Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Obìnrin Náà Gbàdúrà Àtọkànwá sí Ọlọ́run

Obìnrin Náà Gbàdúrà Àtọkànwá sí Ọlọ́run

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

Obìnrin Náà Gbàdúrà Àtọkànwá sí Ọlọ́run

ỌWỌ́ Hánà dí bo ṣe ń múra sílẹ̀ fún ìrìn àjò tí wọ́n fẹ́ lọ, ìyẹn ló gbà á lọ́kàn. Àkókò ayọ̀ ló yẹ kí àkókò náà jẹ́ nítorí ó jẹ́ àṣà Ẹlikénà, ọkọ rẹ̀, láti máa kó ìdílé rẹ̀ lọ ṣèjọsìn lọ́dọọdún ní àgọ́ ìjọsìn tó wà ní Ṣílò. Àkókò ìdùnnú ni Jèhófà fẹ́ kí àkókò yìí jẹ́. (Diutarónómì 16:15) Kò sí àní-àní pé látìgbà èwe ni inú Hánà ti máa ń dùn sí àwọn àjọyọ̀ yẹn. Àmọ́, àwọn nǹkan ti yí pa dà fún un láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.

Ọlọ́run fi ọkọ tó fẹ́ràn rẹ̀ jíǹkí rẹ̀. Àmọ́ Ẹlikénà ọkọ́ rẹ̀, ní ìyàwó míì. Orúkọ rẹ̀ ni Pẹ̀nínà, ó jọ pé ó ti pinnu láti ba ayọ̀ Hánà jẹ́. Pẹ̀nínà tún ti rí ọ̀nà míì táá fi mú káwọn àjọyọ̀ ọdọọdún pàápàá jẹ́ àkókò ìbànújẹ́ fún Hánà. Báwo ló ṣe ṣe é? Ju gbogbo rẹ̀ lọ, báwo ni ìgbàgbọ́ Hánà nínú Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́ láti borí ìṣòro tó jọ pé ó kọjá agbára rẹ̀ yìí? Tí ìṣòro tó dojú kọ ẹ́ bá ba ayọ̀ rẹ jẹ́, ìtàn Hánà lè jẹ́ ìṣírí fún ẹ.

‘Kí Nìdí Tí Ìbànújẹ́ Fi Dé Bá Ọkàn Rẹ?’

Bíbélì jẹ́ ká mọ ìṣòro ńlá méjì tí Hánà ní nígbèésí ayé rẹ̀. Nǹkan díẹ̀ ló lè ṣe sí ìṣòro àkọ́kọ́ àmọ́ ìṣòro kejì kọjá agbára rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ọkọ rẹ̀ ní ju ìyàwó kan lọ, orogún rẹ̀ sì kórìíra rẹ̀. Èkejì ni pé ó yàgàn. Ipò yìí kò rọrùn rárá fún ìyàwó ilé èyíkéyìí tó ń wá ọmọ, àmọ́ nígbà ayé Hánà àti nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn, àìrí ọmọ bí jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an. Ìdílé kọ̀ọ̀kan fọkàn sí i pé ọmọ àwọn á máa jẹ́ orúkọ ìdílé náà nìṣó tí kò fi ní pa rẹ́. Ẹ̀gàn àti ìtìjú burúkú ni wọ́n kà á sí téèyàn bá yàgàn.

Ì bá rọrùn fún Hánà láti fara da ipò náà ká ní Pẹ̀nínà kò dá kún un. Ìkóbìnrinjọ kò dára rárá. Ohun tó máa ń dá sílẹ̀ ni, ìbánidíje, gbọ́nmi-si-omi-ò-to àti ọgbẹ́ ọkàn. Àṣà yìí kò dára rárá tá a bá fi wé ìlànà níní ìyàwó kan ṣoṣo tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì. a (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Bíbélì kò fara mọ́ ìkóbìnrinjọ, wàhálà tó wà nínú ilé Ẹlikénà jẹ́ ká mọ̀ pé ìkóbìnrinjọ kò dára.

Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, Hánà ni Ẹlikénà fẹ́ràn jù lọ. Ohun tí ìtàn àwọn Júù sọ ni pé Hánà ló kọ́kọ́ fẹ́, láwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ló wá fẹ́ Pẹ̀nínà. Èyí ó wù kó jẹ́, Pẹ̀nínà tó ń jowú Hánà burúkú-burúkú wá onírúurú ọ̀nà láti pọ́n ọn lójú. Ibi tí Pẹ̀nínà ti rọ́wọ́ mú ni pé ó bímọ. Pẹ̀nínà ń bímọ lé ọmọ, bó sì ti ń bí ọmọ kọ̀ọ̀kan ni ìyìn rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Kàkà kó máa káàánú Hánà, kó sì máa tù ú nínú, ńṣe ló ń fi àìrí ọmọ bí gún un lára. Bíbélì sọ pé Pẹ̀nínà mú Hánà bínú gidigidi “nítorí àtimú kí àìbalẹ̀-ọkàn bá a.” (1 Sámúẹ́lì 1:6) Pẹ̀nínà mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe yẹn ni. Ó fẹ́ ba ọkàn Hánà jẹ́ ni, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó jọ pé àkókò tó dára jù lọ fún Pẹ̀nínà láti ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ ni ìgbà tí wọ́n máa ń rìnrìn-àjò ọdọọdún lọ sí Ṣílò láti lọ jọ́sìn. Ẹlikénà fún ọmọ Pẹ̀nínà kọ̀ọ̀kan, ìyẹn “gbogbo ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀,” ní ìpín lára ẹbọ tó rú sí Jèhófà. Àmọ́ ìpín kan ni Hánà tí kò bímọ máa ń gbà. Pẹ̀nínà wá ń ṣe fọ́ńté lójú Hánà, ó sì ń fìyẹn rán an létí pé àgàn ni, èyí sì mú kí obìnrin tí ìbànújẹ́ ti bá yìí bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, kò sì lè jẹun pàápàá. Ó hàn sí Ẹlikénà pé Hánà tó jẹ́ ààyò rẹ̀ ní ìdààmú kò sì jẹun, torí náà, ó gbìyànjú láti tù ú nínú. Ó béèrè pé, “Hánà, èé ṣe tí o fi ń sunkún, èé sì ti ṣe tí o kò fi jẹun, èé sì ti ṣe tí ìbànújẹ́ fi dé bá ọkàn-àyà rẹ? Èmi kò ha sàn fún ọ ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ bí?”—1 Sámúẹ́lì 1:4-8.

Bí Ẹlikénà ṣe rò ó gan-an ló rí, àìrí ọmọ bí ló fa ìbànújẹ́ Hánà. Hánà sì mọyì bó ṣe fi hàn pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ òun. b Àmọ́ ṣá o, Ẹlikénà kò mẹ́nu kan ìwà ìkà tí Pẹ̀nínà hù, bẹ́ẹ̀ ni àkọsílẹ̀ náà kò sọ pé Hánà sọ fún un. Ó ṣeé ṣe kó mọ̀ pé bí òun bá sọ nǹkan tí Pẹ̀nínà ṣe, ńṣe nìyẹn á dá kún ìṣòro náà. Ǹjẹ́ Ẹlikénà ṣe àtúnṣe sí ìṣòro náà? Ṣé ìwà òǹrorò Pẹ̀nínà sí Hánà kò ní máa pọ̀ sí i? Ṣé àwọn ọmọ àtàwọn ìránṣẹ́ obìnrin òǹrorò yìí kò ní máa bá a hùwà ìkà sí Hánà? Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ńṣe ni Hánà á máa rò pé wọ́n ti ta òun nù ní ọ̀ọ̀dẹ̀ ọkọ òun.

Bóyá Ẹlikénà mọ bí ìwà òǹrorò Pẹ̀nínà ti pọ̀ tó tàbí kò mọ̀, Jèhófà Ọlọ́run rí gbogbo rẹ̀. Bíbélì fi gbogbo rẹ̀ hàn kedere. Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tó bá ní owú àti ìkórìíra tí wọ́n kà sí pé kò tó nǹkan. Ní ìdàkejì, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́wọ́ mímọ́ àti ẹni àlàáfíà bíi Hánà lè rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo yóò mú gbogbo ọ̀ràn tọ́ ní àkókò tó tọ́ àti ní ọ̀nà tó fẹ́. (Diutarónómì 32:4) Ó ṣeé ṣe kí Hánà mọ̀ bẹ́ẹ̀, torí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti wá ìrànlọ́wọ́.

“Ìdàníyàn fún Ara Ẹni Kò sì Hàn Lójú Rẹ̀ Mọ́”

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ọwọ́ gbogbo àwọn ará ilé dí bí wọ́n ṣe ń kó àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ lò. Àní gbogbo wọn, títí kan àwọn ọmọdé ni wọ́n ń múra ìrìn àjò náà. Ìrìn àjò tí gbogbo ìdílé náà máa rìn lọ sí Ṣílò yóò ju ọgbọ̀n kìlómítà lọ ní ìgbèríko Éfúráímù olókè. c Tí wọ́n bá fi ẹsẹ̀ rìn, yóò gbà wọ́n ní ọjọ́ kan tàbí méjì. Hánà mọ ohun tí orogún rẹ̀ lè ṣe. Àmọ́, kò dúró sílé. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn olùjọ́sìn Jèhófà títí di òní, pé kò bọ́gbọ́n mu láti jẹ́ kí ìwà àìtọ́ àwọn ẹlòmíràn ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Tá a bá jẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀, a ó pàdánù okun táá mú ká lágbára láti máa fara dà á.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn látàárọ̀ gba ojú ọ̀nà àárín àwọn òkè ńlá wọ̀nyẹn, níkẹyìn wọ́n sún mọ́ Ṣílò, èyí tí àwọn òkè yí ká. Bí wọ́n ti ń sún mọ́ Ṣílò, ó ṣeé ṣe kí Hánà ti ronú gan-an nípa ohun tó máa sọ fún Jèhófà nínú àdúrà rẹ̀. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, gbogbo wọ́n jẹun. Kò pẹ́ tí Hánà fi kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì lọ sí àgọ́ ìjọsìn Jèhófà. Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà wà níbẹ̀, ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì. Àmọ́ nígbà tí Hánà dé tẹ́ńpìlì, àdúrà tó fẹ́ gbà sí Ọlọ́run ló gbà á lọ́kàn, ó dá a lójú pé Ọlọ́run á fetí sí àdúrà òun. Bí ẹnikẹ́ni kò bá lóye ìdààmú tó bá a, Bàbá rẹ̀ ọ̀run á lóye rẹ̀. Inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.

Bí ara Hánà ti ń gbọ̀n bó ṣe ń sunkún, ó bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Ètè rẹ̀ ń gbọ̀n bó ṣe ń sọ bí ìrora náà ṣe rí lára rẹ̀. Ó sì gbàdúrà tó gùn, tó ń tú ọkàn rẹ̀ jáde fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Àmọ́ ṣá o, ó ṣe ju bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kó jọ̀wọ́ fún òun ní ọmọ. Kì í ṣe pé Hánà ń ṣàníyàn láti gba ìbùkún lọ́dọ̀ Ọlọ́run nìkan ni, òun náà tún fẹ́ fún Ọlọ́run ní ohun tó lè fún un. Nítorí náà, ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ó sọ pé bí òun bá bí ọmọ ọkùnrin, òun á fi í sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 1:9-11.

Hánà tipa báyìí fi àpẹẹrẹ rere nípa àdúrà lélẹ̀ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Jèhófà pe àwọn èèyàn rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́ pé kí wọ́n bá òun sọ̀rọ̀ látọkànwá, kí wọ́n sì sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wọn fún òun bí ọmọ tó fọkàn tán òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 62:8; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run, àpọ́sítélì Pétérù kọ ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú yìí nípa àdúrà sí Jèhófà, ó ní: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:7.

Àmọ́ ṣá o, àwa èèyàn kò lóye nǹkan bíi ti Jèhófà, a kò sì lè báni kẹ́dùn bíi tirẹ̀. Bí Hánà ti ń sunkún tó sì ń gbàdúrà, ó gbọ́ ohùn ẹnì kan. Ohùn Élì àlùfáà àgbà tó ń wo Hánà ni. Ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣe bí ọ̀mùtípara? Mú wáìnì rẹ kúrò lára rẹ.” Élì ti ṣàkíyèsí ètè Hánà tó ń gbọ̀n, bó ṣe ń sunkún àti bí ẹ̀dùn ọkàn tó bá a ti pọ̀ tó. Kàkà kó béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀, ńṣe ló parí èrò sí pé obìnrin náà mutí yó.—1 Sámúẹ́lì 1:12-14.

Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ náà á ti dun Hánà tó lákòókò yẹn, pé ẹnì kan fẹ̀sùn kan òun láìsí ẹ̀rí àti pé ẹni tó wà nípò ọ̀wọ̀ ló sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Síbẹ̀, Hánà tún fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa ìgbàgbọ́. Kò jẹ́ kí àìpé ẹ̀dá ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn òun sí Jèhófà. Ó dá Élì lóhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì ṣàlàyé ohun tó ń ṣe é fún un. Élì fi ohùn tútù fèsì lọ́nà tó fi hàn pé ó kábàámọ̀, ó ní: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 1:15-17.

Ipa wo ni ṣíṣí tí Hánà ṣí ọkàn rẹ̀ payá fún Jèhófà tó sì jọ́sìn rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì ní lórí rẹ̀? Àkọsílẹ̀ náà kà pé: “Obìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì jẹun, ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.” (1 Sámúẹ́lì 1:18) Bibeli Mimọ sọ pé: “Kò si fà oju ro mọ.” Ìtura bá Hánà. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbé ẹrù náà fún ẹni tó lágbára jù ú lọ fíìfíì, ìyẹn Bàbá rẹ̀ ọ̀run. (Sáàmù 55:22) Ǹjẹ́ ìṣòro kan wà tó tóbi jù fún Ọlọ́run? Rárá o, kò sígbà kankan rí tí ìṣòro kan tóbi jù fún un!

Nígbà tí ìṣòro bá wọ̀ wá lọ́rùn, tó bò wá mọ́lẹ̀ tàbí tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò, á dára ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà, ká sì sọ̀rọ̀ látọkànwá fún Ẹni tí Bíbélì pè ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Tá a bá fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà, àwa náà lè rí i pé “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” yóò rọ́pò ìbànújẹ́ tá a ní.—Fílípì 4:6, 7.

‘Kò Sí Àpáta Kan Tí Ó Dà Bí Ọlọ́run Wa’

Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, Hánà pa dà lọ sí àgọ́ ìjọsìn pẹ̀lú Ẹlikénà. Ó ṣeé ṣe kó ti sọ fún un nípa ohun tí òun tọrọ àti ẹ̀jẹ́ tó jẹ́, nítorí Òfin Mósè sọ pé ọkọ kan ní ẹ̀tọ́ láti fagi lé ẹ̀jẹ́ kan tí ìyàwó rẹ̀ jẹ́ tí ọkọ náà kò bá fọwọ́ sí i tẹ́lẹ̀. (Númérì 30:10-15) Àmọ́ ọkùnrin olóòótọ́ yẹn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun àti Hánà jọ jọ́sìn Jèhófà ní àgọ́ ìjọsìn kí wọ́n tó pa dà sí ilé.

Ìgbà wo gan-an ni Pẹ̀nínà mọ̀ pé òun kò lè ba Hánà nínú jẹ́ mọ́? Àkọsílẹ̀ náà kò sọ, àmọ́ gbólóhùn náà, “ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́” fi hàn pé inú Hánà bẹ̀rẹ̀ sí í dùn láti ìgbà yẹn lọ. Ohun yòówù kó jẹ́, Pẹ̀nínà rí i láìpẹ́ pé ìwà òǹrorò tóun ń hù kò ṣàṣeyọrí. Bíbélì kò dárúkọ obìnrin náà mọ́.

Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ayọ̀ ọkàn Hánà kún rẹ́rẹ́ lọ́nà tó kọ yọyọ. Ó lóyún! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayọ̀ rẹ̀ pọ̀ jọjọ, kò gbàgbé ẹni tó bù kún rẹ̀. Nígbà tó bí ọmọdékùnrin náà, ó pè é ní Sámúẹ́lì, èyí tó túmọ̀ sí “Orúkọ Ọlọ́run,” ó sì ń tọ́ka sí bí Hánà ṣe ń ké pe orúkọ Ọlọ́run. Lọ́dún yẹn kò bá Ẹlikénà àti ìdílé rẹ̀ rìn lọ sí Ṣílò. Fún ọdún mẹ́ta ló fi wà pẹ̀lú ọmọ náà ní ilé títí dìgbà tó já a lẹ́nu ọmú. Lẹ́yìn náà, ó gbára dì fún ọjọ́ tí ọmọ rẹ̀ àtàtà yìí máa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ó dájú pé kò rọrùn rárá lọ́jọ́ tí ọmọ náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó dá Hánà lójú pé wọ́n á tọ́jú Sámúẹ́lì dáadáa ní Ṣílò, ó sì lè jẹ́ lára àwọn obìnrin tó ń sìn nínú àgọ́ ìjọsìn náà ló máa tọ́jú rẹ̀. Àmọ́ ọmọ ọ̀hún ṣì kéré gan-an, ta ló sì mọ̀ ọ́n wò bí kò ṣe ọlọ́mọ? Láìka gbogbo ìyẹn sí, Hánà àti Ẹlikénà fayọ̀ mú ọmọdékùnrin náà lọ sí tẹ́ńpìlì, wọn ò sì mikàn. Wọ́n rú ẹbọ ní ilé Ọlọ́run, wọ́n sì mú Sámúẹ́lì fún Élì, wọ́n sì rán an létí ẹ̀jẹ́ tí Hánà ti jẹ́ níbẹ̀ láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn.

Lẹ́yìn náà, Hánà gba àdúrà, Ọlọ́run sì rí i pé ó yẹ kí àdúrà náà wà nínú Bíbélì. Bó o ṣe ń ka ọ̀rọ̀ Hánà tó wà ní 1 Sámúẹ́lì 2:1-10, wàá rí bí àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣe fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ jinlẹ̀ gan-an. Ó yin Jèhófà nítorí agbára rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu, nítorí agbára aláìlẹ́gbẹ́ tó ní láti rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀, láti bù kún àwọn tójú ń pọ́n àti láti pani tàbí láti gbani lọ́wọ́ ikú. Hánà yin Bàbá rẹ̀ ọ̀run nítorí ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ìṣòtítọ́ rẹ̀. Abájọ tí Hánà fi sọ pé: “Kò sí àpáta kan tó dà bí Ọlọ́run wa.” Jèhófà ni ẹni tá a lè fọkàn tán pátápátá, kì í yí pa dà, òun sì ni ibi ààbò fún gbogbo àwọn tó ń rí ìpọ́njú, táwọn èèyàn ń ni lára, tí wọ́n sì ń wojú Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún Sámúẹ́lì pé ó ní ìyá tó ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ mọ́ nígbà tó ń dàgbà, ó mọ̀ pé kò jẹ́ gbàgbé òun láé. Lọ́dọọdún ni Hánà máa ń wá sí Ṣílò, tí á mú aṣọ àwọ̀lékè kékeré tí kò lápá táá máa fi ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìjọsìn wá fún un. Bó ṣe jẹ́ Hánà fúnra rẹ̀ ló ń hun aṣọ náà fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ náà gan-an, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 2:19) A lè fojú inú wo bó ṣe ń wọ aṣọ náà fún ọmọdékùnrin náà, tó ń fọwọ́ na aṣọ náà tó sì ń wò ó tìdùnnú-tìdùnnú bó ṣe ń bá ọmọ náà sọ̀rọ̀ ìṣírí lọ́nà tó tuni lára. Ìbùkún ló jẹ́ fún Sámúẹ́lì pé ó ní irú ìyá rere bẹ́ẹ̀ àti pé òun fúnra rẹ̀ jẹ́ ìbùkún fún àwọn òbí rẹ̀ àti fún gbogbo Ísírẹ́lì bó ṣe ń dàgbà.

Ọlọ́run kò gbàgbé Hánà náà. Jèhófà bù kún rẹ̀, ó sì bí ọmọ márùn-ún míì fún Ẹlikénà. (1 Sámúẹ́lì 2:21) Ìbùkún tó tóbi jù lọ tí Hánà ní ni bí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ Jèhófà ṣe ń lágbára sí i bí ọdún ṣe ń gorí ọdún. Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ tìrẹ náà rí bíi ti Hánà, bó o ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìkóbìnrinjọ láwọn ìgbà kan láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, ka àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ìkóbìnrinjọ?” lójú ìwé 30 nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2009.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ náà sọ pé Jèhófà ti ‘sé ilé ọlẹ̀ Hánà,’ kò sí ẹ̀rí pé inú Ọlọ́run kò dùn sí obìnrin onírẹ̀lẹ̀ àti olóòótọ́ yìí. (1 Sámúẹ́lì 1:5) Nígbà míì, Bíbélì máa ń sọ pé Ọlọ́run ló ṣe àwọn nǹkan kan nítorí pé ó gbà wọ́n láyè pé kí wọ́n ṣẹlẹ̀ fún àwọn àkókò kan.

c Bí ìrìn àjò náà ṣe jìn tó yìí lè jẹ́ nítorí pé Rámà ìlú ìbílẹ̀ Ẹlikénà ni ibi tá a wá mọ̀ sí Arimatíà ní ọjọ́ Jésù.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Àdúrà Méjì Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀

Àdúrà méjì tí Hánà gbà wà nínú ìwé 1 Sámúẹ́lì 1:11 àti 2:1-10, àwọn àdúrà náà sì ní àwọn ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Gbé díẹ̀ lara wọn yẹ̀ wò:

◼ Hánà gba àdúrà àkọ́kọ́ sí “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé ó lo orúkọ oyè yẹn fún Ọlọ́run. Orúkọ náà fara hàn nígbà ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [285] nínú Bíbélì, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní àṣẹ lórí gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó ńbẹ lọ́run.

◼ Kíyè sí i pé kì í ṣe ìgbà tí Hánà bímọ ló gba àdúrà kejì, ìgbà tí òun àti Ẹlikénà mú ọmọ náà lọ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní Ṣílò ló gbà á. Nítorí náà ayọ̀ ńlá tí Hánà ní jẹ́ nítorí pé Jèhófà bù kún rẹ̀, kì í ṣe nítorí pé ó pa orogún rẹ̀ lẹ́nu mọ́.

◼ Nígbà tí Hánà sọ pé, “Ìwo mi ni a gbé ga ní tòótọ́ nínú Jèhófà,” ó lè jẹ́ akọ màlúù tó ń túlẹ̀ ló ní lọ́kàn, ìyẹn ẹranko alágbára tó máa ń ru àjàgà tó sì máa ń lo ìwo rẹ̀ lọ́nà tó kàmàmà. Ohun tí Hánà ń sọ ni pé: ‘Jèhófà, ìwọ sọ mí di alágbára.’—1 Sámúẹ́lì 2:1.

◼ Ọ̀rọ̀ tí Hánà sọ nípa “ẹni àmì òróró” Ọlọ́run jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ni wọ́n pè ní “mèsáyà,” Hánà sì ni ẹni àkọ́kọ́ nínú Bíbélì tó máa lò ó láti fi tọ́ka sí ọba ọjọ́ iwájú tó jẹ́ ẹni àmì òróró.—1 Sámúẹ́lì 2:10.

◼ Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Màríà ìyá Jésù lo díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ Hánà láti fi yin Jèhófà.—Lúùkù 1:46-55.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìdààmú ọkàn bá Hánà gidigidi nítorí pé ó yàgàn, Pẹ̀nínà sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú kí inú Hánà máa bà jẹ́ sí i

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ǹjẹ́ o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà tó gbàdúrà látọkànwá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Élì ṣi Hánà lóye, síbẹ̀ kò bínú