Jẹ́ Onígboyà, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!
“Jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.”—JÓṢ. 1:9.
1, 2. (a) Kí la nílò ká bàa lè kojú àwọn àdánwò? (b) Kí ni ìgbàgbọ́? Ṣàpèjúwe.
IṢẸ́ ÌSÌN Jèhófà máa ń mú ká láyọ̀. Síbẹ̀, àwa náà máa ń dojú kọ ìṣòro bíi ti gbogbo aráyé. Àwọn alátakò sì lè fìyà jẹ wá “nítorí òdodo.” (1 Pét. 3:14; 5:8, 9; 1 Kọ́r. 10:13) Ká bàa lè kojú àwọn àdánwò, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà.
2 Kí ni ìgbàgbọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Héb. 11:1) A lè fi ìgbàgbọ́ wé ìwé tó ní òǹtẹ̀ ìjọba. Ọkàn ẹni tí wọ́n bá fún ní irú ìwé bẹ́ẹ̀ á balẹ̀ pé ohun tí wọ́n torí rẹ̀ fún òun ní ìwé náà ti di tòun. Níwọ̀n bí a sì ti mọ̀ pé ìlérí Ọlọ́run kì í kùnà, ńṣe ló dà bí ìgbà tí Ọlọ́run fún wa ní ìwé tó lù ní òǹtẹ̀ pé ohun tá à ń retí ti di tiwa. Lọ́nà kan náà, ìgbàgbọ́ tá a ní mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí tó ṣe fún wa nínú Bíbélì ṣẹ, “bí a kò tilẹ̀ rí wọn.”
3, 4. (a) Kí ni ìgboyà? (b) Báwo la ṣe lè túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?
3 Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ìgboyà túmọ̀ sí pé kéèyàn lè sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù tàbí kó ṣọkàn akin nígbà tó bá dojú kọ ewu. Torí náà, a lè sọ pé onígboyà lẹni tí kì í bẹ̀rù, tó sì ṣe tán láti jìyà nítorí ohun tó gbà gbọ́.—Máàkù 6:49, 50; 2 Tím. 1:7.
4 Ó dára ká ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ìgbàgbọ́ wa kò tó tàbí pé a ò nígboyà ńkọ́? Ó máa dára ká rántí pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n sì tún jẹ́ onígboyà. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ni pé ká fara balẹ̀ ronú nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.
JÈHÓFÀ WÀ PẸ̀LÚ JÓṢÚÀ
5. Kí ni Jóṣúà gbọ́dọ̀ ṣe kó bàa lè jẹ́ aṣáájú rere?
5 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn. Nígbà yẹn, Mósè ni Jèhófà lò láti dá ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Diu. 34:1-9) Ní báyìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti múra tán láti gba ilẹ̀ Kénáánì. Kí Jóṣúà sì lè jẹ́ aṣáájú rere, ó dájú pé ó nílò ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó tún gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, kó sì jẹ́ onígboyà àti alágbára.—Diu. 31:22, 23.
ilẹ̀ Íjíbítì. Ní ogójì ọdún lẹ́yìn náà, Mósè tó ti pé ọgọ́fà ọdún [120], gun orí Òkè Nébò lọ. Látibẹ̀ ló sì ti rí Ilẹ̀ Ìlérí. Kódà orí òkè náà ló kú sí. Lẹ́yìn ikú Mósè, Jóṣúà di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó jẹ́ ọkùnrin tó “kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n.” (6. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Jóṣúà 23:6, kí la nílò ìgboyà láti ṣe? (b) Kí la rí kọ́ nínú Ìṣe 4:18-20 àti Ìṣe 5:29?
6 Jóṣúà ní ọgbọ́n àti ìgbàgbọ́, ó sì tún jẹ́ onígboyà. Èyí ti ní láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lókun gan-an ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi jagun láti gba ilẹ̀ Kénáánì. Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n ń jagun nìkan ni wọ́n nílò ìgboyà. Ó tún gba ìgboyà kí wọ́n tó lè ṣe ohun tí Ọlọ́run bá ní kí wọ́n ṣe. Nígbà tí Jóṣúà darúgbó, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ẹ sì jẹ́ onígboyà gidigidi láti pa gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mósè mọ́ àti láti tẹ̀ lé wọn nípa ṣíṣàì yí padà kúrò nínú rẹ̀ láé sí ọ̀tún tàbí sí òsì.” (Jóṣ. 23:6) Ó gba ìgboyà kí àwa pẹ̀lú tó lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà gbogbo, pàápàá jù lọ táwọn èèyàn bá ní ká ṣe ohun tí kò bá òfin Ọlọ́run mu. (Ka Ìṣe 4:18-20; 5:29.) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ onígboyà.
BÓ O ṢE LÈ “MÚ KÍ Ọ̀NÀ RẸ YỌRÍ SÍ RERE”
7. Kí Jóṣúà lè jẹ́ onígboyà kó sì ṣe àṣeyọrí sí rere, kí ló gbọ́dọ̀ ṣe?
7 Ká bàa lè ní ìgboyà láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká sì máa fi ohun tá a bá kọ́ sílò. Ohun tí Jèhófà sọ fún Jóṣúà nìyẹn nígbà tó di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó ní: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi láti máa kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ. . . . Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.” (Jóṣ. 1:7, 8) Jóṣúà tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn, ‘ọ̀nà rẹ̀ sì yọrí sí rere.’ Bí àwa náà bá ṣe bíi ti Jóṣúà, a máa túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà, a ó sì ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2013: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.”—Jóṣúà 1:9
8. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2013, ibo la sì ti mú un jáde? Báwo ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
8 Jèhófà tún sọ fún Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” (Jóṣ. 1:9) Jèhófà wà pẹ̀lú àwa náà. Torí náà, àdánwò yòówù kó dé bá wa, ẹ má ṣe jẹ́ ká ‘gbọ̀n rìrì tàbí ká jáyà.’ Àwọn ọ̀rọ̀ tó gbàfiyèsí nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ni: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.” A ti yan ọ̀rọ̀ tí Jóṣúà sọ yìí gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2013. Ó sì dájú pé ọ̀rọ̀ yìí àti àpẹẹrẹ àwọn mìíràn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà máa fún wa lókun gan-an jálẹ̀ ọdún yìí.
WỌ́N FÌGBOYÀ PINNU PÉ TI ỌLỌ́RUN LÀWỌN MÁA ṢE
9. Àwọn nǹkan wo ni Ráhábù ṣe tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?
9 Nígbà tí Jóṣúà rán àwọn amí méjì lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, Ráhábù aṣẹ́wó fi wọ́n pa mọ́, ó sì darí àwọn ọ̀tá wọn gba ibòmíì. Héb. 11:30, 31; Ják. 2:25) Àmọ́ ṣá o, Ráhábù fi iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe sílẹ̀ kó bàa lè ṣe ohun tó wu Jèhófà. Ohun táwọn kan ṣe lóde òní náà nìyẹn. Kí wọ́n lè di Kristẹni, wọ́n ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Wọ́n yí ìgbésí ayé wọn pa dà kí wọ́n lè máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run.
Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Torí náà, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì dá òun àti ìdílé rẹ̀ sí nígbà tí wọ́n pa ìlú Jẹ́ríkò run. (10. Ipò wo ni Rúùtù wà nígbà tó pinnu láti máa sin Jèhófà? Báwo ló ṣe rí ìbùkún Jèhófà gbà?
10 Lẹ́yìn ikú Jóṣúà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Rúùtù. Ọmọ ìlú Móábù ni Rúùtù, ṣùgbọ́n ọmọ Ísírẹ́lì ni ọkọ rẹ̀. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ló jẹ́ kó mọ Jèhófà tó sì pinnu láti sìn ín lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀. Náómì ni orúkọ ìyá ọkọ Rúùtù. Òun, ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì ni wọ́n jọ ń gbé ní ìlú Móábù. Àmọ́, nígbà tí ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì kú, ó pinnu láti pa dà sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà tí wọ́n wà lójú ọ̀nà, Náómì sọ fún Rúùtù pé kó pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìlú Móábù. Dípò tí Rúùtù ì bá fi pa dà, ó sọ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé: “Má rọ̀ mí láti pa ọ́ tì, láti padà lẹ́yìn rẹ . . . Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.” (Rúùtù 1:16) Bí Rúùtù ṣe bá Náómì lọ si Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nìyẹn o. Nígbà tó yá, ìbátan Náómì kan tó ń jẹ́ Bóásì fẹ́ Rúùtù. Nígbà tó ṣe, ó bí ọmọkùnrin kan fún un. Nípasẹ̀ ọmọ yìí ni Rúùtù fi di ìyá ńlá Dáfídì àti ti Jésù. Èyí mú kó ṣe kedere pé àwọn tó bá ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà, máa ń rí ìbùkún Jèhófà gbà.—Rúùtù 2:12; 4:17-22; Mát. 1:1-6.
Ọ̀PỌ̀ FI Ẹ̀MÍ ARA WỌN WEWU!
11. Kí ló fi hàn pé Jèhóádà àti Jèhóṣébà jẹ́ onígboyà? Kí ni ìgboyà wọn yọrí sí?
11 Ìgbàgbọ́ àti ìgboyà wa máa pọ̀ sí i tá a bá rí bí Ọlọ́run ṣe dúró ti àwọn tó fi ìjọsìn rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́, tí wọ́n sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn jẹ wọ́n lógún. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Àlùfáà Àgbà Jèhóádà àti ìyàwó rẹ̀, Jèhóṣébà. Lẹ́yìn ikú Ahasáyà Ọba, Ataláyà tó jẹ́ ìyá ọba, pa àwọn ọmọ ọba, àyàfi Jèhóáṣì. Lẹ́yìn náà, ó fi ara rẹ̀ jẹ ọbabìnrin. Àmọ́, Jèhóádà àti Jèhóṣébà ṣe ohun tó léwu. Wọ́n dáàbò bo Jèhóáṣì tó jẹ́ ọmọ Ahasáyà, wọ́n sì gbé e pa mọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, Jèhóádà fi Jèhóáṣì jọba, ó sì ní kí wọ́n pa Ataláyà. (2 Ọba 11:1-16) Lẹ́yìn ìgbà náà ni Jèhóádà ran Jèhóáṣì Ọba lọ́wọ́ láti tún tẹ́ńpìlì ṣe. Jèhóádà kú lẹ́ni àádóje [130] ọdún, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn ọba “nítorí pé ó ti ṣe rere ní Ísírẹ́lì àti sí Ọlọ́run tòótọ́ àti ilé Rẹ̀.” (2 Kíró. 24:15, 16) Bí Jèhóádà àti ìyàwó rẹ̀ ṣe hùwà akin yìí tún dàábò bo ìlà ìdílé tí Mèsáyà máa gbà wá.
12. Ìwà akin wo ni Ebedi-mélékì hù?
12 Ìránṣẹ́ ni Ebedi-mélékì nínú ilé Sedekáyà Ọba, ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nítorí Jeremáyà. Àwọn ọmọ ọba Júdà fẹ̀sùn èké kan Jeremáyà pé ó ń dìtẹ̀ sí ìjọba. Ọba wá yọ̀ǹda fún wọn pé kí wọ́n lọ ṣe Jeremáyà bí wọ́n ṣe fẹ́. Torí náà, wọ́n gbé e jù sínú kòtò jíjìn kan tí ẹrẹ̀ wà níbẹ̀. Ńṣe ni wọ́n sì fẹ́ kó kú síbẹ̀. (Jer. 38:4-6) Ebedi-mélékì wá lọ bẹ ọba pé kó jẹ́ kí wọ́n tú Jeremáyà sílẹ̀. Ohun tí Ebedi-mélékì ṣe yẹn léwu gan-an torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló kórìíra Jeremáyà. Ṣùgbọ́n, Sedekáyà Ọba gbà pé kí wọ́n tú Jeremáyà sílẹ̀. Ó wá sọ fún Ebedi-mélékì pé kí ó kó ọgbọ̀n ọkùnrin dání kí wọ́n sì lọ yọ Jeremáyà kúrò nínú kòtò náà. Ọlọ́run tipasẹ̀ Jeremáyà ṣèlérí fún Ebedi-mélékì pé òun máa dá ẹ̀mí rẹ̀ sí nígbà táwọn ará Bábílónì bá wá pa ìlú Jerúsálẹ́mù run. (Jer. 39:15-18) Èyí mú kó dájú pé Ọlọ́run máa ń san ẹ̀san rere fáwọn tó bá fi ìgboyà ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
13. Báwo ni àwọn Hébérù mẹ́ta ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ onígboyà? Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn?
13 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún kí Dán. 3:16-18) Bí Ọlọ́run ṣe ṣe ọ̀nà àbáyọ fún àwọn Hébérù mẹ́ta náà múni lórí yá. Ìtàn náà wà nínú Dáníẹ́lì 3:19-30. Ọ̀ràn tiwa lè má gba pé kí wọ́n sọ pé àwọn máa jù wá sínú iná tí ń jó fòfò. Síbẹ̀, ìgbà míì wà tó máa pọn dandan pé ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run nínú àwọn ipò tó le gan-an. Ó dájú pé a máa rí ìbùkún Ọlọ́run tá a bá ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà.
Jésù tó wá sáyé, Ọlọ́run san àwọn Hébérù mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́san rere torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ wọ́n sì tún jẹ́ onígboyà. Nebukadinésárì Ọba pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn sàràkí-sàràkí tó wà ní ìlú Bábílónì kóra jọ láti jọ́sìn èrè gàgàrà kan tó fi wúrà ṣe. Bí ẹnikẹ́ni kò bá forí balẹ̀ fún ère náà, ńṣe ni wọ́n máa jù ú sínú iná tí ń jó fòfò. Àwọn Hébérù mẹ́ta náà sọ fún Nebukadinésárì Ọba tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Ọlọ́run wa, ẹni tí àwa ń sìn lè gbà wá sílẹ̀. Òun yóò gbà wá sílẹ̀ kúrò nínú ìléru oníná tí ń jó àti kúrò ní ọwọ́ rẹ, ọba. Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó di mímọ̀ fún ọ, ọba, pé àwọn ọlọ́run rẹ kì í ṣe èyí tí àwa ń sìn, àwa kì yóò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.” (14. Báwo ni ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì orí 6 ṣe fi hàn pé Dáníẹ́lì jẹ́ onígboyà? Kí ni àbájáde ìgboyà Dáníẹ́lì?
14 Àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì sún Dáríúsì Ọba láti ṣe òfin tó máa kó Dáníẹ́lì sínú wàhálà. Wọ́n sọ fún ọba pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́wọ́ rẹ, ọba, ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún.” Síbẹ̀, Dáníẹ́lì ṣe ohun tó fi hàn pé ó jẹ́ onígboyà. Lẹ́yìn tó gbọ́ pé wọ́n ti ṣe òfin yẹn, “ó wọnú ilé rẹ̀ lọ, fèrèsé ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ wà ní ṣíṣí fún un síhà Jerúsálẹ́mù, àní ní ìgbà mẹ́ta lójúmọ́, ó ń kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó ń gbàdúrà, ó sì ń bu ìyìn níwájú Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe déédéé ṣáájú èyí.” (Dán. 6:6-10) Wọ́n wá gbé Dáníẹ́lì, wọ́n sì jù ú sínú ihò kìnnìún. Àmọ́, Jèhófà gbà á lọ́wọ́ àwọn kìnnìún náà!—Dán. 6:16-23.
15. (a) Báwo ni Ákúílà àti Pírísílà ṣe fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ àti pé àwọn jẹ́ onígboyà? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 13:34 túmọ̀ sí? Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ṣe fi irú ìfẹ́ yìí hàn?
15 Bíbélì sọ pé Ákúílà àti Pírísílà “fi ọrùn ara wọn wewu” nítorí Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 18:2; Róòmù 16:3, 4) Wọ́n fi hàn pé àwọn jẹ́ onígboyà, wọ́n sì ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ nígbà tó sọ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòh. 13:34) Òfin Mósè sọ pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn míì bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀. (Léf. 19:18) Báwo wá ni ohun tí Jésù sọ ṣe jẹ́ àṣẹ “tuntun”? Àṣẹ tuntun ni, torí ó gba pé ká máa fi ìfẹ́ hàn bíi ti Jésù, ká sì múra tán láti kú nítorí àwọn ẹlòmíì bó bá gbà bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ti fi ẹ̀mí ara wọn wewu nítorí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn. Ohun tó sì mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọn kò fẹ́ kí àwọn ọ̀tá fìyà jẹ àwọn ará wọn tàbí kí wọ́n pa wọ́n.—Ka 1 Jòhánù 3:16.
16, 17. Kí ló dán ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni kan wò ní ọ̀rúndún kìíní? Kí ló ń dán ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni kan wò lóde òní?
16 Bíi ti Jésù, àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni kò sin Ọlọ́run míì yàtọ̀ sí Jèhófà. Ìyẹn sì gba ìgboyà. (Mát. 4:8-10) Wọ́n kọ̀ láti sun tùràrí kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún olú-ọba Róòmù. (Wo àwòrán tó wà lójú ìwé 10.) Daniel P. Mannix sọ nínú ìwé rẹ̀ kan pé, “ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn Kristẹni ló sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn.” Ó tún ṣàlàyé pé: “Wọ́n sábà máa ń gbé pẹpẹ kan tí iná ń jó nínú rẹ̀ sí àrọ́wọ́tó wọn láàárín gbọ̀ngàn ìṣeré. Kìkì ohun tí wọ́n sì retí pé kí ẹlẹ́wọ̀n kan ṣe ni pé kó fọ́n tùràrí ṣín-ún sórí iná tó ń jó náà. Wọ́n á wá fún un ní Ìwé Ẹ̀rí Ìrúbọ, yóò sì di òmìnira. Wọ́n á tún fara balẹ̀ ṣàlàyé fún un pé kì í ṣe pé àwọn ní kó jọ́sìn olú-ọba o; ńṣe làwọn kàn fẹ́ kó fi hàn pé òun gba olú-ọba gẹ́gẹ́ bí olórí orílẹ̀-èdè Róòmù. Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Kristẹni kò bọ́hùn.”—A fa ọ̀rọ̀ yìí yọ látinú ìwé, Those About to Die.
17 Bó ṣe rí lóde òní náà nìyẹn. Àwọn ará wa tó wà ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà ìṣàkóso Hitler ní àǹfààní tó pọ̀ láti di òmìnira kí ikú sì yẹ̀ lórí wọn. Ohun tí wọ́n máa ṣe ò ju pé kí wọ́n fọwọ́ síwèé pé àwọn ò sin Jèhófà mọ́. Àmọ́, àwọn díẹ̀ péré ló fọwọ́ sí ìwé náà. Bákan náà, nígbà tí ogun jà ní orílẹ̀-èdè Rwanda, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Tutsi àti Hutu fi ẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n bàa lè dáàbò bo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn. Irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ gba ìgboyà àti ìgbàgbọ́.
MÁA RÁNTÍ PÉ JÈHÓFÀ WÀ PẸ̀LÚ WA
18, 19. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì nípa bá a ṣe lè máa lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
18 Ní báyìí, àǹfààní ńlá la ní láti máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Èyí sì ni iṣẹ́ títóbi jù lọ tí Ọlọ́run gbé fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Àfi ká máa dúpẹ́ pé Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe iṣẹ́ náà! Ó ń “rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Bíi ti Jésù, àwa náà nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ká lè máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn tó jẹ́ onígboyà ni Nóà. Ọlọ́run lè mú káwa náà jẹ́ onígboyà bíi tirẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí oníwàásù òdodo,” ìgboyà rẹ̀ mú kó wàásù nínú ayé tó kún fún “àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run,” tí Ọlọ́run máa fi Ìkún-omi kan tó kárí ayé pa run.—2 Pét. 2:4, 5.
19 Àdúrà máa ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kan tí wọ́n ṣe inúnibíni sí gbàdúrà pé káwọn lè máa bá a nìṣó láti “fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ọlọ́run sì gbọ́ àdúrà wọn. (Ka Ìṣe 4:29-31.) Bí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́ láti máa wàásù láti ilé dé ilé, gbàdúrà pé kí Jèhófà túbọ̀ fún ẹ ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà, yóò sì dáhùn àdúrà rẹ.—Ka Sáàmù 66:19, 20. *
20. Kí ló lè ran àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́wọ́?
20 Kò rọrùn láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ayé búburú yìí. Àmọ́, ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ orí ìjọ Ọlọ́run náà ń ràn wá lọ́wọ́. Àwọn ará wa kárí ayé, tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù méje sì tún wà níbẹ̀ fún wa. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti fi ìgbàgbọ́ hàn, ká sì máa wàásù ìhìn rere. Ẹ sì jẹ́ ká máa rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún yìí tó sọ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.”—Jóṣ. 1:9.
^ ìpínrọ̀ 19 Tún wo àwọn àpẹẹrẹ míì nípa bó o ṣe lè jẹ́ onígboyà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára Gidigidi,” nínú Ilé Ìṣọ́ February 15, 2012.