Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Mọ̀ Pé Ádámù Àti Éfà Máa Dẹ́ṣẹ̀?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Mọ̀ Pé Ádámù Àti Éfà Máa Dẹ́ṣẹ̀?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Mọ̀ Pé Ádámù Àti Éfà Máa Dẹ́ṣẹ̀?

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló ń béèrè ìbéèrè yìí nítorí wọ́n fẹ́ mọ òtítọ́. Nígbà táwọn èèyàn bá béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, tí wọ́n bá sọ ọ́ lọ, sọ ọ́ bọ̀, orí ẹ̀ṣẹ̀ tí tọkọtaya àkọ́kọ́ dá nínú ọgbà Édẹ́nì ni ọ̀rọ̀ náà máa ń dá lé. Èrò pé ‘Ọlọ́run mọ ohun gbogbo’ lè tètè mú káwọn kan rò pé Ọlọ́run ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Ádámù àti Éfà máa ṣàìgbọràn sí òun.

Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Ọlọ́run ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé yìí máa dẹ́ṣẹ̀, kí nìyẹn máa túmọ̀ sí? Ìyẹn máa fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni burúkú. Ó máa fi hàn pé ó jẹ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́, ẹni tí kì í ṣe ìdájọ́ òdodo, tó sì jẹ́ aláìṣòótọ́. Àwọn èèyàn kan lè kà á sí ìwà ìkà pé Ọlọ́run fi tọkọtaya àkọ́kọ́ náà sínú ipò tó mọ̀ pé àgbákò ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀. Ìyẹn sì máa jẹ́ kó dà bíi pé Ọlọ́run ló jẹ̀bi gbogbo ìwà ibi àti ìjìyà tó dé ba ẹ̀dá èèyàn, tàbí kó nípìn-ín nínú ẹ̀bi náà. Lójú àwọn kan, á jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa kò gbọ́n.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú Ìwé Mímọ́, ǹjẹ́ Jèhófà Ọlọ́run bá irú àpèjúwe burúkú yẹn mu? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá àti irú ẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́.

“Ó Dára Gan-an Ni”

Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé, títí kan tọkọtaya àkọ́kọ́, pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ó dá Ádámù àti Éfà ní pípé, lọ́nà tí wọ́n á fi gbádùn àyíká ilẹ̀ ayé. Kò sí àbùkù kankan lára wọn. Ó dájú pé wọ́n lè ṣe ohun tó dáa tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe nítorí pé ó dá wọn lọ́nà tó “dára gan-an.” Ọlọ́run dá wọn ní “àwòrán” ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Nítorí náà, dé ìwọ̀n àyè kan, wọ́n lágbára láti fi ànímọ́ Ọlọ́run hàn, irú bí ọgbọ́n, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ìdájọ́ òdodo àti ìwà rere. Bí wọ́n bá ń fi àwọn ànímọ́ yìí ṣèwàhù, wọ́n á lè ṣe ìpinnu tó máa ṣe wọ́n láǹfààní tí á sì mú ayọ̀ bá Bàbá wọn ọ̀run.

Jèhófà fún àwọn èèyàn pípé tí wọ́n jẹ́ olóye yìí ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Nítorí náà, Ọlọ́run kò dá wọn bí ẹ̀rọ, kí wọ́n lè máa ṣe ohun tó fẹ́. Rò ó wò ná. Èwo ló máa múnú rẹ̀ dùn nínú ẹ̀bùn tí ó ti ọkàn ẹni tó fún ẹ wá àti èyí tí kò ti ọkàn rẹ̀ wá? Ó dájú pé ẹ̀bùn àtọkànwá lo máa fẹ́. Bákàn náà, tí Ádámù àti Éfà bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run látọkànwá, ìyẹn ì bá múnú Ọlọ́run dùn gan-an. Nítorí tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí lágbára láti yan ohun tó wù wọ́n, wọ́n láǹfààní láti fi ìfẹ́ ṣègbọràn sí Jèhófà látọkànwá.—Diutarónómì 30:19, 20.

Olódodo, Onídàájọ́ Òdodo àti Olóore

Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Àwọn ànímọ́ yìí kò lè mú kí ó dẹ́ṣẹ̀ láéláé. Sáàmù 33:5 sọ pé, Jèhófà jẹ́ “olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.” Nípa báyìí, Jákọ́bù 1:13 sọ pé: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” Nítorí Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo àti agbatẹnirò, ó kìlọ̀ fún Ádámù pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ọlọ́run fún tọkọtaya àkọ́kọ́ ní àǹfààní láti yan ìyè àìnípẹ̀kun tàbí ikú. Ṣé kò ní jẹ́ pé Ọlọ́run hùwà àgàbàgebè tó bá kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n kò ní ṣàì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà? Nítorí pé Jèhófà jẹ́ “olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo,” ó dájú pé kò ní sọ pé òun máa fún wọn ní ohun kan tó mọ̀ pé kò sí.

Jèhófà tún jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń ṣoore gan-an. (Sáàmù 31:19) Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé oore Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ rẹ̀ béèrè búrẹ́dì—òun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Tàbí, bóyá, òun yóò béèrè ẹja—òun kì yóò fi ejò lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Nítorí náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Mátíù 7:9-11) Ọlọ́run ń fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní “ohun rere.” Ọ̀nà tó gbà dá èèyàn àti bó ṣe ṣe Párádísè ilé wọn fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ olóore. Ǹjẹ́ Ọba Aláṣẹ tó jẹ́ ẹni rere yìí á burú débi táá fi pèsè ilé ẹlẹ́wà fún ẹ̀dá èèyàn tó sì mọ̀ pé tó bá yá òun ṣì máa gbà á lọ́wọ́ wọn? Rárá. Kò sídìí láti dá Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ olódodo àti ẹni rere lẹ́bi nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀dá èèyàn hù.

“Ẹnì Kan Ṣoṣo Tí Ó Gbọ́n”

Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.” (Róòmù 16:27) Àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run fojú ara wọn rí ọ̀pọ̀ ọgbọ́n yìí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “hó yèè nínú ìyìn” nígbà tí Jèhófà dá àwọn nǹkan sí orí ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 38:4-7) Kò sí àní-àní pé, àwọn áńgẹ́lì olóye yìí ń fìdùnnú wo bí Ọlọ́run ṣe ń ṣẹ̀dá àwọn nǹkan sínú ọgbà Édẹ́nì. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu fún Ọlọ́run tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n pé lẹ́yìn tó tí dá àwọn nǹkan àgbàyanu sí ayé àti sí ọ̀run ní ìṣojú àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ rẹ̀, kó tún wá dá àwọn ẹ̀dá èèyàn méjì tó mọ̀ pé wọn kò ní ṣàṣeyọrí? Ó dájú pé kò ní ṣe irú ohun tí kò bọ́gbọ́n mu yẹn láéláé.

Síbẹ̀, àwọn kan lè sọ pé, ‘Àmọ́ báwo ni Ọlọ́run tó gbọ́n jù lọ kò ṣe ní mọ̀ pé wọ́n máa dẹ́ṣẹ̀?’ Òótọ́ ni pé, ọgbọ́n Jèhófà pọ̀ débi pé, ó lágbára láti “ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin.” (Aísáyà 46:9, 10) Àmọ́, kò sí ìdí kan tó fi yẹ kó lo gbogbo ọgbọ́n yìí, bí kò ṣe sí ìdí pé kó lo gbogbo agbára tó ní. Jèhófà máa ń lo agbára tó ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ìgbà tó bọ́gbọ́n mu àti àkókò tó yẹ ló máa ń lo agbára yìí.

A lè fi bí Ọlọ́run kì í ṣeé lo agbára tó ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú wé ohun tí ẹnì kan lè ṣe tó bá fẹ́ wo eré bọ́ọ̀lù kan tí wọ́n ti gbà sórí àwo DVD. Tó bá wu ẹni náà, ó lè kọ́kọ́ wo apá tó kẹ́yìn nínú eré bọ́ọ̀lù náà láti mọ ibi tó yọrí sí. Àmọ́, kò pọn dandan kó ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ṣó burú tí ẹni náà bá sọ pé láti ìbẹ̀rẹ̀ lóun tí máa wo eré náà? Bákan náà, Ẹlẹ́dàá náà yàn láti má ṣe wo ìgbẹ̀yìn ọ̀ràn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yàn pé òun á dúró láti máa wo bí ọ̀ràn náà á ṣe máa lọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé títí á fi dé òpin, láti wo bí àwọn ọmọ òun tó wà lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣe hùwà.

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, Jèhófà fi ọgbọ́n dá èèyàn, kò dá wọn bí ẹ̀rọ tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n fẹ́ kó ṣe ló máa ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fìfẹ́ fún wọn ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Tí wọ́n bá yàn láti ṣe ohun tó tọ́, wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ fi ìfẹ́, ìmọrírì àti ìgbọràn wọn hàn sí Jèhófà, àwọn fúnra wọn á láyọ̀, wọ́n á sì mú ọkàn Bàbá wọn ọ̀run yọ̀.—Òwe 27:11; Aísáyà 48:18.

Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé, lọ́pọ̀ ìgbà, Ọlọ́run kò lo agbára tó ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ábúráhámù olóòótọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, Jèhófà sọ pé: “Nísinsìnyí ni mo mọ̀ pé olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìwọ ní ti pé ìwọ kò fawọ́ ọmọkùnrin rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, sẹ́yìn fún mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:12) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn àkókò kan wà tí ohun búburú tí àwọn kan ṣe ‘dun’ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ á dun Ọlọ́run tó yẹn ká ní ó ti mọ̀ tipẹ́ pé ohun tí wọ́n máa ṣe nìyẹn?—Sáàmù 78:40, 41; 1 Àwọn Ọba 11:9, 10.

Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé, Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n gbogbo kò lo agbára tó ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, láti fi mọ̀ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ máa dẹ́ṣẹ̀. Ó dájú pé Ọlọ́run tó ní agbára láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kò ní hùwà òmùgọ̀, ìyẹn ni pé kó dáwọ́ lé ohun tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé kò ní yọrí sí rere.

“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

Sátánì tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run ló dá ìṣọ̀tẹ̀ sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, èyí sì ti ní àbájáde búburú títí kan ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nítorí náà, “apànìyàn” ni Sátánì. Ó tún jẹ́ “òpùrọ́” àti “baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Nítorí pé èrò búburú tó ní ló ń darí rẹ̀, ó gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn máa wo Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ bí ẹni burúkú. Ó ń fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé Jèhófà ló mú káwọn èèyàn máa dẹ́ṣẹ̀.

Ìfẹ́ tí Jèhófà ní ló jẹ́ ìdí tó lágbára tó fi yàn láti má ṣe mọ̀ ṣáájú pé Ádámù àti Éfà máa dẹ́ṣẹ̀. Ìfẹ́ ló tóbi jù lọ nínú ànímọ́ Ọlọ́run. Ìwé 1 Jòhánù 4:8 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ohun tó dára ni ìfẹ́ máa ń ṣe, kì í ṣe ohun tó burú. Ohun tó dára ló máa ń wò nínú àwọn èèyàn. Ó dájú pé nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ní, ó fẹ́ ohun tó dára jù lọ fún àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ọmọ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé lè yàn láti ṣe ohun tí kò tọ́, kò sí ìdí fún Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ láti máa rò pé àwọn ẹ̀dá rẹ̀ tó jẹ́ ẹni pípé kò ní ṣàṣeyọrí tàbí kò máa ṣiyè méjì nípa wọn. Ó ti fún wọn ní gbogbo nǹkan tí wọ́n nílò nígbèésí ayé, ó sì ti sọ ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ fún wọn. Ohun tó bọ́gbọ́n mu tí Ọlọ́run yóò máa rétí lọ́dọ̀ wọn ni pé kí wọ́n máa fìfẹ́ ṣègbọràn, kì í ṣe kí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀. Ọlọ́run mọ̀ pé, Ádámù àti Éfà ní agbára láti jẹ́ olóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù, Jóòbù, Dáníẹ́lì àti ọ̀pọ̀ èèyàn aláìpé míì ṣe jẹ́ olóòótọ́ nígbà tó yá.

Jésù sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” (Mátíù 19:26) Ọ̀rọ̀ yìí mà tuni nínú o! Ìfẹ́ tí Jèhófà ní àtàwọn ànímọ̀ rẹ̀ pàtàkì yòókù bí, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti agbára mú kó dáni lójú pé, láìpẹ́, ó máa mú gbogbo ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú dá sílẹ̀ kúrò.—Ìṣípayá 21:3-5.

Ó hàn kedere pé, Jèhófà kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé tọkọtaya àkọ́kọ́ náà máa dẹ́ṣẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ẹ̀ṣẹ̀ tí èèyàn dá àti ìjìyà tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ dun Ọlọ́run, síbẹ̀, ó mọ̀ pé ipò tí ayé wà nísinsìnyí kò ní dí òun lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ òun fún ayé àti aráyé ṣẹ. O ò ṣe wádìí sí i nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe yìí àti bó o ṣe lè jàǹfààní nínú ìmúṣẹ ológo náà. *

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé, ka orí 3 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Jèhófà kò dá àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ bí ẹ̀rọ tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n fẹ́ kó ṣe ló máa ń ṣe.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

Ọlọ́run mọ̀ pé, Ádámù àti Éfà ní agbára láti jẹ́ olóòótọ́