Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Nítorí pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn máa ń gùn gan-an lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ọgbọ́n wo ni wọ́n ń dá nígbà àtijọ́ tí wọ́n fi ń rí omi tó pọ̀ tó lò?

Òjò máa ń rọ̀ láti oṣù October sí April ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, nígbà míì, ọ̀gbàrá òjò sì máa ń ṣàn lọ sí àwọn àfonífojì. Àmọ́ tó bá di ìgbà ẹ̀rùn, ọ̀pọ̀ lára àwọn “adágún” yìí máa ń gbẹ, òjò sì lè má rọ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Báwo ni àwọn èèyàn ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì ṣe máa ń rí omi lò déédéé?

Bí wọ́n ṣe yanjú ìṣòro yìí ni pé, wọ́n máa ń gbẹ́ kòtò sí ẹ̀gbẹ́ àwọn òkè kéékèèké láti darí omi òjò ìgbà òtútù lọ sínú ìkùdu, ìyẹn kòtò abẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n ń tọ́jú omi sí. Wọ́n ṣe òrùlé ilé wọn lọ́nà tó dà gẹ̀rẹ́ kí omi òjò lè lọ sínú àwọn kòtò abẹ́ ilẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ ìdílé ló ṣe kòtò abẹ́ ilẹ̀ tiwọn, ibẹ̀ ni wọ́n tí ń fa omi tí wọ́n ń mu.—2 Àwọn Ọba 18:31; Jeremáyà 6:7.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún máa ń lo omi tó ń sun láti abẹ́ ilẹ̀. Lórí àwọn òkè, òjò ìgbà òtútù máa ń wọnú ilẹ̀ lọ títí tó máa fi dé ibi àpáta abẹ́ ilẹ̀ tí kò ní lè lọ mọ́, á wá máa ṣàn níbẹ̀ títí á tún fi sun jáde pa dà. Àwọn ìlú bí Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì, Ẹ́ń-rógélì àti Ẹ́ń-gédì fi hàn pé wọ́n sábà máa ń tẹ àwọn abúlé dó sí ẹ̀gbẹ́ ìsun omi (ìyẹn en lédè Hébérù). (Jóṣúà 15:7, 62) Ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n gbẹ́ ọ̀nà omi abẹ́ ilẹ̀ gba inú àpáta láti mú omi wọ ìlú náà.—2 Àwọn Ọba 20:20.

Ní ibi tí kò bá ti sí ìsun omi, kànga (ìyẹn beʼerʹ lédè Hébérù), ni wọ́n máa ń gbẹ́ bí irú èyí tó wà ní Bíá-ṣébà kí wọ́n lè fa omi jáde lábẹ́ ilẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 26:32, 33) Òǹṣèwé tó ń jẹ́ André Chouraqui sọ pé, “ọgbọ́n tí [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] dá sí ìṣòro náà jọni lójú gan-an, àní títí dòní pàápàá.”

Irú ilé wo ló ṣeé ṣe kí Ábúrámù (Ábúráhámù) gbé?

Ìlú Úrì, ìyẹn ìlú tó lọ́rọ̀ nílẹ̀ Kálídíà ni Ábúrámù àti aya rẹ̀ gbé. Àmọ́, wọ́n fi ìlú náà sílẹ̀ nítorí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú àgọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 11:31; 13:12) Ronú nípa ohun tí ìyípadà yìí ti ní láti mú kí wọ́n ṣe.

Lọ́dún 1922 sí ọdún 1934, Ọ̀gbẹ́ni Leonard Woolley hú ilẹ̀ ìlú Úrì tó wà ní orílẹ̀-èdè Ìráàkì òde òní. Lára àwọn ilé tó rí níbẹ̀ ni ilé mẹ́tàléláàádọ́rin [73] tí wọ́n fi bíríkì kọ́. Àwọn yàrá tó wà ní ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé náà ló wà yíká àgbàlá ilé náà, tí ọ̀dẹ̀dẹ̀ wọn sì dami sí àárín, níbi tí omi ìdọ̀tí lè gbà ṣàn lọ. Ní àwọn ilé ńláńlá, àwọn yàrá ìgbàlejò máa ń ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tiwọn. Àwọn yàrá tó wà ní ìsàlẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ní ilé ìgbọ́únjẹ àti ààrò ìdáná tó ń mú kí ilé móoru àti yàrá táwọn ẹrú ń sùn. Òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì làwọn tó ni ilé máa ń gbé, àtẹ̀gùn ni wọ́n máa ń gùn dé ibẹ̀. Àwọn àtẹ̀gùn náà lọ sí ọ̀dẹ̀dẹ̀ onígi tó wà lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì yíká àgbàlá náà, wọ́n sì lọ sẹ́nu ọ̀nà àwọn yàrá náà.

Ọ̀gbẹ́ni Woolley sọ pé: “Ilé kan . . . , tó ní àgbàlá pẹ̀lú ọ̀dẹ̀dẹ̀, tí wọ́n sì kun ògiri rẹ̀ lẹ́fun, tó ní kòtò ìdaminù, . . . tó ní yàrá méjìlá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, jẹ́ ẹ̀rí pé ìgbésí ayé tó wà létòlétò gan-an ni àwọn èèyàn ibẹ̀ ń gbé. Ilé wọ̀nyí sì jẹ́ ti . . . àwọn kòlàkòṣagbe, àwọn onílé ìtajà, àwọn oníṣòwò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, àwọn akọ̀wé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ìkùdu, Horvot Mezada, Israel

[Credit Line]

© Masada National Park, Israel Nature and Parks Authority

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwòrán ilé táwọn èèyàn ń gbé ní àkókò Abúráhámù

[Credit Line]

© Àwòrán Látọwọ́: A. S. Whitburn