Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Dájú Pé Ìwà Ibi Máa Dópin!

Ó Dájú Pé Ìwà Ibi Máa Dópin!

Ó Dájú Pé Ìwà Ibi Máa Dópin!

ỌLỌ́RUN ti fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí, èyí tó jẹ́ ká mọ àwọn ìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà ibi. Ó tún fún wa ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá àti agbára láti kóra wa ní ìjánu, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti yẹra fún ohun tó burú. (Diutarónómì 30:15, 16, 19) Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ní yìí, a lè mọ èrò burúkú tó wà lọ́kàn wa, ká sì ṣe àtúnṣe tó tọ́ nípa rẹ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, yíyẹra fún ìwà ibi máa jẹ́ kí àwa àtàwọn tó wà láyìíká wa láyọ̀.—Sáàmù 1:1.

Síbẹ̀, kò sí bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè gbìyànjú tó láti yẹra fún ìwà ibi, ńṣe ni ìwà ibi táwọn èèyàn ń hù nínú ayé túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” Ó sọ àwọn nǹkan tó mú kí àwọn àkókò náà “nira láti bá lò,” ó ní: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀; yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.”—2 Tímótì 3:1-5.

Ó ṣeé ṣe kó o kíyè sí bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó wà lókè yìí. Báwo lo ṣe lóye ọ̀rọ̀ yìí sí? Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn lóye ọ̀rọ̀ náà, “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” sí ni pé, nǹkan kan máa tó dópin. Kí ni nǹkan náà? Gbọ́ ìlérí Ọlọ́run nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Àwọn èèyàn búburú máa pa run pátápátá.

“Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”SÁÀMÙ 37:10, 11.

“Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni burúkú ni òun yóò pa rẹ́ ráúráú.”SÁÀMÙ 145:20.

Kò ní sí ìnilára mọ́.

“Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”​—SÁÀMÙ 72:12, 14.

“A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”RÓÒMÙ 8:21.

Ọwọ́ àwọn èèyàn máa tẹ gbogbo nǹkan tí wọ́n nílò.

“Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”​—MÍKÀ 4:4.

“Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”​—AÍSÁYÀ 65:21, 22.

Ìdájọ́ òdodo máa lékè.

“Dájúdájú, nígbà náà, Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán-tòru . . . ? Mo sọ fún yín, Yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹ̀lú ìyára kánkán.”LÚÙKÙ 18:7, 8.

“Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú.”​—SÁÀMÙ 37:28.

Òdodo máa rọ́pò ìmọtara ẹni nìkan.

“Òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.”AÍSÁYÀ 26:9.

“Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”​—2 PÉTÉRÙ 3:13.

Àwọn Èèyàn Ń Yí Pa Dà Lákòókò Yìí Pàápàá

Kò sí àní-àní pé, gbogbo wa ni inú wa máa dùn sí àwọn ìlérí wọ̀nyí. Àmọ́ kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé wọ́n máa ṣẹ? Ní báyìí, a ní ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ. Kí ni ẹ̀rí náà? Ohun ni pé, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé ló ń gbádùn ara wọn nítorí pé wọ́n ti jáwọ́ nínú ìmọtara-ẹni-nìkan, ìṣekúṣe tàbí ìwà ipá, wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ olóòótọ́, ẹni àlàáfíà àti onínúure. Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù méje kárí ayé tó wà ní ìṣọ̀kan ti borí ọ̀pọ̀ ìkórìíra, ìwà ipá àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ èyí tí ẹ̀yà tèmi lọ̀gá, ìṣèlú àti ìṣúnná owó ti ṣokùnfà. a Àwọn ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní yìí jẹ́ ká gbà gbọ́ pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ lọ́nà tó pabanbarì.

Àmọ́ kí ló jẹ́ káwọn ìyípadà náà ṣeé ṣe? Ìdáhùn yẹn wà nínú àwọn ìlérí míì tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀, èyí tí wòlíì Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀. Ó ní:

“Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n. . . . Kìnnìún pàápàá yóò jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. Dájúdájú, ọmọ ẹnu ọmú yóò máa ṣeré lórí ihò ṣèbé; ihò tí ó ní ìmọ́lẹ̀, tí í ṣe ti ejò olóró ni ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú yóò sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí ní ti gidi. Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:6-9.

Ṣé àkókò tí àwọn ẹranko á máa gbé lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn ni ìlérí yìí ń sọ ni? Rárá, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kíyè sí i pé apá tó gbẹ̀yìn ẹsẹ yẹn jẹ́ ká mọ ohun tó fa ìyípadà yẹn, ó ní: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” Ṣé ìmọ̀ Ọlọ́run lè yí ìwà ẹranko pa dà? Rárá o, kò lè rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó lè yí èèyàn pa dà, ó sì ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀! Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ pé, àwọn tó ti ní ìwà bí ẹranko máa pa ìwà náà tì, wọ́n á sì wá máa hùwà bíi ti Kristi nítorí pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú rẹ̀ sílò.

Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Pedro. b Èrò rẹ̀ ni pé, òun ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nígbà tó dara pọ̀ mọ́ àwùjọ apániláyà kan. Lẹ́yìn tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, wọ́n yan iṣẹ́ fún un pé kó lọ ju bọ́ǹbù lu àgọ́ ọlọ́pàá kan. Ìgbà tó ń múra sílẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí ni wọ́n fi òfin mú un. Ọdún kan ààbọ̀ ni Pedro lò lẹ́wọ̀n, síbẹ̀, ó ń bá ìdìtẹ̀ náà nìṣó. Àmọ́ lákòókò yìí, ìyàwó Pedro ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí Pedro jáde lẹ́wọ̀n, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tó kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run mú kó ṣe ìyípadà tó pọ̀ nínú ìwà rẹ̀, èrò rẹ̀ nípa ìgbésí ayé sì yí pa dà gan-an. Pedro sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mi ò pa ẹnikẹ́ni láwọn ọdún tí mo fi jẹ́ apániláyà. Ní báyìí, idà ẹ̀mí, ìyẹn Bíbélì ni mò ń lò láti fi kéde ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run tó máa mú àlàáfíà tòótọ́ wá, tó sì máa ṣẹ̀tọ́ fún gbogbo èèyàn.” Pedro tiẹ̀ tún lọ kéde ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti ọ̀rọ̀ nípa ayé kan tí kò ti ní sí ìwà ipá ní àgọ́ ọlọ́pàá tó fẹ́ ju bọ́ǹbù lù tẹ́lẹ̀.

Agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní láti yí èèyàn pa dà túbọ̀ jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run pé, ó dájú pé gbogbo ìwà ibi máa dópin. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn èèyàn kò ní máa bá ìwà ibi nìṣó títí láé, wọ́n máa yí pa dà kí wọ́n lè máa ṣe ohun tó tọ́. Láìpẹ́, Jèhófà máa mú Sátánì Èṣù tó dá ìwà ibi sílẹ̀ tó sì ń darí ayé kúrò. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Àmọ́, ẹni burúkú náà kò ní sí mọ́ láìpẹ́. Bákan náà, àwọn tí kò jáwọ́ nínú ìwà ibi kò ní sí mọ́. Á mà dára gan-an láti gbé nírú àkókò yẹn o!

Kí ló yẹ kí ẹnì kan tó bá fẹ́ gbé ní àkókò yẹn ṣe? Rántí pé “ìmọ̀ Jèhófà” ló ń mú kí àwọn èèyàn yí ìgbésí ayé wọn pa dà lónìí, ìmọ̀ yìí náà ló máa mú ìyípadà kárí ayé wá lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá gba ìmọ̀ pípéye tó wà nínú Bíbélì, tó o sì ń fi í sílò, bíi Pedro, ìwọ náà á láǹfààní láti gbé nínú ayé kan tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) A rọ̀ ẹ́ pé kó o lo àkókò tó o ní nísinsìnyí láti kẹ́kọ̀ọ́, kó o lè ní ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi, torí pé ìyẹn lè jẹ́ kó o wà láàyè títí láé.—Jòhánù 17:3.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé síwájú sí i, ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

b A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Ìwọ náà lè láǹfààní láti gbé nínú ayé kan tí “òdodo yóò . . . máa gbé.”​—2 PÉTÉRÙ 3:13