Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run

Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run

“Wọn kì í ṣe apá kan ayé.”—JÒH. 17:16.

ORIN: 63, 129

1, 2. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, kí sì nìdí tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ máa dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ni àwọn èèyàn máa ń yàn láàyò, kí nìyẹn sì lè yọrí sí?

NÍGBÀ ogun àti láwọn ìgbà míì, ó máa ń pọn dandan fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kí wọ́n sì ta kété sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwọn á jẹ́ adúróṣinṣin, àwọn á sì máa ṣègbọràn sí i. (1 Jòh. 5:3) Láìka ibi tá à ń gbé sí, yálà a jẹ́ olówó tàbí òtòṣì, orílẹ̀-èdè yòówù ká ti wá, tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa, àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run la fẹ́ máa tẹ̀ lé. Jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ borí àjọṣe èyíkéyìí tá a lè ní pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. (Mát. 6:33) Bí àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe jẹ́ adúróṣinṣin yìí gba pé kí wọ́n má ṣe máa dá sí ìjà àti àríyànjiyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé.—Aísá. 2:4; ka Jòhánù 17:11, 15, 16.

2 Ó lè jẹ́ pé ohun mìíràn ni àwọn tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ yàn láàyò, irú bí orílẹ̀-èdè wọn, ẹ̀yà wọn, àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè wọn pàápàá. Bí ẹnikẹ́ni bá ní èrò tó yàtọ̀ sí tiwọn, ó máa ń yọrí sí bíbá ara ẹni díje àti ìfagagbága, ìtàjẹ̀sílẹ̀ tàbí ìpẹ̀yàrun nígbà míì. Àwọn èèyàn máa ń ṣe gbogbo ohun tó bá gbà kí èrò wọn lè borí, èyí sì lè kan àwa tàbí ìdílé wa torí pé inú ayé yìí náà la ṣì ń gbé. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn ní àwòrán rẹ̀, a kì í fẹ́ káwọn èèyàn rẹ́ wa jẹ, látàrí ìyẹn a lè rí àwọn ìpinnu kan tí ìjọba ṣe bí èyí tí kò tọ́ tí kò sì bójú mu. (Jẹ́n. 1:27; Diu. 32:4) Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí la máa ṣe? Tá ò bá ṣọ́ra, àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í fara mọ́ èrò àwọn èèyàn, ká sì máa dá sí àríyànjiyàn tó ń lọ nínú ayé.

3, 4. (a) Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í dá sí àríyànjiyàn tó ń lọ nínú ayé? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àwọn àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn nínú ayé lè máa pàrọwà fún àwọn aráàlú pé kí wọ́n máa dá sí i bí awuyewuye bá ṣẹlẹ̀. Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. A kì í lọ́wọ́ sí àwọn àríyànjiyàn tó ń wáyé lágbo àwọn olóṣèlú inú ayé, a kì í sì í lo ohun ìjà. (Mát. 26:52) A kì í gbà kí ẹnikẹ́ni mú ká gbé orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àṣà ìbílẹ̀ tàbí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù èyíkéyìí nínú ayé Sátánì ga ju òmíràn lọ. (2 Kọ́r. 2:11) Torí pé a kì í ṣe apá kan ayé, a kì í lọ́wọ́ sí awuyewuye tó ń lọ nínú ayé.—Ka Jòhánù 15:18, 19.

4 Àmọ́, torí pé a jẹ́ aláìpé, ó lè ṣòro fún àwọn kan nínú wa láti borí ìwà wa àtijọ́ tó máa ń dá ìyapa sílẹ̀. (Jer. 17:9; Éfé. 4:22-24) Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. A tún máa ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó yẹ kó máa wà lọ́kàn wa àti ohun tó yẹ ká máa fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa ká bàa lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run.

KÍ NÌDÍ TÍ A KÌ Í FI Í DÁ SÍ ÀWỌN ÀRÍYÀNJIYÀN TÓ Ń LỌ NÍNÚ AYÉ

5, 6. Ojú wo ni Jésù fi wo ẹ̀tanú tó gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tó gbé nígbà tó wà láyé, kí sì nìdí?

5 Tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀, tó ò sì mọ ohun tó yẹ kó o ṣe, ó máa dáa kó o bi ara rẹ pé, ‘Ká ní Jésù ni irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, kí ló máa ṣe?’ Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó gbé láàárín àwọn èèyàn tó wá láti àgbègbè tó yàtọ̀ síra, irú bíi Jùdíà, Gálílì, Samáríà àti àwọn ìlú míì. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbọ́nmi-si-omi-ò-to wà láàárín àwọn èèyàn wọ̀nyí. (Jòh. 4:9) Gbọ́nmi-si-omi-ò-to tún wà láàárín àwọn Farisí àti àwọn Sadusí (Ìṣe 23:6-9); ó wà láàárín àwọn èèyàn àti àwọn agbowó orí (Mát. 9:11); ó sì tún wà láàárín àwọn tó lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn Rábì àti àwọn tí kò lọ. (Jòh. 7:49) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, abẹ́ ìjọba Róòmù ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà, inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í sì í dùn láti rí wọn. Ìwàásù Jésù dá lórí ìsìn tòótọ́, ó sì fi hàn pé ìgbàlà pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn Júù, síbẹ̀ kò sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa dá àríyànjiyàn sílẹ̀. (Jòh. 4:22) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n fẹ́ràn àwọn aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn.—Lúùkù 10:27.

6 Kí nìdí tí Jésù ò fi lọ́wọ́ sí ẹ̀tanú tó gbilẹ̀ láàárín àwọn Júù? Ìdí ni pé òun àti Baba rẹ kì í lọ́wọ́ sí àríyànjiyàn tó ń lọ nínú ayé. Nígbà tí Jèhófà lo Ọmọ rẹ̀ láti dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ohun tó ní lọ́kàn ni pé kí wọ́n di púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:27, 28) Ọlọ́run dá èèyàn lọ́nà tí wọ́n á fi lè bí àwọn ọmọ tó máa di onírúurú ẹ̀yà. Jèhófà àti Jésù kì í gbé ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, tàbí èdè kan ga ju òmíràn lọ. (Ìṣe 10:34, 35; Ìṣí. 7:9, 13, 14) Ó pọn dandan pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.—Mát. 5:43-48.

7, 8. (a) Ọ̀rọ̀ wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ fi ọwọ́ pàtàkì mú? (b) Kí ló yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ fi sọ́kàn tó bá kan wíwá ojútùú sí àwọn ìṣòro tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ àti lágbo òṣèlú?

7 Ọ̀rọ̀ kan wà tó yẹ ká fi ọwọ́ pàtàkì mú, ìyẹn ni bí a ó ṣe máa ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run lẹ́yìn. Àríyànjiyàn ti kọ́kọ́ wáyé lórí ọ̀rọ̀ yìí nínú Ọgbà Édẹ́nì nígbà tí Sátánì pe ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso níjà. Ní báyìí, gbogbo wa gbọ́dọ̀ fi hàn bóyá a gbà lóòótọ́ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso ló sàn ju ti Sátánì lọ tàbí kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ǹjẹ́ o fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ dípò kó o máa ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ? Ǹjẹ́ o gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú ìṣòro tó ń bá àwa ẹ̀dá èèyàn fínra? Àbí o gbà pé àwọn èèyàn lè ṣàkóso ara wọn?—Jẹ́n. 3:4, 5.

8 Ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí ló máa sọ bó o ṣe máa dáhùn táwọn èèyàn bá ní kó o dá sí ọ̀rọ̀ kan tó ń jà ràn-ìn. Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn olóṣèlú, àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àti àwọn alátùn-únṣe ìsìn ti ń sapá bóyá wọ́n á lè rí ojútùú sí ìyapa tó máa ń wà. Èrò irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè dáa, kí wọ́n sì fẹ́ ṣe ohun tó tọ́. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé, kó sì rí i dájú pé ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀. Àfi ká yáa jẹ́ kí Jèhófà fi ọwọ́ ara rẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ó ṣe tán, bí àwọn Kristẹni tòótọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá ń wá ojútùú tí wọ́n rò pé ó máa yanjú ìṣòro aráyé, ǹjẹ́ ìjọ ò ní pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ?

9. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìṣòro wo ló wáyé nínú ìjọ Kọ́ríńtì? Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ṣe?

9 Kíyè sí ohun tí àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ kan tó lè fa ìpínyà wáyé nínú ìjọ Kọ́ríńtì. Àwọn kan nínú ìjọ náà ń sọ pé: “‘Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,’ ‘Ṣùgbọ́n èmi ti Àpólò,’ ‘Ṣùgbọ́n èmi ti Kéfà,’ ‘Ṣùgbọ́n èmi ti Kristi.’” Láìka ohun tó fa ìṣòro náà sí, inú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò dùn torí ó mọ̀ pé ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí kò ní dáa. Ó wá bi wọ́n pé ṣé ‘Kristi wà pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ’ ni? Kí ni Pọ́ọ̀lù wá ní kí wọ́n ṣe nípa ọ̀rọ̀ tó lè fa ìpínyà náà? Ó sọ pé: “Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, àti pé kí ìpínyà má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” Lóde òní ńkọ́? Kò yẹ kí ìyapa èyíkéyìí wà nínú ìjọ Kristẹni.—1 Kọ́r. 1:10-13; ka Róòmù 16:17, 18.

10. Àpèjúwe wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni má ṣe dá sí awuyewuye inú ayé?

10 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí ẹ̀tọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aráàlú ní ọ̀run dípò àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Fílí. 3:17-20) * Wọ́n ní láti máa ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi. Àwọn tó jẹ́ ikọ̀ kì í dá sí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n rán wọn lọ. Ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè tiwọn ló máa ń jẹ wọ́n lógún. (2 Kọ́r. 5:20) Ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run náà ni àwọn Kristẹni tó ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, torí náà kò bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n máa dá sí awuyewuye inú ayé.

KỌ́ BÍ WÀÁ ṢE JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ JÈHÓFÀ

11, 12. (a) Kí ló lè mú kó ṣòro fún Kristẹni kan láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run? (b) Ìṣòro wo ni arábìnrin kan dojú kọ, kí ló sì ṣe nípa rẹ̀?

11 Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, àwọn èèyàn tí ìtàn wọn, àṣà ìbílẹ̀ wọn àti èdè wọ́n jọra máa ń gbé pọ̀ bí ọmọ ìyá. Àwọn èèyàn sì máa ń fi ibi tí wọ́n ti wá yangàn. Tí àwọn Kristẹni tòótọ́ bá bára wọn láàárín irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, àfi kí wọ́n kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn kí wọ́n lè ronú lọ́nà tó tọ́ kó má di pé wọ́n á máa bá wọn dá sí awuyewuye tó bá ṣẹlẹ̀. Lọ́nà wo?

12 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Arábìnrin Mirjeta * yẹ̀ wò. Orílẹ̀-èdè tó ń jẹ́ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ ni arábìnrin yìí ti wá. Láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ ọ pé kó kórìíra àwọn tó wá láti ìlú Serbia. Nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú àti pé Sátánì ló ń fa ìṣòro láàárín ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó sapá láti borí gbígbé orílẹ̀-èdè rẹ̀ ga ju òmíràn lọ. Síbẹ̀, nígbà tí àwọn ẹ̀yà kan ń jà ní àdúgbò tí Mirjeta ń gbé, ìkórìíra tó máa ń ní tẹ́lẹ̀ tún pa dà wá sọ́kàn rẹ̀, ìyẹn wá jẹ́ kó ṣòro fún un láti wàásù fún àwọn tó wá láti ìlú Serbia. Àmọ́, ó mọ̀ pé òun ò kàn lè fọwọ́ lẹ́rán, kí òun sì máa retí pé kí ìkórìíra náà kúrò lọ́kàn òun. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè borí ìkórìíra tó wà lọ́kàn òun, kí òun lè máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn òun, kí òun sì lè tóótun láti di aṣáájú-ọ̀nà. Ó sọ pé: “Mo ti rí i pé pípa ọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn mi ni ohun tó tíì ràn mí lọ́wọ́ jù lọ. Tí mo bá wà lóde ẹ̀rí, mo máa ń gbìyànjú láti fìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà, ẹ̀mí ìkórìíra tó wà lọ́kàn mi sì di àfẹ́kù.”

13. (a) Kí ló fà á tí ara arábìnrin kan ò fi gba ohun tí àwọn kan ṣe, àmọ́ kí ló ṣe? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Zoila?

13 Tún ronú nípa ẹnì kan tó ń jẹ́ Zoila, tó wá láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, àmọ́ tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tó wà nílẹ̀ Yúróòpù báyìí. Ó sọ pé àwọn arákùnrin kan wà nínu ìjọ òun tí wọ́n wá láti apá ibì kan ní ìhà Gúúsù Amẹ́ríkà. Ó ní wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ibi tí òun ti wá, nípa àṣà ìbílẹ̀ àti orin àwọn. Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí lo máa ṣe? Ó rọrùn láti rí ìdí tí ara Zoila ò fi gba irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó ṣe ohun tó wúni lórí, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè borí èrò òdì tó wà ní ọkàn òun. Ó dájú pé àwọn kan wà láàárín wa tí wọ́n ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. A ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa fa ìpínyà tàbí gbé ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ láàárín àwọn ará tàbí àwọn tí kì í ṣe ará pàápàá.—Róòmù 14:19; 2 Kọ́r. 6:3.

14. Báwo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn kí wọ́n lè máa ní èrò tó tọ́ nípa ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà?

14 Nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ ẹ tàbí ibi tó o gbé dàgbà, ṣé o ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ tàbí ìlú tó o ti wá? Ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ ṣì wà lọ́kàn rẹ? Kò yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ kí ọwọ́ tí wọ́n fi mú orílẹ̀-èdè wọn máa nípa lórí ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn èèyàn. Àmọ́ kí lo máa ṣe tó o bá kíyè sí i pé o èrò tí kò tọ́ nípa àwọn èèyàn tí orílẹ̀-èdè wọn, àṣà, èdè tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tìẹ? Ó máa dára kó o ṣe àṣàrò lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Wàá rí i pé ó tọ́ kó o ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà àti àwọn kókó tó fara jọ ọ́ tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà ìjọsìn ìdílé. Lẹ́yìn náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà wò ó.—Ka Róòmù 12:2.

Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a máa dúró gbọn-in nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò (Wo ìpínrọ̀ 15, 16)

15, 16. (a) Kí la retí pé kí àwọn èèyàn ṣe tí wọ́n bá rí i pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run? (b) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

15 Bó pẹ́ bó yá, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa bá ara wọn nínú ipò kan tó ti máa pọn dandan pé kí wọ́n dá yàtọ̀ sí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, ọmọléèwé wọn, aládùúgbò wọn, àwọn ìbátan wọn tàbí àwọn ẹlòmíì. (1 Pét. 2:19) Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ dá yàtọ̀. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu bí ayé bá kórìíra wa torí pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, Jésù ti kìlọ̀ fún wa pé wọ́n máa kórìíra wa. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣàtakò sí wa ò mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Àmọ́ ní tiwa, ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.

16 Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a máa dúró gbọn-in nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò. (Dán. 3:16-18) Ìbẹ̀rù èèyàn máa ń nípa lórí tọmọdé tàgbà, àmọ́ ó lè ṣòro fún àwọn ọ̀dọ́ láti dá yàtọ̀ láàárín àwọn ojúgbà wọn. Bí àwọn ọmọ rẹ bá ń dojú kọ ìṣòro bíi kíkí àsíá tàbí àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè, má ṣe jáfara láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà Ìjọsìn Ìdílé, jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n bàa lè fìgboyà kojú àwọn ìṣòro náà. Jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n á ṣe ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lọ́nà tó ṣe kedere àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (Róòmù 1:16) O tún lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ nípa bíbá àwọn olùkọ́ wọn jíròrò àwọn kókó yìí tó bá pọn dandan pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀.

MỌRÍRÌ GBOGBO OHUN TÍ JÈHÓFÀ DÁ

17. Kí ni kò yẹ ká máa ṣe, kí sì nìdí?

17 Òótọ́ ni pé a lè nífẹ̀ẹ́ ilẹ̀, àṣà, èdè àti oúnjẹ tó wà ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà. Síbẹ̀, kò yẹ ká máa ronú pé ohun tá a bá nífẹ̀ẹ́ sí ló dáa jù. Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn onírúurú nǹkan tó dá. (Sm. 104:24; Ìṣí. 4:11) Kí nìdí tá ó fi máa ronú pé ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan ló sàn ju tí àwọn míì lọ?

18. Àǹfààní wo ló wà nínú wíwo nǹkan bí Jèhófà ṣe ń wò ó?

18 Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo onírúurú èèyàn ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ kí wọ́n sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16; 1 Tím. 2:3, 4) Tá a bá gbà pé bí èrò kan tiẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa, ìyẹn ò fi dandan sọ pé kò tọ̀nà, ó máa ṣe wá láǹfààní, á sì jẹ́ ká lè máa wà ní ìṣọ̀kan. Bá a ti ń bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a kò gbọ́dọ̀ máa dá sí awuyewuye tó ń lọ nínú ayé. Kò sí àyè fún kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láàárín wa. Ẹ sì wo bó ṣe yẹ ká kún fún ọpẹ́ tó pé Jèhófà ti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀mí ìgbéraga, ẹ̀mí ìdíje àti ìyapa tó kún inú ayé Sátánì! Onísáàmù náà sọ pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa jẹ́ ẹni àlàáfíà.—Sm. 133:1.

^ ìpínrọ̀ 10 Ìlú Fílípì wà lára àwọn ìlú tí Róòmù ń ṣàkóso. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn tó wà nínú ìjọ náà ti ní ẹ̀tọ́ kan tàbí òmíràn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú Róòmù. Èyí sì mú kí wọ́n ní àwọn àǹfààní kan tí àwọn ará tó kù ò ní.

^ ìpínrọ̀ 12 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.