Ọmọbìnrin Kan Lo Ìdánúṣe
Akéde onítara ni María Isabel. Ó ń gbé ní ìlú San Bernardo, tó wà ní orílẹ̀-èdè Chile, ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Òun àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Mapuche. Gbogbo ìdílé wọn lápapọ̀ ń sapá gidigidi kí wọ́n lè dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ tí wọ́n á ti máa sọ èdè Mapuche, tí wọ́n tún ń pè ní Mapudungun.
María Isabel gbọ́ pé wọ́n máa sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi ní èdè Mapudungun. Ó tún gbọ́ pé ẹgbẹ̀rún méjì ìwé ìkésíni lédè náà ni wọ́n máa pín. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ohun tó lè ṣe. Ó rántí àwọn ọ̀dọ̀ Kristẹni kan tí wọ́n ti wàásù fún àwọn ọmọ iléèwé wọn àti àwọn olùkọ́ wọn rí, tí wọ́n sì ṣe àṣeyọrí sí rere. Torí náà, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé ó wu òun láti fi àwọn ìwé ìkésíni náà pé àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn òbí rẹ̀ sì sọ fún un pé kó lọ ronú sí ọ̀nà tó lè gbà pín ìwé ìkésíni náà ní iléèwé. Báwo ló ṣe fẹ́ ṣe é?
Ó kọ́kọ́ lọ tọrọ àyè lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ iléèwé pé kí wọ́n jẹ́ kí òun lẹ ìwé ìkésíni kan mọ́ ibi àbáwọlé iléèwé náà. Àwọn aláṣẹ iléèwé náà gbóríyìn fún un pé ó lo ìdánúṣe láti ṣe ohun tó tọ́, wọ́n sì yọ̀ǹda fún un. Kódà, láàárọ̀ ọjọ́ kan nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ iléèwé wà lórí ìlà, ọ̀gá iléèwé náà sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú ìwé ìkésíni náà!
Lẹ́yìn náà, María Isabel bẹ àwọn aláṣẹ iléèwé pé kí wọ́n jẹ́ kí òun bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀ ní kíláàsì kọ̀ọ̀kan. Wọ́n tún gbà fún un. Tó bá ti dé kíláàsì kan, á ní kí olùkọ́ jẹ́ kí òun béèrè bóyá a rí lára wọn tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Mapuche. Ó ní: “Èrò mi ni pé gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Mapuche tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà kò ní ju mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ. Àmọ́, wọ́n pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí mo fún ní ìwé ìkésíni náà to àádọ́jọ [150]!”
“ÀGBÀLAGBÀ LÓ RÒ PÉ ÒUN MÁA RÍ”
Obìnrin kan rí ìwé ìkésíni náà ní ibi àbáwọlé iléèwé náà. Ó wá béèrè bóyá òun lè rí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń fi ìwé ìkésíni náà pé àwọn èèyàn fún. Ẹnú yà á gan-an nígbà tó rí i pé ọmọbìnrin tí ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ ni wọ́n ní kóun lọ bá! María Isabel sọ pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pé: “Àgbàlagbà ló rò pé òun máa rí.” Lẹ́yìn náà, ó fún un ní ìwé ìkésíni kan, ó sì ṣe àlàyé ṣókí fún un. Ó wá ní kí obìnrin náà sọ ibi tó ń gbé fún òun, kí òun àti ìyá òun lè wá bá a sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Inú àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ogún tó wà ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè Mapudungun dùn gan-an láti rí obìnrin náà. Òun àtàwọn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Mapuche ni wọ́n wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn akéde ìjọ náà sì ti ń pọ̀ sí i báyìí.
Yálà o jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ǹjẹ́ ìwọ náà lè lo ìdánúṣe láti pe àwọn ọmọ iléèwé rẹ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ wá síbi Ìrántí Ikú Kristi? Àbí, o lè pè wọ́n láti wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn tàbí kó o pè wọ́n wá sí àpéjọ àgbègbè? O ò ṣe wo àwọn ìtẹ̀jáde wa, kó o sì ka ìrírí àwọn tó ti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí? Bákan náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Tó o bá lo irú ìdánúṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ó máa yọrí sí rere. Ìyẹn á sì mú inú rẹ dùn.