Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run àti Pẹ̀lú Màmá Mi

Mo Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run àti Pẹ̀lú Màmá Mi

MÀMÁ mi da ìbéèrè bò mí lọ́jọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bi mí pé: “Kí nìdí tó ò fi ní jọ́sìn àwọn baba ńlá wa? Ṣó ò mọ̀ pé àwọn ló ń dá ẹ̀mí ẹ sí ni? Ṣó o fẹ́ ya abaraámóorejẹ ni? Kí nìdí tó o fi máa pa àṣà ìbílẹ̀ táwọn baba ńlá wa fi lélẹ̀ tì? Tó o bá ló ò jọ́sìn àwọn baba ńlá wa mọ́, ṣé ohun tó ò ń sọ ni pé òmùgọ̀ làwa tá à ń ṣe é.” Lẹ́yìn tí màmá mi sọ̀rọ̀ tán, ńṣe ló bú sẹ́kún.

Màmá mi ò fìbínú bá mi sọ̀rọ̀ báyìí rí. Ó ṣe tán àwọn ni wọ́n ní káwọn Ajẹ́rìí máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe làwọn náà dọ́gbọ́n fìyẹn yẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀. Mi ò kọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu rí, àmọ́ níbi tọ́rọ̀ dé yìí, mi ò rò pé màá lè ṣe ohun tí wọ́n ní kí n ṣe, torí mo fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn. Mo mọ̀ pé kò lè rọrùn, àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́.

MO DI KRISTẸNI

Ẹ̀sìn Búdà tí ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè Japan ń ṣe ni ìdílé wa náà ń ṣe. Àmọ́ oṣù méjì péré làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ tí mo fi gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì. Ohun tí wọ́n kọ́ mi jẹ́ kí n mọ̀ pé mo ní Ọlọ́run ní Baba, torí náà mo fẹ́ mọ̀ ọ́n. Inú èmi àti mọ́mì mi máa ń dùn tá a bá jọ ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí mò ń kọ́. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọ́ Sunday. Bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe ń yé mi sí i, mo sọ fún mọ́mì mi pé mi ò ní máa bá wọn ṣe ààtò ẹ̀sìn Búdà mọ́. Bí wọ́n ṣe yíwà wọn pa dà sí mi nìyẹn. Mọ́mì mi sọ pé: “Etí wo ló ń báni gbọ́ ọ pé ẹnì kan wà nínú ilé wa yìí tí ò sin àwọn baba ńlá wa.” Torí náà wọ́n ní mi ò gbọ́dọ̀ lọ sípàdé mọ́, mi ò sì gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́. Ó yà mí lẹ́nu pé màmá mi lè sọ ohun tí wọ́n sọ yìí! Ṣe ló dà bíi pé àwọn kọ́ ló ń sọ̀rọ̀.

Mo rí i kà nínú ìwé Éfésù orí kẹfà pé Jèhófà fẹ́ kí n máa gbọ́ràn sáwọn òbí mi lẹ́nu. Àmọ́, ibi tọ́rọ̀ náà burú sí ni pé ẹ̀yìn Mọ́mì ni Dádì ń gbè sí. Mo kọ́kọ́ ronú pé tí n bá gba tiwọn, àwọn náà á gba tèmi, àlàáfíà á sì pa dà jọba nínú ìdílé wa. Yàtọ̀ síyẹn, ìdánwò tí màá fi wọ ilé ẹ̀kọ́ girama ti sún mọ́lé, mo sì ní láti múra sílẹ̀ fún un. Torí náà mo gbà láti ṣe ohun tí wọ́n sọ fún oṣù mẹ́ta, àmọ́ mo ṣèlérí fún Jèhófà pé lẹ́yìn oṣù mẹ́ta yẹn, màá tún máa lọ sípàdé.

Ìdí méjì ni ìpinnu tí mo ṣe yẹn ò fi bọ́gbọ́n mu. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé mo rò pé ó ṣì máa wù mí láti sin Jèhófà lẹ́yìn oṣù mẹ́ta. Àmọ́, kíákíá ni ebi oúnjẹ tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ sí í pa mí, àjọṣe tó wà láàárín èmi àti Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í yingin. Ìkejì ni pé Dádì àti Mọ́mì wá túbọ̀ fúngun mọ́ mi pé kí n má sin Jèhófà mọ́.

WỌ́N ṢE ÀTAKÒ SÍ MI ÀMỌ́ JÈHÓFÀ RÀN MÍ LỌ́WỌ́

Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo ti rí ọ̀pọ̀ àwọn ará táwọn ìdílé wọn ń ṣàtakò sí. Wọ́n sì fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́. (Mát. 10:34-37) Wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé tí mi ò bá fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn míì nínú ìdílé wa lè kẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ mi kí wọ́n sì rí ìgbàlà. Torí pé mo fẹ́ máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí i déédéé pé kó ràn mí lọ́wọ́.

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwọn ìdílé mi gbà ṣe àtakò sí mi. Màmá mi gbìyànjú láti bẹ̀ mí kó sì tún yí mi lérò pa dà. Mo máa ń dákẹ́ tí wọ́n bá ti ń bá mi sọ̀rọ̀ torí tí n bá ní kí n dá wọn lóhùn, ńṣe làwa méjèèjì á bẹ̀rẹ̀ sí í bára wa jiyàn. Mo ti wá mọ̀ báyìí pé ká ní a máa ń gbọ́ ara wa yé nígbà yẹn ni, a ò ní máa bára wa jiyàn púpọ̀. Àwọn òbí mi fi kún iṣẹ́ ilé tí mò ń ṣe kí n má bàa máa jáde kúrò nílé. Láwọn ìgbà míì sì rèé, ńṣe ni wọ́n máa tì mí mọ́ta tàbí kí wọ́n má fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ fún mi.

Mọ́mì mi bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ àwọn èèyàn pé kí wọ́n bá mi sọ̀rọ̀ kí n lè yí èrò mi pa dà. Kódà wọ́n tún bá tíṣà mi sọ̀rọ̀, àmọ́ ìyẹn ò dá sí i. Mọ́mì tún mú mi lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá wọn níbi iṣẹ́ kó lè ṣàlàyé fún mi pé kò sí ẹ̀sìn tó dáa. Nílé, Mọ́mì máa ń pe àwọn ẹbí wa lórí fóònù, wọ́n á sì máa bẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omijé lójú pé kí wọ́n bá àwọn bá mi sọ̀rọ̀. Nǹkan tí wọ́n ń ṣe yẹn máa ń múnú bí mi, àmọ́ nípàdé, àwọn alàgbà máa ń gbà mí níyànjú pé kí n máa ronú nípa àwọn tí màmá mi ń tipa bẹ́ẹ̀ wàásù fún.

Nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ yunifásítì ò ṣe yunifásítì ló tún jẹ yọ. Àwọn òbí mi gbà pé ó dìgbà tí wọ́n bá rán mi lọ sí yunifásítì kí n tó lè jéèyàn. Wọ́n gbà pé tí n bá ti gboyè jáde màá ríṣẹ́ gidi. Èmi àtàwọn òbí mi ò tiẹ̀ tó jókòó sọ̀rọ̀ ọ̀hún ní pẹ̀lẹ́tù, torí náà lẹ́tà ni mo máa ń kọ sí wọn kí wọ́n lè mọ ohun tí mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe. Inú bí Dádì gan-an, wọ́n wá lérí pé: “Tó o bá rò pé o lè ríṣẹ́, yáa wá a kí ilẹ̀ ọ̀la tó ṣú, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá kó jáde kúrò nínú ilé yìí ni.” Mo fi ọ̀rọ̀ náà lọ Jèhófà nínú àdúrà. Lọ́jọ́ kejì nígbà tí mo wà lóde ẹ̀rí, àwọn arábìnrin méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní kí n wá máa kọ́ ọmọ àwọn níwèé káwọn sì máa sanwó fún mi, àwọn méjèèjì ò sì bára wọn sọ ọ́ tẹ́lẹ̀. Inú Dádì ò dùn sí bí mo ṣe ríṣẹ́ yìí wọn ò sì bá mi sọ̀rọ̀ mọ́, ṣe ni wọ́n pa mí tì pátápátá. Mọ́mì tiẹ̀ sọ pé ó pé àwọn kí n ya ọ̀daràn ju kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ.

Jèhófà jẹ́ kí n ní èrò tó tọ́, ó sì jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n ṣe

Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé ṣé Jèhófà tiẹ̀ fẹ́ kí n kọ̀rọ̀ sáwọn òbí mi lẹ́nu tó báyìí. Àmọ́, bí mo ṣe túbọ̀ ń gbàdúrà, tí mo sì ń ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ kí n mọ̀ pé ibi tó dáa ni àtakò náà máa já sí àti pé, torí pé ọ̀rọ̀ mi jẹ àwọn òbí mi lógún ni wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn. Jèhófà ló jẹ́ kí n ní èrò tó tọ́, ó sì jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n ṣe. Bákan náà, bí mo ṣe ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé mú kí n fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù gan-an. Torí náà, mo pinnu láti di aṣáájú-ọ̀nà.

IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Nígbà tí mo sọ fún àwọn arábìnrin kan pé mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n mú sùúrù díẹ̀ kí inú àwọn òbí mi fi rọlẹ̀ ná. Mo bẹ Jèhófà pé kó fún mi lọ́gbọ́n, mo tiẹ̀ tún ṣe ọ̀pọ̀ ìwádìí nípa ẹ̀, mo ronú nípa ìdí tí mo fi fẹ́ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, mo sì bá àwọn ará tó nírìírí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Mo wá pinnu pé mo fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Láfikún síyẹn, mo mọ̀ pé tí mo bá tiẹ̀ dá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mo fẹ́ ṣe dúró, ìyẹn ò ní káwọn òbí mi yíwà pa dà.

Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tó kù díẹ̀ kí n jáde ilé ẹ̀kọ́ girama. Lẹ́yìn tí mo ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fúngbà díẹ̀, mo pinnu pé màá lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àmọ́, Mọ́mì àti Dádì ò fẹ́ kí n kúrò nílé. Torí náà, mo dúró títí tí mo fi pé ọmọ ogún ọdún. Kí ọkàn mọ́mì mi lè balẹ̀, mo kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé kí wọ́n jẹ́ kí n lọ máa wàásù ní apá gúúsù ilẹ̀ Japan torí àwọn ẹbí wa wà níbẹ̀.

Inú mi dùn gan-an pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níbi tí mo ti ń sìn ló ṣèrìbọmi. Láàárín ìgbà yẹn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì kí n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi. Àwọn arákùnrin méjì kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wà ní ìjọ tí mo wà. Mo rí ìtara tí wọ́n ní fún iṣẹ́ ìwàásù àti bí wọ́n ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Torí náà mo pinnu láti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Lásìkò yẹn, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni màmá mi ṣàìsàn tó le koko. Ìgbà méjèèjì ni mo pa dà lọ sílé láti tọ́jú wọn. Ó yà wọ́n lẹ́nu pé mo lè wálé, torí náà wọn ò fọwọ́ líle koko mú mi mọ́.

MO RÍ Ọ̀PỌ̀ ÌBÙKÚN GBÀ

Lẹ́yìn ọdún méje, mo gba lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ Atsushi, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí mo sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan. Ó sọ pé òun ń ronú nípa ìgbéyàwó, òun ò sì mọ̀ bóyá mo nífẹ̀ẹ́ òun. Ọkàn mi ò fà sí Atsushi rí, mi ò sì rò pé ọkàn tiẹ̀ náà ń fà sí mi. Lẹ́yìn oṣù kan, mo kọ lẹ́tà pa dà sí i pé màá fẹ́ ká jọ mọra wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àwa méjèèjì wá rí i pé àfojúsùn wa jọra, àwa méjèèjì la fẹ́ ṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún, a sì ṣe tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Nígbà tó yá, á ṣègbéyàwó. Inú mi dùn gan-an pé Mọ́mì àti Dádì àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa wá síbi ìgbéyàwó wa.

Nepal

À ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nìṣó lẹ́yìn ìgbéyàwó wa. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n ní kí Atsushi wá máa ṣe adelé alábòójútó àyíká. Lẹ́yìn ìyẹn, a tún rí ìbùkún míì gbà. A di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, nígbà tó sì yá wọ́n ní ká wá máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Nígbà kan tá a ti bẹ gbogbo ìjọ tó wà láyìíká wa wò tán, a gba ìpè kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Wọ́n bi wá pé ‘ṣé a máa fẹ́ lọ ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Nepal?’

Bí mo ṣe sìn ní onírúurú orílẹ̀-èdè ti jẹ́ kí n mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà

Mi ò mọ bó ṣe máa rí lára àwọn òbí mi tí wọ́n bá gbọ́ pé mò ń lọ gbé níbi tó jìn tóyẹn. Torí náà, mo tẹ̀ wọ́n láago. Dádì ló gbé e, wọ́n wá sọ pé: “Ibi tó dáa lò ń lọ yẹn.” Ní ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀rẹ́ wọn kan ti fún wọn níwèé kan tó sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè Nepal, Dádì sì ti ń ronú pé á dáa téèyàn bá lè gbafẹ́ lọ síbẹ̀.

Àwọn èèyàn Nepal kóni mọ́ra gan-an, à ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa níbẹ̀, àmọ́ a tún rí ìbùkún míì gbà. Orílẹ̀-èdè Bangladesh di ara àyíká wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sún mọ́ orílẹ̀-èdè Nepal gan-an, àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Oríṣiríṣi ọ̀nà là ń gbà wàásù níbẹ̀. Lẹ́yìn ọdún márùn-ún, wọ́n ní ká tún pa dà sí orílẹ̀-èdè Japan, ibẹ̀ la sì wà báyìí tá à ń gbádùn iṣẹ́ arìnrìn-àjò.

Bá a ṣe ṣiṣẹ́ sìn ní orílẹ̀-èdè Japan, Nepal àti Bangladesh ti jẹ́ kí n mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà. Àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àṣà ìbílẹ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan. Gbogbo wọn ló sì yàtọ̀ síra. Mo ti rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ó sì ń bù kún wọn.

Jèhófà ti jẹ́ kí n mọ òun, ó fún mi níṣẹ́ aláyọ̀ ó sì tún fún mi lọ́kọ tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọlọ́run ti jẹ́ kí n ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́, mo sì ti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀ àti pẹ̀lú ìdílé mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi àti mọ́mì mi ti wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ báyìí. Inú mi dùn gan-an pé mo ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú màmá mi.

À ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò