LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA
Inú Ọba Dùn!
NÍ OṢÙ August, ọdún 1936, ohun kan ṣẹlẹ̀ ní ààfin Ọba Sobhuza Kejì ti ìlú Swaziland tó mú inú rẹ̀ dùn gan-an. Àwọn arákùnrin wa méjì, ìyẹn Arákùnrin Robert àti George Nisbet lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n lè wàásù fún un. Ó kọ́kọ́ gbọ́ orin Ìjọba Ọlọ́run látinú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́. Lẹ́yìn náà, ó gbọ́ àsọyé Arákùnrin J. F. Rutherford tí wọ́n gbà sórí rẹ́kọ́ọ̀dù, inú rẹ̀ sì dùn gan-an. Arákùnrin George wá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn yẹn. Ó ní: “Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tó sọ pé òun fẹ́ ra gbogbo ẹ̀rọ tá a fi ń gbé ohùn sáfẹ́fẹ́, tó fi mọ́ àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù orin àti àsọyé!” Kí ni àwọn arákùnrin náà wá sọ?
Arákùnrin Robert sọ fún ọba náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé wọn kì í ṣe títà torí pé kì í ṣe tàwọn. Ọba wá bi í pé, ‘Ta ló ni ẹ̀rọ àti àwọn àwo rẹ́kọ́ọ̀dù náà?’
Arákùnrin Robert dáhùn pé, “Ọba míì ló ni gbogbo ẹ̀.” Ọba Sobhuza tún bi í pé, ‘Ta ni Ọba náà?’ Arákùnrin Robert dáhùn pé: “Jésù Kristi lorúkọ rẹ̀, òun sì ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run.”
Ọba Sobhuza náà wá fèsì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Áà, Ọba tó ju ọba lọ ni. Mi ò fẹ́ gba ohunkóhun tó bá jẹ́ tiẹ̀.”
Arákùnrin Robert kọ̀wé pé: ‘Ọba náà yàtọ̀ léèyàn, ìwà àti ìṣe rẹ̀ wú mi lórí gan-an. Gẹ̀ẹ́sì dùn lẹ́nu rẹ̀, kò gbéra ga, bọ́rọ̀ ṣe rí lọ́kàn rẹ̀ ló ṣe sọ ọ́, ó sì kóni mọ́ra. Nǹkan bí ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta [45] ni mo lò lọ́dọ̀ rẹ̀, Arákùnrin George sì ń gbé àwo orin sí i níta.’
Arákùnrin Robert ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: ‘Nígbà tó ṣe ní ọjọ́ yẹn, a lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kan tó ń jẹ́ Swazi National School. Ohun kan ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ tó dùn mọ́ wa gan-an. A wàásù fún ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ náà, ó sì tẹ́tí gbọ́rọ̀ wa dáadáa. Nígbà tá a sọ fún un pé a máa fẹ́ kí gbogbo wọn gbọ́ ohun tó wà nínú àwo rẹ́kọ́ọ̀dù wa, inú rẹ̀ dùn, ó sì ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún jókòó sórí koríko láti gbọ́ ọ. Wọ́n sọ fún wa pé ilé ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọkùnrin ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìṣirò, iṣẹ́ àgbẹ̀, bíbójútó ọgbà, iṣẹ́ káfíńtà àti iṣẹ́ ilé kíkọ́; wọ́n sì ń kọ́ àwọn obìnrin ní iṣẹ́ nọ́ọ̀sì, àbójútó ilé àtàwọn iṣẹ́ míì tó wúlò. Ìyá rẹ̀ àgbà ló sì dá ilé ẹ̀kọ́ yẹn sílẹ̀.’ *
Láti ọdún 1933 ni Ọba Sobhuza ti máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n bá lọ sí ààfin rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó pe àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún, pé kí wọ́n wá gbọ́ ìhìn
rere Ìjọba Ọlọ́run tó wà lórí rẹ́kọ́ọ̀dù. Ó san àsansílẹ̀-owó fún ìwé ìròyìn ó sì gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Kò sì pẹ́ tí Ọba náà fi fẹ́rẹ̀ẹ́ ní gbogbo ìwé wa lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàkóso wọn fi òfin de àwọn ìwé wa, ọba náà kò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe àwọn ìwé náà!Ọ̀pọ̀ ọdún ni Ọba Sobhuza Kejì fi ń gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ààfin rẹ̀ tó wà ní Lobamba, kódà ó máa ń pe àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì láti wá gbọ́ àwọn àsọyé Bíbélì wa. Nígbà kan, bí arákùnrin Helvie Mashazi ṣe ń ṣàlàyé Mátíù orí 23, àwọn àlùfáà kan fi ìbínú fò dìde wọ́n sì fẹ́ láti fipá mú kí arákùnrin náà jókòó. Àmọ́, Ọba náà dá sí i, ó sì ní kí Arákùnrin Mashazi máa bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. Ọba tún sọ fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pé kí wọ́n kọ gbogbo ẹsẹ Bíbélì tó lò nínú àsọyé náà sílẹ̀.
Ó tún ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé lẹ́yìn tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́rin kan gbọ́ àsọyé arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan, wọ́n yọ kọ́là ọrùn aṣọ wọn tó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà kúrò, wọ́n sì sọ pé: “A kì í ṣe àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.” Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà náà bóyá ó ṣì ní irú àwọn ìwé tó wà lọ́wọ́ ọba náà.
Láti ọdún 1930 títí di ìgbà tí Ọba náà kú lọ́dún 1982, ó bọ̀wọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sì í jẹ́ kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn torí pé wọn kò lọ́wọ́ sí àwọn ààtò orílẹ̀-èdè Swaziland. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí mọrírì ohun tó ṣe, ikú rẹ̀ sì dùn wọ́n gan-an.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2013, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Swaziland ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] lọ. Àwọn èèyàn tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè náà lé ní mílíọ̀nù kan, torí náà, ní ìpíndọ́gba, akéde kan á wàásù fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [384] èèyàn. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà níbẹ̀ ju igba ó lé ọgọ́ta [260] lọ, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ takuntakun ní àádọ́rùn-ún [90] ìjọ. Ẹgbẹ̀rún méje, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó dín mẹ́rin [7,496] ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2012. Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ṣì wà tí òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ. Ó dájú pé ìpìlẹ̀ tó lágbára ni àwọn tó kọ́kọ́ lọ wàásù ní orílẹ̀-èdè Swaziland láti ọdún 1930 sí 1939 fi lélẹ̀.—Látinú àpamọ́ wa ní orílẹ̀-èdè South Africa.
^ ìpínrọ̀ 8 Ìwé ìròyìn The Golden Age, June 30, ọdún 1937, ojú ìwé 629..