Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsọtẹ́lẹ̀ 6. Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Kárí Ayé

Àsọtẹ́lẹ̀ 6. Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Kárí Ayé

Àsọtẹ́lẹ̀ 6. Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Kárí Ayé

“A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—MÁTÍÙ 24:14.

● Obìnrin kan tó ń jẹ́ Vaiatea ń gbé ní erékùṣù Pàsífíìkì tó wà ní àdádó ní Tuamotu Archipelago. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, erékùṣù Tuamotu ní nǹkan bí ọgọ́rin [80] erékùṣù káàkiri agbègbè tó fẹ̀ ju ogójì ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbàá àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (802,900) kìlómítà lọ, síbẹ̀ nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [16,000] èèyàn ló ń gbé ibẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí lọ sọ́dọ̀ Vaiatea àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn, ní ibi yòówù kí wọ́n máa gbé.

KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń dé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún 2010 nìkan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún mẹ́fà wákàtí láti wàásù ìhìn rere yìí ní ilẹ̀ igba àti mẹ́rìndínlógójì [236]. Ìyẹn sì túmọ̀ sí pé, ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan lò láti fi wàásù lójúmọ́. Ní ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá báyìí, wọ́n ti ṣe ìtẹ̀jáde tó lé ní ogún bílíọ̀nù, wọ́n sì ti pín wọn fún àwọn èèyàn.

ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni wọ́n ti ń wàásù ohun tó wà nínú Bíbélì.

ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Òótọ́ ni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ti wàásù nípa ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, ìgbà díẹ̀ ni ọ̀pọ̀ fi ṣe é, ibi tí wọ́n sì ṣe é dé kò tó nǹkan. Ṣùgbọ́n ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀, wọ́n ti ń ṣe ìṣẹ́ ìwàásù tó kárí ayé tó sì dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe láìka àtakò tí àwọn alágbára kan tí wọ́n jẹ́ aláìláàánú ṣe sí wọn sí. * (Máàkù 13:13) Síwájú sí i, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba owó nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n yọ̀ǹda àkókò wọn, wọ́n sì ń fún àwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde wọn lọ́fẹ̀ẹ́. Ọrẹ àtinúwá ni wọ́n fi ń ṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wọn.

KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ìwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” ti kárí ayé? Ṣé bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ fi hàn pé ohun kan tí ó dára jù ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo fídíò mẹ́ta yìí, “Faithful Under Trials,” “Purple Triangles,” àti “Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń pín wọn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“A óò máa bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà nìṣó pẹ̀lú ìtara, a ó sì máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti wàásù fún àwọn èèyàn títí Jèhófà fi máa sọ pé, ó tó.”—2010 YEARBOOK OF JEHOVAH’S WITNESSES.