Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àṣírí Kan Tó O Lè Sọ fún Ẹlòmíì

Àṣírí Kan Tó O Lè Sọ fún Ẹlòmíì

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Àṣírí Kan Tó O Lè Sọ fún Ẹlòmíì

ǸJẸ́ wọ́n ti sọ àṣírí kan fún ẹ rí?— a Ọ̀kan wà tí mo fẹ́ láti sọ fún ẹ. Bíbélì pè é ní “àṣírí ọlọ́wọ̀ tí a ti pa mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tipẹ́tipẹ́.” (Róòmù 16:25) Ọlọ́run nìkan ló kọ́kọ́ mọ “àṣírí ọlọ́wọ̀” náà. Jẹ́ ká wo bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ àṣírí náà.

Lákọ̀ọ́kọ́ náà, ǹjẹ́ o mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà, “ọlọ́wọ̀” túmọ̀ sí?— Ó túmọ̀ sí mímọ́ tàbí ohun pàtàkì. Ìdí nìyẹn tá a fi pe àṣírí náà ní àṣírí ọlọ́wọ̀, nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí ó jẹ́ mímọ́ ló ti wá. Àwọn wo lo rò pé wọ́n fẹ́ láti mọ àṣírí pàtàkì yìí?— Àwọn áńgẹ́lì ni. Bíbélì sọ pé: “Nǹkan wọ̀nyí gan-an ni àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wò ní àwòfín.” Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n fẹ́ lóye àṣírí mímọ́ yìí.—1 Pétérù 1:12.

Nígbà tí Jésù wá sí ayé, ó sọ̀rọ̀ nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni a ti fún ní àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba Ọlọ́run.” (Máàkù 4:11) Ǹjẹ́ o kíyè sí ohun tí àṣírí ọlọ́wọ̀ náà jẹ́?— Ó jẹ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún!—Mátíù 6:9, 10.

Nísinsìnyí, jẹ́ ká wo bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe jẹ́ àṣírí tó ti wà “tipẹ́tipẹ́” títí fi di ìgbà tí Jésù wá sí ayé tó sì wá ń ṣàlàyé rẹ̀. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà rú òfin Ọlọ́run, tí Ọlọ́run sì lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé Ọlọ́run ṣì máa sọ ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:8, 9; Aísáyà 45:18) Wọ́n kọ̀wé nípa ayọ̀ tí àwọn èèyàn máa ní lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Sáàmù 37:11, 29; Aísáyà 11:6-9; 25:8; 33:24; 65:21-24.

Ní báyìí, wá ronú nípa Ẹni tó máa jẹ́ Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ Alákòóso náà?— Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi tó jẹ́ “Aládé Àlàáfíà” ni. Bíbélì sọ pé: “Ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.” (Aísáyà 9:6, 7) Èmi àti ìwọ gbọ́dọ̀ ní “ìmọ̀ pípéye nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run lọ́kàn, èyíinì ni, Kristi.” (Kólósè 2:2) Ó yẹ ká mọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe mú ẹ̀mí áńgẹ́lì àkọ́kọ́ (ìyẹn Ọmọ rẹ̀) tí ó dá, tí ó sì fi í sínú Màríà. Ọmọ tó jẹ́ áńgẹ́lì alágbára yìí ni Ọlọ́run rán wá sáyé láti fi rúbọ, kí a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; 17:3.

Àmọ́, ó tún ku àwọn nǹkan míì tó yẹ ká mọ̀ nípa àṣírí yìí ju pé Ọlọ́run ti yan Jésù láti jẹ́ Alákòóso Ìjọba Rẹ̀. Ara àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí ni pé, àwọn ọkùnrin àti obìnrin kan máa wà pẹ̀lú Jésù to ti jíǹde ní ọ̀run. Wọn yóò sì bá Jésù ṣàkóso ní ọ̀run!—Éfésù 1:8-12.

Ní báyìí, jẹ́ ká wá mọ orúkọ àwọn kan lára àwọn tó máa bá Jésù ṣàkóso ní ọ̀run. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé òun ń lọ sọ́run láti lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún wọn. (Jòhánù 14:2, 3) Tó o bá wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ le yìí, wàá rí díẹ̀ lára orúkọ àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó máa bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba Bàbá rẹ̀.—Mátíù 10:2-4; Máàkù 15:39-41; Jòhánù 19:25.

Ó ti pẹ́ gan-an tí a kò ti mọ iye èèyàn tó máa bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀ lọ́run. Àmọ́ nísinsìnyí, a ti mọ iye wọn. Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?— Bíbélì sọ pé, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni. Èyí náà jẹ́ ara àṣírí ọlọ́wọ̀ náà.—Ìṣípayá 14:1, 4.

Ǹjẹ́ o gbà pé “àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ìjọba Ọlọ́run” yìí jẹ́ àṣírí tó jẹ́ àgbàyanu tó ju gbogbo àṣírí míì lọ?— Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ ká sapá láti mọ gbogbo ohun tí a bá lè mọ̀ nípa àṣírí náà, ká bàa lè ṣàlàyé nǹkan wọ̀nyí fún àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an débi tágbára wa bá gbé e dé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.

ÌBÉÈRÈ:

▪ Kí là ń pe àṣírí tí à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí, kí sì nìdí tá a fi pè é bẹ́ẹ̀?

▪ Kí ni àṣírí yìí, ta sì ni ẹni àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í fi kọ́ àwọn èèyàn?

▪ Kí làwọn ohun tó o ti mọ̀ nípa àṣírí yìí?

▪ Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àṣírí ọlọ́wọ̀ náà fún ọ̀rẹ́ rẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kí ni o rò pé àwọn áńgẹ́lì ń gbìyànjú láti mọ̀?