Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Máa Sìnrú fún Jèhófà”

“Ẹ Máa Sìnrú fún Jèhófà”

“Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín. . . . Ẹ máa sìnrú fún Jèhófà.”​—RÓÒMÙ 12:11.

1. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo ẹrú? Báwo nìyẹn ṣe yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì rọ̀ wá pé ká ṣe nínú Róòmù 12:11?

BÍ Ọ̀PỌ̀ èèyàn bá gbọ́ pé ẹnì kan jẹ́ ẹrú, èrò tó máa ń wá sọ́kàn wọn ni pé wọ́n ń jẹ gàba lé onítọ̀hún lórí, wọ́n ń ni ín lára, wọ́n sì tún ń hùwà ìkà sí i. Àmọ́ kì í ṣe ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹrú Ọlọ́run nìyẹn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ẹnì kan lè yàn láti máa sin Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tó jẹ́ Ọ̀gá wa. Torí náà, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú ní ọ̀rúndún kìíní pé kí wọ́n máa “sìnrú fún Jèhófà,” ńṣe ló ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Róòmù 12:11) Kí ló túmọ̀ sí láti máa sìnrú fún Ọlọ́run? Báwo la ò ṣe ní di ẹrú Sátánì àti ayé Èṣù yìí? Tá a bá sì sìnrú fún Jèhófà láìyẹsẹ̀, èrè wo la máa rí gbà?

‘MO NÍFẸ̀Ẹ́ Ọ̀GÁ MI NÍ TI GIDI’

2. (a) Kí ló lè mú kí ọmọ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ ẹrú yááfì àǹfààní tó ní láti dòmìnira? (b) Bí ẹrú kan bá gbà kí wọ́n dá etí òun lu, kí nìyẹn fi hàn?

2 Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí fún wa láti jẹ́ ẹrú Jèhófà. Bí wọ́n bá ra Hébérù kan gẹ́gẹ́ bí ẹrú, wọ́n gbọ́dọ̀ dá a sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún keje tó ti ń sin ọ̀gá rẹ̀. (Ẹ́kís. 21:2) Àmọ́, bí ẹrú kan bá nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá rẹ̀ gan-an tó sì fẹ́ láti máa sìn ín nìṣó, Jèhófà ṣe ètò pàtàkì kan tó yọ̀ǹda fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀gá ẹrú náà á mú un wá síbi ilẹ̀kùn tàbí òpó ilẹ̀kùn, á sì fi òòlu lu etí rẹ̀. (Ẹ́kís. 21:5, 6) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé etí ẹrú náà ni Òfin ní kí wọ́n dá lu? Nínú èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ tó dúró fún kéèyàn ṣègbọràn sábà máa ń ní í ṣe pẹ̀lú kéèyàn gbọ́rọ̀ àti kéèyàn tẹ́tí sílẹ̀. Torí bẹ́ẹ̀, bí ẹrú kan bá gbà kí wọ́n dá etí òun lu, ńṣe ló fẹ́ láti máa sin ọ̀gá rẹ̀ nìṣó kó sì máa ṣègbọràn sí i. Ó wá ṣe kedere pé nígbà tá a ya ara wá sí mímọ́ fún Jèhófà ńṣe là ń sọ fún un pé a fẹ́ láti máa sìn ín torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

3. Kí nìdí tí àwa Kristẹni fi ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run?

3 Ká tó ṣèrìbọmi la ti pinnu pé Jèhófà la máa sìn, a sì gbà láti jẹ́ ẹrú rẹ̀. Ohun tó mú ká ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ni pé a fẹ́ láti máa ṣègbọràn sí i, ká sì máa ṣe ohun tó fẹ́. Kò sí ẹni tó fipá mú wa láti ṣe ìpinnu yìí. Kódà, bí àwọn ọ̀dọ́ wa ṣe ń ṣèrìbọmi, wọn ò ṣe é torí kí wọ́n lè múnú àwọn òbí wọn dùn, ṣùgbọ́n wọn ṣe é torí pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Torí náà, ohun tó mú kí àwa Kristẹni ya ara wa sí mímọ́ ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Ọ̀gá wa tí ń bẹ lọ́run. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 Jòh. 5:3.

A WÀ LÓMÌNIRA, SÍBẸ̀ A JẸ́ ẸRÚ

4. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè di “ẹrú fún òdodo”?

4 Àfi ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó mú ká jẹ́ ẹrú rẹ̀! Torí pé a ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, a kò sí lábẹ́ àjàgà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ṣì ni wá, a ti fínnúfíndọ̀ pinnu pé àṣẹ Jèhófà àti ti Jésù la ó máa pa mọ́. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé kedere nípa èyí nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ. Ó ní: “Ẹ ka ara yín sí òkú ní tòótọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n alààyè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Lẹ́yìn náà ló wá kìlọ̀ pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i, yálà ti ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ikú níwájú tàbí ti ìgbọràn pẹ̀lú òdodo níwájú? Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n ẹ di onígbọràn láti inú ọkàn-àyà wá sí irú ẹ̀kọ́ tí a fi yín lé lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, níwọ̀n bí a ti dá yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ẹ di ẹrú fún òdodo.” (Róòmù 6:11, 16-18) Ẹ kíyè sí i pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká “di onígbọràn láti inú ọkàn-àyà.” Torí náà, bá a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà mú ká di “ẹrú fún òdodo.”

5. Kí ni gbogbo wa gbọ́dọ̀ bá wọ̀yá ìjà, kí sì nìdí?

5 Bí a tilẹ̀ jẹ́ ẹrú fún òdodo, a gbọ́dọ̀ borí àwọn ohun ìdíwọ́ kan tó máa mú kó ṣòro fún wa láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ. Ohun méjì wà tá a gbọ́dọ̀ bá wọ̀yá ìjà. Èyí àkọ́kọ́ ni àìpé tá a jogún. Pọ́ọ̀lù náà bá àìpé yìí wọ̀yá ìjà, torí ó sọ nínú lẹ́tà rẹ̀ pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” (Róòmù 7:22, 23) Àwa náà ṣì jẹ́ aláìpé, torí náà á gbọ́dọ̀ máa sakun láìdáwọ́ dúró, kí àwọn ìfẹ́ ti ara má bàa borí wa. Àpọ́sítélì Pétérù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni òmìnira, síbẹ̀ kí ẹ di òmìnira yín mú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí bojúbojú fún ìwà búburú, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọ́run.”—1 Pét. 2:16.

6, 7. Báwo ni Sátánì ṣe ń mú kí ayé yìí dà bí ohun tó fani mọ́ra?

6 Ohun kejì tá a máa bá wọ̀yá ìjà ni ayé tí àwọn ẹ̀mí Èṣù ń dárí rẹ̀ yìí. Sátánì tó jẹ́ olùṣàkóso ayé yìí ń lo àwọn ohun ìjà tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ láti bá wa jà kó lè ba ìṣòtítọ́ wa sí Jèhófà àti Jésù jẹ́. Ó ń wá bó ṣe máa mú ká lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ wá di ẹrú rẹ̀. (Ka Éfésù 6:11, 12.) Ọ̀nà kan tí Sátánì ń gbà ṣe èyí ni pé ó máa ń mú kí ayé tó ń darí yìí dà bí ohun tó fani mọ́ra, kó sì máa wù wá láti di apá kan rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù kìlọ̀ fún wa pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.”—1 Jòh. 2:15, 16.

7 Ó ń wu àwọn èèyàn kárí ayé pé kí wọ́n di ọlọ́rọ̀ kí wọ́n sì láásìkí. Sátánì ń mú kí wọ́n gbà pé ó dìgbà tí wọ́n bá lówó lọ́wọ́ kí wọ́n tó lè láyọ̀. Àwọn ilé ìtajà ńláńlá wà káàkiri. Àwọn tó ń polówó ọjà ń mú káwọn èèyàn rò pé àwọn tó bá kó ohun ìní jọ tí wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ló rí ayé wá. Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń bani ṣètò ìrìn-àjò máa ń rọ àwọn èèyàn láti lọ síbi ìgbafẹ́ tó jojúnígbèsè, èyí sì sábà máa ń mú kéèyàn wà lágbo àwọn tí èrò wọn bá ti ayé mu. Ibi yòówù ká yíjú sí, èrò tó gbòde báyìí ni pé ká wá bí nǹkan á ṣe ṣẹnuure fún wa. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, èyí máa ń gba pé kéèyàn ṣe ohun tí ayé ń ṣe.

8, 9. Kí la lè di ẹrú fún tá ò bá ṣọ́ra, kí sì nìdí tó fi léwu?

8 Ní ọ̀rúndún kìíní, Pétérù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni nípa àwọn kan nínú ìjọ tí èrò wọn jọ ti ayé. Ó ní: “Wọ́n ka ìgbésí ayé fàájì ní ìgbà ọ̀sán sí adùn. Wọ́n jẹ́ èérí àti àbààwọ́n, wọ́n ń kẹ́ra bàjẹ́ pẹ̀lú inú dídùn aláìníjàánu nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìtannijẹ wọn bí wọ́n ti ń jẹ àsè pa pọ̀ pẹ̀lú yín. Nítorí tí wọ́n ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tí kò ní èrè, àti nípa àwọn ìfẹ́-ọkàn ara àti nípa àwọn ìwà tí kò níjàánu, àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yèbọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń hùwà nínú ìṣìnà ni wọ́n ń ré lọ. Nígbà tí wọ́n ń ṣèlérí òmìnira fún wọn, àwọn fúnra wọn wà gẹ́gẹ́ bí ẹrú ìdíbàjẹ́. Nítorí ẹnì yòówù tí ẹlòmíràn ṣẹ́pá rẹ̀ ni ẹni yìí sọ di ẹrú.”—2 Pét. 2:13, 18, 19.

9 Téèyàn bá ń tẹ́ “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” lọ́rùn, ìyẹn ò lè sọ onítọ̀hún di òmìnira. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa sọ onítọ̀hún di ẹrú ọ̀gá tí kò ṣeé fojú rí tó ń ṣàkóso ayé yìí, ìyẹn Sátánì Èṣù. (1 Jòh. 5:19) Tá ò bá ṣọ́ra, a lè di ẹrú ọrọ̀ àti ohun ìní tara. Èyí sì léwu, torí pé téèyàn bá ti kó sínú oko ẹrú bẹ́ẹ̀ tán, kì í rọrùn láti jára ẹni gbà.

IṢẸ́ TÓ Ń MÚ ÌTẸ́LỌ́RÙN WÁ

10, 11. Àwọn wo ni Sátánì dìídì ń dájú sọ lónìí? Báwo ni ẹ̀kọ́ ayé ṣe lè kó wọn sí wàhálà?

10 Bí Sátánì ti ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì, àwọn tí kò ní ìrírí ló tún ń wá kiri lónìí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ ló fẹ́ràn láti máa dájú sọ. Inú Sátánì máa ń bà jẹ́ bí ọ̀dọ́ kan, tàbí ẹni yòówù kó jẹ́, bá pinnu láti di ẹrú Jèhófà. Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà yẹsẹ̀, kí wọ́n sì di aláìṣòótọ́.

11 Ẹ jẹ́ ká pa dà sórí ọ̀rọ̀ ẹrú tó gbà pé kí wọ́n dá etí òun lu yẹn. Ó dájú pé ẹrú náà máa jẹ̀rora díẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní pẹ́ tí ara fi máa tù ú. Àmọ́, àpá tó wà ní etí rẹ̀ á ṣì máa fi hàn pé ó ti pinnu láti máa sin ọ̀gá rẹ̀ nìṣó. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe lè nira fún ọ̀dọ́ kan tó bá yàn láti ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn ojúgbà rẹ̀. Èrò tí Sátánì ń gbìn sáwọn èèyàn lọ́kàn ni pé ó dìgbà tí wọ́n bá ní iṣẹ́ tó jọjú nínú ayé burúkú yìí kí wọ́n tó ní ìtẹ́lọ́rùn. Àmọ́, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Ohun tí Jésù sọ ni pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mát. 5:3) Ohun tó wu Ọlọ́run làwa Kristẹni tá a ti ya ara wa sí mímọ́ máa ń fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe ohun tó wu Sátánì. Òfin Jèhófà ló máa ń múnú wa dùn, a sì máa ń ṣe àṣàrò lé e lórí tọ̀sán tòru. (Ka Sáàmù 1:1-3.) Àmọ́, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ táwọn ọmọ ń lọ fún níléèwé lónìí kì í jẹ́ kí àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà nínú wọn fi bẹ́ẹ̀ ráyè láti ṣe àṣàrò kí wọ́n sì bójú tó àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run.

12. Ìpinnu wo ló wà fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí láti ṣe?

12 Ọ̀gá tí kì í ṣe Kristẹni lè máyé nira fún ẹrú kan tó jẹ́ Kristẹni. Torí náà, Pọ́ọ̀lù béèrè nínú lẹ́tà tó kọ́kọ́ kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “A ha pè ọ́ nígbà tí o jẹ́ ẹrú?” Lẹ́yìn náà ló wá fún wọn nímọ̀ràn pé: “Má ṣe jẹ́ kí ó kó ìdààmú-ọkàn bá ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sì tún lè di òmìnira, kúkú yára mú àǹfààní náà lò.” (1 Kọ́r. 7:21) Èyí fi hàn pé ó sàn kí ẹrú kan wá bó ṣe máa di òmìnira. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lónìí, òfin fi dandan lé e pé káwọn èèyàn kàwé débì kan, ó kéré tán. Lẹ́yìn náà, wọ́n lè wá yàn bóyá wọ́n á fẹ́ láti kàwé sí i. Bí Kristẹni kan bá yàn láti kàwé sí i kó bàa lè ní iṣẹ́ tó jọjú nínú ayé yìí, kò ní lè ráyè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:23.

Ọ̀gá wo lo máa sìnrú fún?

ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA LO FẸ́ ÀBÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ TÓ DÁRA JÙ LỌ?

13. Ẹ̀kọ́ wo ló máa ṣe àwa ìránṣẹ́ Jèhófà láǹfààní jù lọ?

13 Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kól. 2:8) “Ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn” tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí máa ń fara hàn nínú èrò tí kò bá ti Ọlọ́run mu tí ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ayé fi ń kọ́ni. Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń kàwé rẹpẹtẹ, èyí táá mú kí wọ́n wulẹ̀ kó ìmọ̀ sórí. Torí náà, bí wọ́n bá gboyè jáde ìwọ̀nba ni iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n máa ń mọ̀ tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ mọ iṣẹ́ ọwọ́ kankan rárá. Èyí á wá jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti fi ìmọ̀ tí wọ́n gbà yìí gbọ́ bùkátà ara wọn. Àmọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń yan ẹ̀kọ́ táá jẹ́ kí wọ́n ní òye tí wọ́n á fi lè máa gbé ìgbé ayé táá jẹ́ kí wọ́n ráyè ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì sọ́kàn pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tím. 6:6, 8) Dípò tí àwọn Kristẹni tòótọ́ á fi máa wá bí wọ́n á ṣe gba oyè rẹpẹtẹ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kí wọ́n lè máa to oyè tí wọ́n gbà sẹ́yìn orúkọ wọn, ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí wọ́n á ṣe túbọ̀ máa wàásù kí wọ́n lè gba àwọn “lẹ́tà ìdámọ̀ràn fún ìtẹ́wọ́gbà,” ìyẹn àwọn tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Ka 2 Kọ́ríńtì 3:1-3.

14. Fílípì 3:8 ṣe sọ, ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo àǹfààní tó ní láti máa sìnrú fún Ọlọ́run àti Kristi?

14 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ọ̀dọ̀ Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ olùkọ́ni ní Òfin àwọn Júù ló ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Bí ìgbà téèyàn lọ sí yunifásítì ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Pọ́ọ̀lù gbà yẹn rí lóde òní. Àmọ́, kí lèrò Pọ́ọ̀lù nígbà tó fi ẹ̀kọ́ náà wé àǹfààní tó ní láti sìnrú fún Ọlọ́run àti Kristi? Ó kọ̀wé pé: “Mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi.” Lẹ́yìn náà ló wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.” (Fílí. 3:8) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí lè ṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ àtàwọn òbí wọn tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nípa lílọ sí ilé ẹ̀kọ́. (Wo àwọn àwòrán.)

JÀǸFÀÀNÍ LÁTINÚ Ẹ̀KỌ́ TÓ DÁRA JÙ LỌ

15, 16. Ẹ̀kọ́ wo ni ètò Jèhófà ń kọ́ wa, kí sì ni ẹ̀kọ́ náà wà fún?

15 Báwo ni nǹkan ṣe rí ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó wà nínú ayé yìí? Ṣé kì í ṣe ibẹ̀ ni wọ́n ti sábà máa ń tanná ran wàhálà tó ń lọ lágbo òṣèlú àti rògbòdìyàn tó ń lọ láwùjọ? (Éfé. 2:2) Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ nínú ètò Jèhófà tó ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ nínú àwọn ìjọ tí àlàáfíà ti ń jọba. Gbogbo wá lè jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹ̀kọ́ tá a dìídì ṣètò tún wà fún àwọn àpọ́n tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà (Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n) àti fún àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà (Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya). Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí ètò Ọlọ́run dá sílẹ̀ yìí ń mú ká lè máa ṣègbọràn sí Ọ̀gá wa ọ̀run, Jèhófà.

16 A lè ṣàwárí àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye nínú àwọn ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index tàbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa tó wà lórí ike pẹlẹbẹ tá à ń fi kọ̀ǹpútà lò, ìyẹn Watchtower Library on CD-ROM. Ètò Ọlọ́run ṣe gbogbo nǹkan yìí ká lè mọ bó ṣe yẹ ká máa sin Jèhófà. Àwọn ìpèsè yìí tún ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 5:20) Èyí á wá jẹ́ kí àwọn náà mọ bí wọ́n ṣe lè kọ́ àwọn míì.—2 Tím. 2:2.

ẸRÚ NÁÀ GBA ÈRÈ

17. Tá a bá yan ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ, èrè wo la máa rí gbà?

17 Jésù sọ ìtàn nípa àwọn ẹrú kan tí ọ̀gá wọn fún ní tálẹ́ńtì. Ọ̀gá àwọn ẹrú náà gbóríyìn fún àwọn méjì tó jẹ́ olóòótọ́ lára wọn, ó sì fi kún iṣẹ́ wọn torí pé wọ́n mú inú rẹ̀ dùn. (Ka Mátíù 25:21, 23.) Tí àwa náà bá yan ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ, a máa láyọ̀, a ó sì rí èrè gbà. Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó rí irú èrè bẹ́ẹ̀ gbà ni Michael. Ó ṣe dáadáa gan-an níléèwé débi pé àwọn olùkọ́ rẹ̀ pè é, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ nípa lílọ sí yunifásítì. Ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí Michael sọ pé kàkà kí òun lọ sí yunifásítì ńṣe lòun máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́ tí òun á sì kọ́ iṣẹ́ tí kò ní gba òun lákòókò púpọ̀. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún un láti máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ kó sì máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ǹjẹ́ ó ṣe Michael bíi pé ó pàdánù ohunkóhun? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀kọ́ tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì torí pé mo jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti ní báyìí tí mo ti di alàgbà nínú ìjọ ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Kò sí bí owó tó lè máa wọlé fún mi ṣe lè tó ìbùkún àti àǹfààní tí mò ń rí báyìí. Inú mi dùn gan-an pé mi ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga.”

18. Kí ló mú kó o yan ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ?

18 Ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ máa ń jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ó sì máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè sìnrú fún Jèhófà. Ó ń mú ká ní ìrètí pé a máa dá wa “sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,” a ó sì wá “ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run” nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Róòmù 8:21) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà fi hàn pé òótọ́ la fẹ́ràn Ọ̀gá wa ọ̀run, Jèhófà.—Ẹ́kís. 21:5.