Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Ayọ̀ Nínú “Àǹfààní Ìfúnni Onínúrere”?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Ayọ̀ Nínú “Àǹfààní Ìfúnni Onínúrere”?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Ayọ̀ Nínú “Àǹfààní Ìfúnni Onínúrere”?

Ọ̀LÀWỌ́ ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n wà ní ìlú Fílípì, wọ́n máa ń ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́, àwọn èèyàn sì mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀. Nínú lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ sí wọn, ó sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín nínú gbogbo ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún gbogbo yín, bí mo ti ń ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi pẹ̀lú ìdùnnú, nítorí ìrànlọ́wọ́ fún ìtìlẹyìn tí ẹ ti ṣe fún ìhìn rere láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di ìṣẹ́jú yìí.” (Fílí. 1:3-5) Pọ́ọ̀lù rántí dáadáa pé nígbà tí Lìdíà àti agbo ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ mú kó rọ Pọ́ọ̀lù pé kí òun àtàwọn tí wọ́n jọ ń wàásù wá sílé òun.—Ìṣe 16:14, 15.

Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà tí ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní ìlú Fílípì fi kó ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Pọ́ọ̀lù nígbà méjì, níbi tó ti lọ lo ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan pẹ̀lú àwọn ará ní ìlú Tẹsalóníkà, èyí tó fi nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà jìn sí ìlú Fílípì. (Fílí. 4:15, 16) Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn ará Fílípì àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ ará Makedóníà wà nínú ìpọ́njú àti “ipò òṣì paraku,” wọ́n gbọ́ nípa àìní àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ní Jerúsálẹ́mù wọ́n sì fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí i pé èyí “ré kọjá agbára wọn gan-an.” Síbẹ̀, ó kọ̀wé pé: “[Wọ́n], ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere.”—2 Kọ́r. 8:1-4; Róòmù 15:26.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn táwọn ará Fílípì ti kọ́kọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni, wọ́n ṣì ń fi irú ìwà ọ̀làwọ́ yẹn han. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, wọ́n rán Ẹpafíródítù, ẹni tó rìnrìn-àjò ọ̀rìn-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó dín mẹ́ta [1,287] kìlómítà lórí ilẹ̀ àti lórí omi, pé kó lọ gbé ẹ̀bùn fún àpọ́sítélì náà. Ó ṣe kedere pé àwọn ará Fílípì fẹ́ láti pèsè ohun tí Pọ́ọ̀lù nílò fún un kó bàa lè máa bá a nìṣó láti fún àwọn ará níṣìírí kó sì máa wàásù, kódà nígbà tó wà lẹ́wọ̀n.—Fílí. 1:12-14; 2:25-30; 4:18.

Lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ kà á sí àǹfààní láti máa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run nípa yíyọ̀ǹda àkókò, okun àti owó wọn. Àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lọ́wọ́ nínú ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa yìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn Ọ̀nà Táwọn Kan Ń gbà Ṣètọrẹ

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ

Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tí wọ́n á máa fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn. O sì lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. (O tún lè fi ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn nísàlẹ̀ yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.) Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí wa, “Watch Tower” ni kó o kọ sórí rẹ̀ pé kí wọ́n san án fún. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ. Kí o sì kọ lẹ́tà ṣókí mọ́ ohun tó o fẹ́ fi ránṣẹ́ láti fi hàn pé ẹ̀bùn ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́.

ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fowó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan (fixed deposit), tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ Watch Tower láti máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.

Ìpín Ìdókòwò (Shares), Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò (Debenture Stocks) àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó (Bonds): A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ. A sì lè ní kí ẹ̀tọ́ náà di ti Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni.

Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún Watch Tower, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbé inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilẹ̀ tàbí ilé èyíkéyìí di èyí tó o fi ta wá lọ́rẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé Watch Tower ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Àwọn ọrẹ tá a mẹ́nu bà wọ̀nyí lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “ọrẹ téèyàn wéwèé” gba pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà fara balẹ̀ wéwèé wọn kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o fi nọ́ńbà tẹlifóònù tó wà níbi àdírẹ́sì náà pè wá, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

Jehovah’s Witnesses

P.M.B. 1090,

Benin City 300001,

Edo State, Nigeria.

Nọ́ńbà tẹlifóònù wa ni: 07080662020