiṣẹ́.

◇ Bó o bá ń nàgà nígbà tí ò ń ṣiṣẹ́ lórí àkàbà, àkàbà náà ò ní dúró dáadáa. Torí náà, má ṣe nawọ́ mú nǹkan tó jìn sí ẹ bó o bá wà lórí àkàbà, torí pé ó léwu. Ńṣe ni kó o máa gbé àkàbà náà sún mọ́ ibikíbi tó o bá ti fẹ́ ṣiṣẹ́.

◇ Bí o bá ní láti lo àkàbà níwájú ilẹ̀kùn tí wọ́n tì pa, gbé àmì ìkìlọ̀ síwájú ilẹ̀kùn náà kó o sì ti ilẹ̀kùn náà pa. Bí kò bá ṣeé ṣe láti ti ilẹ̀kùn náà pa, wá ẹnì kan tó máa dúró síbẹ̀ láti máa darí àwọn tó bá fẹ́ gba ibẹ̀.

◇ Kí ẹni méjì má ṣe gun àkàbà kan ṣoṣo àyàfi tó bá jẹ́ èyí tí òṣìṣẹ́ méjì lè wà lórí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. b

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Àfikún ìránnilétí nípa bó o ṣe lè máa ṣiṣẹ́ lórí àkàbà tún wà nínú Jí! ti February 8, 2000, ojú ìwé 22 sí 24.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Nínú Òfin Mósè, ẹni tí ilé rẹ̀ bá ní òrùlé pẹrẹsẹ gbọ́dọ̀ ṣe ìgbátí yí òrùlé náà ká