Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibeere Lati Owo Awon Onkawe

Ibeere Lati Owo Awon Onkawe

Kí la lè ṣe ká lè gba ti àwọn ará wa tí lọ́fíńdà máa ń gbòdì lára wọn rò?

Àwọn tí lọ́fíńdà máa ń dà láàmú ń kójú ìṣòro tó le koko. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí wọ́n lè ṣe sí i kí wọ́n má bàa gbóòórùn lọ́fíńdà bí wọ́n ti ń wà láàárín àwọn èèyàn lójoojúmọ́. Síbẹ̀, àwọn kan ti béèrè bóyá ó ṣeé ṣe ká sọ fáwọn ará pé kí wọ́n má ṣe lo lọ́fíńdà wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni, àwọn àpéjọ wa àti àpéjọ àgbègbè.

Ó dájú pé, kò sí Kristẹni kankan tó máa mọ̀ọ́mọ̀ mú kó ṣòro fún ẹlòmíì láti máa wá sáwọn ìpàdé Kristẹni. Gbogbo wa la nílò ìṣírí táà ń rí gbà láwọn ìpàdé wa. (Héb. 10:24, 25) Torí náà, tí lọ́fíńdà bá ń da ẹnì kan láàmú gidigidi débi pé kì í lè wá sípàdé nítorí ẹ̀, ẹni náà lè fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn alàgbà. Kò bójú mu káwọn alàgbà ṣe òfin fáwọn ará nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa lo lọ́fíńdà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu, àmọ́ àwọn alàgbà lè jẹ́ káwọn ará mọ ìṣòro àìlera táwọn míì nínú ìjọ ní. Àwọn alàgbà lè fi bí ipò nǹkan ti rí nínú ìjọ pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè pinnu láti jíròrò àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípá kókó yìí nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ nígbà Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tàbí kí wọ́n fọgbọ́n ṣèfilọ̀ nípa ọ̀ràn náà fáwọn ará. * Àmọ́ ṣá o, àwọn alàgbà ò lè máa ṣe irú ìfilọ̀ yìí ní gbogbo ìgbà. Torí pé àwọn olùfìfẹ́hàn àti àwọn àlejò tí kò mọ̀ nípa ìṣòro yìí máa ń wà ní àwọn ìpàdé wa, a sì fẹ́ kí ara tù wọ́n láàárín wa. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni rò pé òun ni wọ́n ń fọ̀rọ̀ gún lára torí pé òun lo lọ́fíńdà.

Ní àwọn ìjọ táwọn tí lọ́fíńdà ń dà láàmú bá wà, bí ipò nǹkan bá ṣe rí làwọn alàgbà fi máa pinnu bóyá wọ́n á ṣètò kí àwọn tó ní ìṣòro yìí máa jókòó sí ibì kan tí wọ́n yà sọ́tọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí àpẹẹrẹ, tí yàrá àpérò tó ní ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ bá wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n lè ní kí wọ́n jókòó síbẹ̀ káwọn náà lè gbádùn ìpàdé. Àmọ́, tí wọn ò bá rí ọ̀ràn yìí yanjú tí àwọn kan ò sì lè wá sí ìpàdé nítorí òórùn lọ́fíńdà, á jẹ́ pé ìjọ lè ṣètò bí wọ́n á ṣe gba ohùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé sílẹ̀ káwọn náà lè gbádùn ìpàdé. Ìjọ sì lè ṣètò pé kí wọ́n máa tẹ́tí sílẹ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé lórí tẹlifóònù bí wọ́n ṣe máa ń ṣe fáwọn tí kò lè jáde nílé mọ́.

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti rọ àwọn ará pé tí wọ́n bá fẹ́ lo lọ́fíńdà tí wọ́n bá ń lọ sáwọn àpéjọ àgbègbè, kí wọ́n gba tàwọn míì tí òórùn lọ́fíńdà máa ń dà láàmú rò. Èyí ṣe pàtàkì torí pé a kì í ya ibì kan pàtó sọ́tọ̀ láwọn àpéjọ wa fáwọn tí òórùn lọ́fíńdà máa ń dà láàmú. Àmọ́ ṣá o, a kò sọ pé ìtọ́ni yìí ni kí àwọn ìjọ máa tẹ̀ lé nínú ìpàdé ìjọ o.

Gbogbo wa ni àwọn àbájáde àìpé tá a jogún ń bá fínra. A máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an táwọn míì bá ń sapá láti mú kí nǹkan rọrùn díẹ̀ fún wa! Èyí sì lè gba pé káwọn kan pinnu pé àwọn ò ní lo lọ́fíńdà torí kí arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè wá sí ìpàdé Kristẹni. Ìfẹ́ ló máa mú ká ṣe irú ìpinnu yìí.

Ǹjẹ́ àwọn ìwé ìtàn jẹ́rìí sí i pé Pọ́ńtíù Pílátù gbé láyé rí?

Orúkọ Pílátù ní èdè Látìn ní wọ́n kọ sára òkúta fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ yìí

Àwọn tó ń ka Bíbélì mọ Pọ́ńtíù Pílátù torí pé òun ló gbọ́ ẹjọ́ Jésù, tó sì fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa á. (Mát. 27:1, 2, 24-26) Orúkọ rẹ̀ tún wà nínú àwọn ìwé ìtàn míì tí wọ́n kọ nígbà yẹn. Ìwé The Anchor Bible Dictionary, jẹ́ ká mọ̀ pé àkọsílẹ̀ tí àwọn ìwé ìtàn kọ nípa Pílátù “pọ̀ gan-an, ìsọfúnni tí wọ́n sì kọ nípa rẹ̀ kún rẹ́rẹ́ ju ti àwọn gómìnà yòókù tí wọ́n jẹ́ ará Róòmù tí wọ́n ṣàkóso ní ilẹ̀ Jùdíà.”

Orúkọ Pílátù wà nínú àwọn ìwé tí òpìtàn àwọn Júù tó ń jẹ́ Josephus kọ, ó kọ̀wé nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta pàtó kan tó ti sọ àwọn ìṣòro tí Pílátù ní nígbà tó ń ṣàkóso Jùdíà. Òpìtàn àwọn Júù tó ń jẹ́ Philo ló kọ ìṣẹ̀lẹ̀ kẹrin. Tacitus òǹkọ̀wé ará Róòmù ṣe àkọsílẹ̀ nípa ìtàn àwọn olú ọba Róòmù, òun náà jẹ́rìí sí i pé Pọ́ńtíù Pílátù ló pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù nígbà tí Tìbéríù ń ṣàkóso.

Lọ́dún 1961, àwọn awalẹ̀pìtàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú gbọ̀ngàn ìṣeré àwọn ará Róòmù tó wà nílùú Késáríà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì rí orúkọ Pílátù tí wọ́n kọ gàdàgbà lédè Látìn sára òkúta fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan tí wọ́n ti lò fún nǹkan míì. Àfọ́kù òkúta yìí ló wà nínú àwòrán yìí, àmọ́ ohun tí wọ́n sọ pé ó wà lára òkúta yìí nígbà yẹn ni: “Pọ́ńtíù Pílátù tí ó jẹ́ alákòóso Jùdíà ya ilé yìí sí mímọ́ sí ọlọ́run ọlọ́lá Tìbéríù.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé tẹ́ńpìlì tí wọ́n fi buyì fún Tìbéríù Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù ni ilé yìí.

Ǹjẹ́ ó yẹ kí arábìnrin kan borí rẹ̀ tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi tí arákùnrin wà?

Nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2002, a sọ lábẹ́ ìsọ̀rí “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” pé ó yẹ kí arábìnrin borí rẹ̀ tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi ti ọkùnrin tí ó jẹ́ akéde wà, yálà ọkùnrin náà ti ṣèrìbọmi tàbí kò tí ì ṣèrìbọmi. Nígbà tí a tún gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò dáadáa, a rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe sí ohun tí a sọ tẹ́lẹ̀.

Tí arábìnrin kan bá lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì jẹ́ pé akéde tó ti ṣèrìbọmi ni ọkùnrin tí wọ́n jọ lọ, ó yẹ kí arábìnrin náà borí rẹ̀. Á fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ètò ipò orí tí Jèhófà gbé kalẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni, torí pé ohun tó yẹ kí arákùnrin ṣe ló ń ṣe yẹn. (1 Kọ́r. 11:5, 6, 10) Tí arábìnrin náà bá sì fẹ́, ó lè ní kí arákùnrin tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tó bá kúnjú ìwọ̀n láti ṣe bẹ́ẹ̀, tó sì lè ṣe é.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tí ọkùnrin tó jẹ́ akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi bá tẹ̀ lé arábìnrin kan lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí arákùnrin náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀, tí kò bá borí ní irú ipò yìí kò lòdì sí Ìwé Mímọ́. Àmọ́, àwọn ­arábìnrin kan lè wò ó pé ẹ̀rí ọkàn àwọn ò gbé e pé káwọn má borí kódà bí ọkùnrin tó tẹ̀ lé àwọn ò tiẹ̀ tí ì ṣèrìbọmi, torí náà tí wọ́n bá fẹ́ wọ́n lè borí.

^ ìpínrọ̀ 2 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa kókó yìí, wo àpilẹ̀kọ náà “Helping Those With MCS,” nínú Jí! August 8, 2000, ojú ìwé 8 sí 10 lédè Gẹ̀ẹ́sì.