Ṣé Ọ̀rọ̀ Rẹ Yé Ọlọ́run?
OHUN TÁ A KỌ́ LÁRA ÌṢẸ̀DÁ
Ronú ná nípa àjọṣe tímọ́tímọ tó máa ń wà láàárín àwọn ìbejì tó jọra. Wọ́n máa ń sún mọ́ra gan-an. Nancy Segal, tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń ṣèwádìí nípa àwọn ìbejì, tí òun fúnra rẹ̀ sì jẹ́ ìbejì sọ pé: “Àwọn ìbejì míì máa ń mọ bí nǹkan ṣe rí lára ìkejì wọn láì jẹ́ pé ó ṣàlàyé púpọ̀ jù.” Obìnrin kan sọ nípa ara rẹ̀ àti ìkejì rẹ̀ pé: “Kò sí ohun tá ò mọ̀ nípa ara wa.”
Kí ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn yé ara wọn tó bẹ́ẹ̀? Ìwádìí fi hàn pé ibi tí wọ́n dàgbà sí àti bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà lè fà á, àmọ́ olórí ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn méjèèjì ní ìpìlẹ̀ àbùdá tó jọra.
RÒ Ó WÒ NÁ: Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá tó dá ìpìlẹ̀ àbùdá sínú èèyàn mọ̀ wá ju bí ẹnikẹ́ni ṣe lè mọ̀ wá lọ. Abájọ tí onísáàmù náà Dáfídì fi sọ pé: “Ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi. Àwọn egungun mi kò pa mọ́ fún ọ. Nígbà tí a ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀. . . . ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀.” (Sáàmù 139:13, 15, 16) Ọlọ́run nìkan ló mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa látòkèdélẹ̀, òun ni ọ̀rọ̀ wa yé jù lọ, òun ló sì mọ ohun tí ojú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti rí àti ohun táwọn nǹkan yẹn ti mú kó ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí Ọlọ́run ṣe mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wa yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́ WA NÍPA ÒYE ỌLỌ́RUN
Dáfídì sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkèdélẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí. Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, Ṣùgbọ́n, wò ó! Jèhófà, ìwọ ti mọ gbogbo rẹ̀ tẹ́lẹ̀.” (Sáàmù 139:1, 2, 4) Jèhófà mọ àwọn èrò inú wa lọ́hùn-ún, ó sì máa ń fi òye mọ “gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú” wa. (1 Kíróníkà 28:9; 1 Sámúẹ́lì 16:6, 7) Kí ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run?
Kódà tá ò bá tiẹ̀ mọ bá a ṣe fẹ́ sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Ọlọ́run nínú àdúrà, Ẹlẹ́dàá wa ń kíyè sí ohun tá à ń ṣe àti ìdí tá a fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tún mọ àwọn nǹkan rere tó wù wá láti ṣe, kódà tí agbára wa kò bá tiẹ̀ gbé e láti ṣe é. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló fi ìfẹ́ sí wa lọ́kàn, ó sì wù ú láti mọ àwọn èrò rere tó wà lọ́kàn wa àti ohun tó mú ká ṣe ohun kan.—1 Jòhánù 4:7-10.
Kò sí nǹkan tí Ọlọ́run ò mọ̀. Ó mọ ìyà tó ń jẹ wá bí àwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ mọ̀
Bíbélì fi dá wa lójú pé
-
“Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.”—1 PÉTÉRÙ 3:12.
-
Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—SÁÀMÙ 32:8.
ÀÁNÚ ỌLỌ́RUN PỌ̀ GAN-AN
Ṣé a máa lè fara da ìṣòro tá à ń kojú tó bá dá wa lójú pé Ọlọ́run mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Anna láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ, ó ní: “Ìṣòro tó dé bá mi mú kí n bi ara mi pé kí nìdí tí mo fi wà láàyè gan-an. Ọkọ mi ti kú, èmi nìkan sì ni mò ń tọ́jú ọmọbìnrin mi tó ní àìsàn hydrocephalus [tó máa ń jẹ́ kí omi pọ̀ jù nínú ọpọlọ], ìgbà yẹn náà ni wọ́n tún sọ fún mi ní ilé ìwòsàn pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi àtàwọn ọ̀nà ìwòsàn míì tó máa ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora. Kò rọrùn fún mi rárá láti máa bójú tó ara mi àti ọmọ mi ní ilé ìwòsàn kan náà.”
Kí ló jẹ́ kí Anna lè fara da ìṣòro yìí? Ó sọ pé: “Mo máa ń ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Fílípì 4:6, 7 tó sọ pé ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.’ Gbogbo ìgbà tí ẹsẹ Bíbélì yìí bá wá sí mi lọ́kàn ni mo máa ń rántí pé Ọlọ́run mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí mi ju èmi fúnra mi lọ, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tún máa ń fún mi ní ìṣírí nígbà gbogbo.
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara mi ò tíì yá pátápátá, nǹkan ti sàn díẹ̀ fún èmi àti ọmọ mi. Torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa, a kì í ronú òdì tá a bá ní ìṣòro. Jákọ́bù 5:11 jẹ́ kó dá wa lójú pé: ‘Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ni a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.’ ” Jèhófà mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù dáadáa, ó dá àwa náà lójú pé ó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì mọ àwọn ìṣòro tá a ní.