Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilé Ìṣọ́ Tá A Fi Èdè Gẹ̀ẹ́sì Tó Rọrùn Kọ

Ilé Ìṣọ́ Tá A Fi Èdè Gẹ̀ẹ́sì Tó Rọrùn Kọ

Ilé Ìṣọ́ Tá A Fi Èdè Gẹ̀ẹ́sì Tó Rọrùn Kọ

INÚ wa dùn láti jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé bẹ̀rẹ̀ látorí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, a óò tún máa tẹ ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ míì tí a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ. Ìgbà kan náà la ó máa tẹ ẹ̀dá Ilé Ìṣọ́ méjèèjì jáde lóṣù. Ọdún kan la fẹ́ fi dán ìṣètò tuntun yìí wò ká tó lè mọ̀ bóyá yóò máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe gbogbo àpilẹ̀kọ inú ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ la ó máa gbé jáde nínú ẹ̀dà tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ. Àmọ́ yóò máa ní àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Yóò sì tún máa ní mélòó kan lára àwọn àpilẹ̀kọ yòókù, bí àyè bá ṣe wà sí. Ó dá wa lójú pé ẹ̀dà tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ yìí á mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì máa túbọ̀ lóye àwọn ìsọfúnni tá à ń rí gbà nípasẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kí nìdí tá a fi fẹ́ láti máa tẹ ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ?

Ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Fíjì, Gánà, Kẹ́ńyà, Làìbéríà, Nàìjíríà, Papua New Guinea àti erékùṣù Solomon Islands, Gẹ̀ẹ́sì ni èdè àjùmọ̀lò tí àwọn ará wa máa ń sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè ìbílẹ̀ míì lè wà tí àwọn ará wa yìí ń sọ, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n sábà máa ń lò láti darí àwọn ìpàdé ìjọ àti lóde ẹ̀rí. Àmọ́, èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń sọ rọrùn ju èyí tá a fi ń kọ Ilé Ìṣọ́ lọ. Bákan náà, àwọn míì wà lára àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè míì tí wọ́n ti gbọ́dọ̀ máa lo èdè Gẹ̀ẹ́sì bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè náà. Àti pé, kò sí ìpàdé kankan tí wọ́n ń ṣe ní èdè ìbílẹ̀ wọn.

Àwọn àpilẹ̀kọ tá à ń kà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ni ọ̀nà pàtàkì tí à ń gbà rí oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sí àkókò jẹ déédéé. Torí náà, kí gbogbo àwọn tó ń pésẹ̀ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè jàǹfààní látinú àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ la ṣe fẹ́ máa tẹ Ilé Ìṣọ́ tí a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ. Èèpo ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ máa tẹ̀ yìí máa yàtọ̀. Àmọ́, àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀, tó fi mọ́ àwọn ìpínrọ̀, ìbéèrè fún àtúnyẹ̀wò àtàwọn àwòrán kò ní yàtọ̀ sí ti ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ará á lè lo èyí tí wọ́n bá fẹ́ nínú ẹ̀dà méjèèjì wọ́n á sì lè dáhùn ìbéèrè nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Bí ẹ bá wo ìsàlẹ̀ ojú ìwé yìí ẹ máa rí ìyàtọ̀ tó wà nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì tá a lò fún ẹ̀dà ti tẹ́lẹ̀ àti ẹ̀dà tá a mú Gẹ̀ẹ́sì rẹ̀ rọrùn. Inú ìpínrọ̀ kejì nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé ìròyìn yìí la ti mú àpẹẹrẹ náà wá.

A retí pé Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ yìí ni Jèhófà máa fi dáhùn àdúrà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbà pé: “Mú mi lóye, kí n lè kọ́ àwọn àṣẹ rẹ.” (Sm. 119:73) Ó dá wa lójú pé ìṣètò yìí á mú kó túbọ̀ rọrùn fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn ọmọdé tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti máa múra sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. A dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà torí pé “ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará,” ti mú kó máa lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu.—1 Pét. 2:17; Mát. 24:45.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà