Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ìwọ Yóò Ṣe Àfẹ́rí”
Ó MÁA ń bà wá nínú jẹ́ láti rí àwọn èèyàn wa tí wọ́n ń jìyà títí wọ́n fi kú. Ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá wa tí irú ohun bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa. Àmọ́, ó ń tuni nínú láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà Ọlọ́run mọ ẹ̀dùn ọkàn wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó fẹ́ láti lo agbára ńlá rẹ̀ láti mú kí ẹni tó kú náà pa dà wà láàyè. Kíyè sí ọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìrètí tí Jóòbù sọ, èyí tó wà nínú Jóòbù 14:13-15.
Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà yẹ̀ wò. Jóòbù tó ní ìgbàgbọ́ tó ta yọ, dojú kọ àwọn àdánwò tó lé gan-an. Ó pàdánù àwọn ohun ìní rẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ kú, àìsàn burúkú kan sì bá a fínra. Nígbà tó wà nínú ìrora gógó yìí, ó ké pe Ọlọ́run pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù [ipò òkú]!” (Ẹsẹ 13) Jóòbù wò ó pé Ṣìọ́ọ̀lù ló máa fòpin sí gbogbo ìjìyà òun. Ibẹ̀ ni òun ti máa bọ́ lọ́wọ́ ìrora àti ìjìyà, tí òun á dàbí ìṣúra tí Ọlọ́run fi pa mọ́. *
Ṣé inú Ṣìọ́ọ̀lù ni Jóòbù á máa wà títí lọ? Jóòbù kò gbà bẹ́ẹ̀. Ó ń bá àdúrà rẹ̀ lọ pé: “Pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!” Jóòbù ní ìrètí tó dájú pé òun kò ní pẹ́ lọ títí nínú Ṣìọ́ọ̀lù àti pé Jèhófà kò ní gbàgbé òun. Jóòbù fi ìgbà tó máa lò nínu Ṣìọ́ọ̀lù wé “òpò [tó] ní láti ṣe lápàpàǹdodo,” ìyẹn ìgbà tó fi ní láti dúró. Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó? Ó sọ pé, “Títí ìtura mi yóò fi dé.” (Ẹsẹ 14) Ìtura yẹn túmọ̀ sí ìgbà tí Ọlọ́run máa tú u sílẹ̀ kúrò ní Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn ìgbà tó máa jí i dìde nínú ikú!
Kí nìdí tó fi dá Jóòbù lójú pé ìtura òun yóò dé? Ìdí ni pé ó mọ bí ọ̀ràn àwọn olóòótọ́ tí wọ́n ti kú ṣe rí lára Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́. Jóòbù sọ pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Ẹsẹ 15) Jóòbù mọ̀ pé òun jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Ó dájú pé Ẹni tó fún Jóòbù ní ìyè nígbà tó wà nínú ilé ọlẹ̀ yóò jí Jóòbù dìde lẹ́yìn tó bá kú.—Jóòbù 10:8, 9; 31:15.
Àwọn ọ̀rọ̀ Jóòbù kọ́ wa pé Jèhófà jẹ́ aláàánú. Ó ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn tó fi ara wọn sí ìkáwọ́ rẹ̀ bí Jóòbù ti ṣe, pé kí ó mọ àwọn, kí ó sì tún àwọn ṣe, káwọn lè jẹ́ ẹni tó ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Aísáyà 64:8) Ojú iyebíye ni Jèhófà fi ń wo àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn rẹ̀. Ó sọ nípa àwọn adúróṣinṣin tí wọ́n ti kú pé, òun ń “ṣe àfẹ́rí” wọn. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò jẹ́ “ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ tó lágbára jù lọ tó ń ṣàlàyé ìfẹ́ ọkàn ẹnì kan tó fẹ́ ṣe ohun kan.” Bẹ́ẹ̀ ni o, kì í ṣe pé Jèhófà rántí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó tún fẹ́ láti jí wọn dìde láti wà láàyè.
A dúpẹ́ pé Jèhófà sọ èrò rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde nínú ìwé Jóòbù, ìyẹn ìwé tó wà lára àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ. * Jèhófà fẹ́ kí ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ tí wọ́n ti kú pa dà rí ara yín. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe yìí máa mú kó rọrùn fún wa láti fara da á téèyàn wa bá kú. A rọ̀ ẹ́ pé kó o kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yìí, kó o sì kọ́ nípa bó o ṣe lè jẹ́ kí ó mọ ẹ́, kó sì tún ẹ ṣe, kó o bàa lè di ẹni tó máa rí nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe nígbà tó bá ṣe é.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún March:
^ Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ohun tí ọ̀rọ̀ Jóòbù náà, “fi mí pa mọ́” lè túmọ̀ sí ni “fi [mí] sí ibi ààbò gẹ́gẹ́ bí ohun iyebíye.” Ìwé míì sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí “fi mí pa mọ́ bí ohun ìṣúra.”
^ Láti mọ púpọ̀ sí i nípa ìlérí tó wà nínú Bíbélì nípa àjíǹde sí ìyè nínú ayé tuntun òdodo, ka orí 7 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.