ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ October 2013

Ẹ̀dà yìí jíròrò bí ìṣẹ̀dá ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa agbára àti ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá. Ó tún sọ bá a ṣe lè ṣe ohun tí Jésù sọ nínú ọ̀kan lára àwọn àdúrà onífẹ̀ẹ́ tó gbà.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú ní Philippines.

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó mú kí àwọn kan fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, kí wọ́n ta àwọn ohun ìní wọn, tí wọ́n sì lọ sí àdádó ní orílẹ̀-èdè Philippines

Ìṣẹ̀dá Ń Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa Ọlọ́run Alààyè

Kọ́ bí a ṣe lè mú káwọn èèyàn mọ ẹni tí Ẹlẹ́dàá jẹ́ ká sì tún mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ túbọ̀ lágbára.

“Ẹ Máa Sìnrú fún Jèhófà”

Kí la lè ṣe tá ò fi ní di ẹrú Sátánì? Èrè wo la máa rí bá a ṣe ń fi ìṣòtítọ́ sìnrú fún Jèhófà?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jèhófà Mú Èrè Wá

Ó ti lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́rin tí Malcolm Allen àti Grace ti fi sin Jèhófà. Kà nípa bí wọ́n ṣe rí i pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e.

Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Àdúrà Tí Wọ́n Ronú Jinlẹ̀ Gbà

Kí la rí kọ́ nínú àdúrà tí àwọn ọmọ Léf ì gbà? Báwo la ṣe lè mú kí àdúrà wa túbọ̀ nítumọ̀?

Máa Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Nínú Àdúrà Onífẹ̀ẹ́ Tó Gbà

Nígbà tí Jésù gbàdúrà, ìfẹ́ Jèhófà ló fi ṣáájú tirẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe ohun tó bá àdúrà rẹ̀ mu?

Ṣé Wàá Túbọ̀ Máa Kìlọ̀ Fáwọn Èèyàn?

Kọ́ báwọn kan ṣe lo àǹfààní tí wọ́n ní láti wàásù fáwọn tí wọ́n bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lójoojúmọ́.