Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jọ́sìn Jèhófà ní “Àwọn Ọjọ́ Oníyọnu”

Jọ́sìn Jèhófà ní “Àwọn Ọjọ́ Oníyọnu”

ARÁKÙNRIN Ernst tó ti lé ní ẹni àádọ́rin [70] ọdún sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, ó ní: “Àìlera mi máa ń jẹ́ kí nǹkan ṣòro fún mi ní gbogbo ìgbà.” * Ṣé ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀? Tí o bá ti ń dàgbà, tí ara rẹ ò fi bẹ́ẹ̀ le, tí o ò sì lókun nínú bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, wàá túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú ìwé Oníwàásù orí kejìlá. Ẹsẹ kìíní sọ pé ọjọ́ ogbó jẹ́ “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù.” Ìyẹn ò wá sọ pé kó o máa banú jẹ́ o! O ṣì lè gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀ kó o sì máa sin Jèhófà tayọ̀tayọ̀.

JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ O NÍ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA

Ẹ̀yin tí ẹ ti dàgbà nìkan kọ́ lẹ dá wà nínú ìṣòro tí ẹ̀ ń dojú kọ o. Bíbélì mẹ́nu ba àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan tó dàgbà tí wọ́n sì dojú kọ irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ísákì, Jékọ́bù àti Áhíjà kò ríran mọ́ nígbà tó yá. (Jẹ́n. 27:1; 48:10; 1 Ọba 14:4) Sárà sọ pé òun ti “gbó tán.” (Jẹ́n. 18:11, 12) Nígbà tí Dáfídì Ọba darúgbó, ara rẹ̀ kò “móoru” mọ́. (1 Ọba 1:1) Básíláì tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ pàápàá kò mọ adùn oúnjẹ mọ́, kò sì gbádùn ohùn orin mọ́ nígbà tó yá. (2 Sám. 19:32-35) Ábúráhámù àti Náómì náà ní láti fara da ikú ẹnì kejì wọn nínú ìgbéyàwó.—Jẹ́n. 23:1, 2; Rúùtù 1:3, 12.

Kí ló mú kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn tá a dárúkọ yìí máa sin Jèhófà nìṣó, kí wọ́n sì máa láyọ̀? Nígbà tí Ábúráhámù dàgbà ó ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, torí náà ó “di alágbára nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀.” (Róòmù 4:19, 20) Àwa náà nílò ìgbàgbọ́ tó lágbára. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kò sinmi lórí ọjọ́ orí wa, nǹkan tí a lè ṣe tàbí ipò tí a bá wà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí baba ńlá náà Jékọ́bù dàgbà, kò lágbára mọ́, kò ríran kò sì lè dìde kúrò lórí ibùsùn rẹ̀, síbẹ̀ ó fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run. (Jẹ́n. 48: 1-4, 10; Héb. 11:21) Lóde òní ńkọ́? Àwọn míì náà ń fara da irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ines ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93] ní àrùn kan tó ń ba iṣan jẹ́, síbẹ̀ ó sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mò ń rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Gbogbo ìgbà ni mò ń ronú nípa Párádísè. Ìyẹn ló ń fi mi lọ́kàn balẹ̀.” Ẹ ò rí i pé ẹ̀mí tó dáa nìyẹn!

Tí a bá ń gbàdúrà, tí à ń ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí a sì ń pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i. Àgbàlagbà ni wòlíì Dáníẹ́lì, síbẹ̀ ẹ̀ẹ̀mẹta ló máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lójúmọ́, ó sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (Dán. 6:10; 9:2) Opó ni Ánà ó sì ti darúgbó, síbẹ̀ “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ.” (Lúùkù 2:36, 37) Tí a bá ń pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, tí a sì ń lóhùn sí i, ńṣe là ń gbé ara wa àti gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ró. Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba àdúrà rẹ kódà bó ò tiẹ̀ lè ṣe ohun púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ.—Òwe 15:8.

Ẹ máa fún ara yín níṣìírí

Ó máa ń wu àwọn tó ti dàgbà pé kí ojú wọ́n ríran kedere láti kàwé, kí ara wọ́n sì gbé kánkán láti lọ sí ìpàdé, àmọ́ ó máa ń ṣòro, kódà kì í ṣeé ṣe nígbà míì. Tó o bá bá ara rẹ ní irú ipò yìí, kí lo máa ṣe? Lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ fún ẹ lọ́nà tó dáa. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ò lè wá sí ìpàdé máa ń fetí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ láti orí tẹlifóònù. Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] ni Inge. Ṣùgbọ́n láìka ojú rẹ̀ tó ti di bàìbàì sí, ó máa ń fi ìwé onílẹ́tà gàdàgbà tí arákùnrin kan nínú ìjọ bá a tẹ̀ látinú kọ̀ǹpútà múra ìpàdé sílẹ̀.

Ó ṣeé ṣe kí o ní ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní, ìyẹn àkókò. O ò ṣe kúkú máa lò ó láti fi tẹ́tí sí Bíbélì kíkà tí a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì, àsọyé àti àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Bákan náà, o tún lè máa lo àkókò tó o ní láti máa fi gbé àwọn ará ró láti orí tẹlifóònù kí ẹ sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fún ara yín ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.”—Róòmù 1:11, 12.

JẸ́ KÍ ỌWỌ́ RẸ DÍ LẸ́NU IṢẸ́ ÌSÌN ỌLỌ́RUN

Máa wàásù ọ̀rọ̀ náà

Christa ẹni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún [85] sọ pé: “Tí èèyàn ò bá lè ṣe àwọn ohun tó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́, ńṣe ló máa ń ṣe èèyàn bíi pé kò ti ẹ̀ wúlò fún ohunkóhun mọ́.” Kí ni àwọn tó ti dàgbà wá lè ṣe tí wọ́n a fi máa láyọ̀? Peter ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] sọ pé: “Kò yẹ kó o máa rẹ̀wẹ̀sì ṣáá nípa àwọn ohun tí o ò lè ṣe mọ́, ó yẹ kó o máa ronú lórí àwọn nǹkan tó o ṣì lè ṣe tó sì máa fún ẹ láyọ̀.”

Ǹjẹ́ o lè ronú nípa onírúurú ọ̀nà míì tó o lè gbà wàásù? Arábìnrin Heidi ti lé ní ọgọ́rin [80] ọdún báyìí, kò lè wàásù láti ilé dé ilé mọ́, torí náà ó kọ́ bí a ṣe ń fi kọ̀ǹpútà kọ lẹ́tà. Àwọn akéde tó ti dàgbà míì máa ń bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n bá jókòó sí ọgbà ìtura tàbí tí wọ́n bá wà ní ibùdókọ̀. Tó bá jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó lò ń gbé ńkọ́? Ǹjẹ́ o lè wo ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ, kó o sì máa wàásù fún àwọn tó ń tọ́jú ẹ àti àwọn tí ẹ jọ ń gbé níbẹ̀?

Ní ẹ̀mí aájò àlejò

Nígbà tí Dáfídì Ọba darúgbó, ó ti ìsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Ó ṣètò gbogbo ohun èlò ìkọ́lé, ó sì tún rí i dájú pé gbogbo àwọn èèyàn náà kọ́wọ́ ti iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì. (1 Kíró. 28:11–29:5) Ìwọ náà lè kópa kíkún nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Lọ́nà wo? O lè ṣètìlẹyìn fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà tàbí àwọn akéde onítara míì nínú ìjọ rẹ nípa fífún wọn níṣìírí, kó o wá nǹkan fún wọn bó tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn kékeré, tàbí kó o pè wọ́n wá jẹun nílé rẹ. Tó o bá ń gbàdúrà, o lè máa mẹ́nu kan àwọn ọ̀dọ́, àwọn onídìílé, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ alákòókò kíkún, àwọn tó ń ṣàìsàn àti àwọn tí iṣẹ́ ńlá já lé léjìká.

Jèhófà mọyì yín, iṣẹ́ ìsìn yín sì ṣe pàtàkì gan-an lójú rẹ̀. Ó dájú pé Baba wa ọ̀run ò ní pa ẹ̀yin àgbàlagbà tí ẹ jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa tì láé. (Sm. 71:9) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín ó sì mọyì iṣẹ́ ìsìn yín. Láìpẹ́ gbogbo wa máa dàgbà, a ò sì ní máa ní àwọn ìyọnu tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá ní agbára àti ìlera pípé láti máa fi sin Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, títí láé!

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.