Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Jẹ́ Ilé Ẹ̀dá Èèyàn Ní Ìbẹ̀rẹ̀?

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Jẹ́ Ilé Ẹ̀dá Èèyàn Ní Ìbẹ̀rẹ̀?

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Jẹ́ Ilé Ẹ̀dá Èèyàn Ní Ìbẹ̀rẹ̀?

FOJÚ inú wò ó pé o wà nínú ọgbà kan. Kò sí ìpínyà ọkàn, kò sí ariwo gèè tó ń wá látinú ìlú. Ọgbà náà tóbi gan-an, kò sì sí wàhálà kankan níbẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí ohun tó ń da ọkàn rẹ láàmú, àìsàn kankan kò ṣe ọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni o kò ní ìrora kankan. Gbogbo nǹkan tó wà láyìíká rẹ lò ń gbádùn.

Bó o ṣe tajú kán, o rí òdòdó tó lẹ́wà tó ń tàn, lẹ́yìn náà, o rí omi tó ń ṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, o tún rí ewéko tó tutù yọ̀yọ̀ tó lọ salalu tí oòrùn ń ràn sí. Ò ń gbádùn afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ lóló àti òórùn dídùn tó gba afẹ́fẹ́ kan. Ò ń gbọ́ ìró ewé tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ìró omi tó ń rọ́ lu àpáta, o sì ń gbọ́ ìró àti orin àwọn ẹyẹ àti ìró àwọn kòkòrò tó ń kùn bí wọ́n ṣe ń gbé nǹkan ṣe. Bó o ti ń fojú inú wo àwọn nǹkan yìí, ǹjẹ́ kò wù ẹ́ láti wà nínú irú ọgbà yìí?

Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló gbà pé irú àyíká yìí ni ẹ̀dá èèyàn gbé ní ìbẹ̀rẹ̀. Ó ti pẹ́ gan-an tí àwọn ẹlẹ́sìn Júù, àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn Mùsùlùmí ti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn nípa ọgbà Édẹ́nì, ibi tí Ọlọ́run fi Ádámù àti Éfà sí láti máa gbé. Bíbélì sọ pé, ìgbésí ayé aláyọ̀ àti alálàáfíà ni wọ́n gbé níbẹ̀. Àlááfíà wà láàárín Ádámù àti Éfà, ó wà láàárín àwọn àti ẹranko, bẹ́ẹ̀ ni kò sí wàhálà láàárín àwọn àti Ọlọ́run, ẹni tó fìfẹ́ fún wọn láǹfààní láti máa gbé lọ títí láé ní ibi tó fani mọ́ra yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-24.

Láyé ìgbàanì, àwọn onísìn Híńdù náà ní èrò tó yàtọ̀ nípa Párádísè. Ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Búdà náà ni pé, ìgbà sànmánì aásìkí tí ayé rí bíi Párádísè ni àwọn Búdà, ìyẹn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí ti wà. Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn nílẹ̀ Áfíríkà ló sì máa ń sọ ìtàn tó jọ ìtàn nípa Ádámù àti Éfà.

Ìgbàgbọ́ pé Párádísè kan wà ní ìgbàanì wọ́pọ̀ gan-an nínú ìjọsìn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn èèyàn. Òǹṣèwé kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé láyé òde òní gbà pé Párádísè kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, pé nígbà yẹn, òmìnira, àlàáfíà àti ayọ̀ wà, kò sí àìríná-àìrílò, pákáǹleke àti ìjà. . . . Ìgbàgbọ́ yìí mú káwọn èèyàn níbi gbogbo nífẹ̀ẹ́ Párádísè tí aráyé pàdánù náà, wọ́n sì ń fẹ́ láti jèrè rẹ̀ pa dà.”

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibì kan náà ni àwọn ìtàn àtàwọn ìgbàgbọ́ yìí ti wá? Ǹjẹ́ ó lè jẹ́ pé fífẹ́ táwọn èèyàn ń fẹ́ Párádísè náà ló mú kí wọ́n gbà pé ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí? Ṣé òótọ́ ni pé ọgbà Édẹ́nì wà ní ìgbàanì? Ṣé àwọn kan wà tí wọ́n ń jẹ́ Ádámù àti Éfà lóòótọ́?

Àwọn tó ń ṣiyè méjì ń bẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ nípa ọgbà Édẹ́nì. Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn láyé òde òní tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti gbilẹ̀ ni pé, ìtàn àròsọ lásán ni ọ̀ràn náà, kì í ṣe òtítọ́. Ohun tó jọni lójú ni pé, àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ìsìn nìkan kọ́ ló ń ṣiyè méjì nípa ọ̀ràn yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ni wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ wọn ṣàkóbá fún àwọn èèyàn, ìyẹn sì ń mú káwọn èèyàn má ṣe gbà pé ọgbà Édẹ́nì wà. Wọ́n ń kọ́ni pé, kò sí ibì kankan tó ń jẹ́ ọgbà Édẹ́nì. Wọ́n sọ pé, àfiwé, ìtàn àròsọ, àlọ́ àti àkàwé lásán ni.

Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ àkàwé wà nínú Bíbélì. Jésù pàápàá ló sọ èyí tí àwọn èèyàn mọ̀ jù lọ lára àwọn àkàwé náà. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ nípa ọgbà Édẹ́nì jẹ́ ìtàn tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, kì í ṣe àkàwé. Bí ìtàn nípa ọgbà Édẹ́nì kò bá ṣẹlẹ̀, báwo la wá ṣe máa gba àwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ gbọ́? Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìdí táwọn kan fi ń ṣiyè méjì nípa ọgbà Édẹ́nì, ká sì wò ó bóyá ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Lẹ́yìn náà, a ó wá sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kí ìtàn náà ṣe pàtàkì sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.