Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Fẹ́ràn Ìrìn-àjò Àti Eré Ìfarapitú

Mo Fẹ́ràn Ìrìn-àjò Àti Eré Ìfarapitú

Mo Fẹ́ràn Ìrìn-àjò Àti Eré Ìfarapitú

Gẹ́gẹ́ bí Zoya Dimitrova ṣe sọ ọ́

Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ọwọ́ mi tẹ ohun tí mò ń lépa, mò ń láyọ̀ bí mo ti ń fi ara pitú àti bí mo ṣe ń rin ìrìn-àjò káàkiri pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèré yìí. Àmọ́ ní September 4, ọdún 1970, àjálù kan bá mi. Bí mo ṣe tọ́ sókè lálá, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, mo ti já bọ́ lulẹ̀.

WỌ́N bí mi ní December 16, ọdún 1952, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí wa nílùú Sofia, lórílẹ̀-èdè Bulgaria. Ní àkókò yẹn, ètò ìjọba Kọ́múníìsì ni wọ́n ń lò lórílẹ̀-èdè Bulgaria, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò fòfin de ẹ̀sìn, àmọ́ wọn kò fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe ẹ̀sìn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn náà ni kò gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà ní kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi sọ pé onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì làwọn, wọn kò fi ẹ̀kọ́ ìsìn kọ́ mi, mi ò sì ronú nípa Ọlọ́run rárá.

Láti kékeré ni mo ti fẹ́ràn onírúurú eré ìdárayá, àmọ́ eré ìdárayá tí èèyàn ti ń fara pitú ni mo fẹ́ràn jù. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, ọkùnrin kan wá sílé ìwé wa, ó ń wá ọmọbìnrin kan tí wọ́n lè kọ́ ní eré ìdárayá téèyàn ti ń fara pitú. Olùkọ́ tó ń kọ́ mi ní eré yìí sọ pé èmi ló máa dára fún eré náà. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mọ́níjà náà fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ṣe ní Amẹ́ríkà gbé mi lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, kí wọ́n sì ṣe ìdánrawò fún mi. Inú mi dùn gan-an nígbà tí wọ́n mú mi. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn o, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdánrawò náà gbóná girigiri, ó sì lé ní ọdún méjì ti mo fi ṣe é. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mi parí, mo di eléré ìdárayá tó ń fara pitú, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í rin ìrìn-àjò káàkiri pẹ̀lú àwọn eléré ìdárayá yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, mo rin ìrìn-àjò jákèjádò orílẹ̀-èdè Bulgaria, lẹ́yìn náà mo lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ìjọba Soviet Union, kódà mo lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè bí Algeria, Hungary àti Yugoslavia tìgbà yẹn.

Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi ń ṣeré tó wù mí yẹn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, níbi tí mo ti ń fara pitú nílùú Titov Veles, lórílẹ̀-èdè Macedonia, ni jàǹbá ti mo sọ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi ṣẹlẹ̀ sí mi. Mo ń fi ara mi pitú lókè, níwájú ọ̀pọ̀ òǹwòran tí wọ́n jókòó. Ẹnì kejì tá a jọ ń ṣeré so ara rẹ̀ rọ̀ nísàlẹ̀, á jù mí sókè lálá, á sì hán mi nígbà tí mo bá ń bọ̀ nílẹ̀. Mo tàsé ọwọ́ rẹ̀, okùn tí mo so mọ́ra láti gbà mí dúró sì já, bí mo ṣe já bọ́ láti òkè tó ga tó ilé alágbèékà kan nìyẹn. Wọ́n sáré gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn, níbẹ̀ wọ́n rí i pé apá mi ti dá, àwọn kan lára egungun ìhà mi ti kán, egungun ẹ̀yìn mi sì dá pẹ̀lú. Mo kú sára fún bí ọjọ́ mélòó kan, mi ò sì mọ nǹkan kan. Nígbà tí mo jàjà pa dà jí, mo wá rí i pé ara mi ti rọ láti ìbàdí lọ sísàlẹ̀. Àmọ́ nítorí pé mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, mo nírètí pé iṣẹ́ abẹ́ àti ìtọ́jú ara lè mú kí n pa dà fẹsẹ̀ mi rìn, ó sì lè ṣeé ṣe fún mi láti pa dà sí í ṣe eré ìfarapitú pẹ̀lú àwọn òṣèré yòókù.

Ọdún méjì ààbọ̀ ni mo fi gba ìtọ́jú láwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ń ṣàìsàn tí kò lọ bọ̀rọ̀, mo nírètí pé ara mi máa yá. Nígbà tó yá, mo gbà pé kò lè ṣeé ṣe mọ́. Ní báyìí, bí mo ṣe rò ó kọ́ ló rí, mo ní láti máa wà lórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláàbọ̀ ara, èyí sì yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó wù mí, ìyẹn kí n máa rìnrìn àjò káàkiri kí n sì máa ṣe eré ìfarapitú.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé Tuntun

Lẹ́yìn tí mo ti gbé ìgbésí ayé tó gba pé kí n máa lọ káàkiri, mo rò pé kò ní ṣeé ṣe fún mi láti fara da ipò tí mo bá ara mi yìí. Mi ò ní ìrètí kankan, ìdààmú ọkàn sì bá mi. Lẹ́yìn náà lọ́dún 1977, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Stoyan wá sílé mi. Nígbà tí mo wá mọ̀ pé èmi àti àbúrò rẹ̀ la jọ ń ṣeré ìfarapitú tẹ́lẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo ní kó wọlé. Nígbà tí à ń jíròrò, ó béèrè lọ́wọ́ mi bóyá mo nírètí pé ara mi máa yá. Nítorí pé gbogbo nǹkan tojú sú mi, tí mo sì rí ìjákulẹ̀, mo fèsì pé kò sí ìrètí kankan. Nígbà tó sọ fún mi pé Ọlọ́run nìkan ló lè ràn mí lọ́wọ́, mo fi ẹ̀hónú fèsì pé: “Ó dáa, tí Ọlọ́run bá wà kí ló dé tí mo wà nírú ipò yìí?”

Ọ̀rọ̀ tí mo sọ yìí mú kí Stoyan, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó ń ṣiṣẹ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà pẹ̀lú àwọn eléré ìdárayá tó ń fara pitú, finú tútù ṣàlàyé fún mi nípa ìlérí àgbàyanu tí Bíbélì ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé láìpẹ́ ayé yìí yóò di Párádísè. Ìlérí náà pé, “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́” wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. (Ìṣípayá 21:4) Ó wù mí gan-an kí n pa dà ní ìlera tó dáa! Mo gbà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Báyìí ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun. Níkẹyìn, mo ti wá ní ìrètí gidi!

Mo máa ń fojú sọ́nà fún ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ mi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Stoyan ló kọ́kọ́ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, lẹ́yìn náà ni Totka kọ́ mi, obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí jẹ́ onínúure. Òun ló ràn mí lọ́wọ́ tí ìmọ̀ mi nínú Bíbélì fi yára pọ̀ sí i, tí mo sì ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Ní àkókò yẹn, kò sí ẹni tó lè ṣe ìrìbọmi fún mi nílùú Sofia, nítorí náà mo ní láti dúró dìgbà tí arákùnrin kan máa wá láti orílẹ̀-èdè Macedonia. Ní September 11, ọdún 1978, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ṣèrìbọmi nínú ọpọ́n ìwẹ̀ kan nínú ilé mi. Ìrìbọmi tí mo ṣe láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà múnú mi dùn gan-an, ìgbésí ayé mi sì wá nítumọ̀ gidi.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ti kọ́ ń jó nínú mi bí iná. Mo máa ń fìtara sọ fún gbogbo àwọn èèyàn tó wá sílé mi nípa ìrètí tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní. Ó dùn mí gan-an pé kò sẹ́ni tó fojú pàtàkì wo ohun tí mò ń sọ, bóyá wọ́n ń rò pé jàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí mi ló sọ mí di ẹni tí orí rẹ̀ kò pé dáadáa.

Àṣìṣe Ńlá Kan

Ní àkókò yẹn, wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Bulgaria, àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ ló sì wà lórílẹ̀-èdè náà. Kò sí ìpàdé ìjọ tí mo lè lọ, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Nítorí ìdí èyí àti pé mi ò kíyè sí ewu tó wà nínú kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, èyí mú kí n ṣe àṣìṣe ńlá kan.

Ẹ̀rí ọkàn mi ń dà mí láàmù gan-an, mo sì ní ìrora ọkàn nítorí mo di àjèjì sí Jèhófà Ọlọ́run. Ọkàn mi bà jẹ́ gidigidi, ojú sì tì mí, mo gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, mo bẹ̀bẹ̀ pé kó dárí jì mí. Nígbà tó yá, àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ ràn mí lọ́wọ́, mo pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, mo sì ń sìn ín tayọ̀tayọ̀. Mo mọyì fífi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ jọ́sìn Jèhófà àti dídara pọ̀ mọ́ ètò rẹ̀ mímọ́!

Mo Láyọ̀ Bi Mo Tilẹ̀ Jẹ́ Aláìlera

Jàǹbá tó ṣe mí ní ogójì ọdún sẹ́yìn ṣàkóbá fún eré ìfarapitú àti ìrìn-àjò káàkiri tó wù mí, mo sì wá dẹni tó wà lórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláàbọ̀ ara. Síbẹ̀, inú mi kò bà jẹ́, mi ò sì kábàámọ̀. Ẹ̀kọ́ Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ayọ̀ àti àṣeyọrí nínú eré ìfarapitú kò lè fúnni ní ayọ̀ tó wà pẹ́ títí. Mo ti rí i bí àwọn ẹlẹgbẹ́ mi tí wọ́n ń bá eré ìfarapitú nìṣó ṣe ní ìjákulẹ̀ tó burú jù nígbèésí ayé wọn. Àmọ́ mo ti ní ohun tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá mi, Jèhófà Ọlọ́run. Ìyẹn ti fún mi ní ayọ̀ tó pọ̀ gan-an ju èyí tí mo lè rí nínú eré ìfarapitú.

Yàtọ̀ síyẹn, mo ti ní ayọ̀ rírí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọdún 1977, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà díẹ̀ ló wà lórílẹ̀-èdè Bulgaria. Àní títí di ọdún 1991, nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba lẹ́yìn tí Ìjọba Kọ́múníìsì forí ṣánpọ́n, àwọn Ẹlẹ́rìí kò ju ọgọ́rùn-ún kan lọ ní gbogbo orílẹ̀-èdè yìí. Ó múnú mi dùn gan-an láti rí i tí iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń pọ̀ sí i títí di ìsinsìnyí tí iye náà sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀sán [1,800]!

Iṣẹ́ púpọ̀ ṣì wà láti ṣe lórílẹ̀-èdè Bulgaria. Ọ̀pọ̀ ló ń wá ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun tó jẹ́ ká mọ èyí ni bí àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2010 ṣe pọ̀ tó, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín ọgọ́rin ó lé mẹ́fà [3,914]. Inú mi dùn gan-an láti rí ẹ̀rí yìí pé Jèhófà ti bù kún ohun tó bẹ̀rẹ̀ lọ́nà kékeré ní orílẹ̀-èdè Bulgaria. Lójú mi kòrókòró “ẹni kékeré” ti pọ̀ di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè,” gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 60:22 ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

Ohun míì tó ń fún mi láyọ̀ tó sì ṣe pàtàkì sí mi ni títẹ̀ tí wọ́n tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Bulgaria. Èyí ṣẹlẹ̀ ní August 2009 ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Sọ́nà!” tá a ṣe nílùú Sofia. Bíbélì tí wọ́n ṣe ní èdè ìbílẹ̀ mi yìí jẹ́ ohun kan tí a ti ń retí tipẹ́tipẹ́! Ó dájú pé yóò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn sí i lórílẹ̀-èdè Bulgaria kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìlera mi kò lè jẹ́ kí n ṣe tó bí mo ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, inú mi máa ń dùn gan-an láti máa wàásù òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn aládùúgbò mi àti ẹni tó bá wá sílé mi. Lọ́jọ́ kan tí mo wà ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé mi, mo pe aládùúgbò mi kan tó ń kọjá lọ. Obìnrin náà sì wá bá mi, mo sọ oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ìyànjú fún un látinú Bíbélì, ó sì gbà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé kí n máa kọ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ayọ̀ mi pọ̀ gan-an nígbà tó ṣèrìbọmi tó sì di arábìnrin mi nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Mo ti láǹfààní láti ran èèyàn mẹ́rin lọ́wọ́, wọ́n sì ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.

Ohun tó jẹ́ olórí ayọ̀ mi, tó sì ń fún mi ní ìṣírí ni àwọn ìpàdé ìjọ tí mo ń lọ déédéé pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n lé ní ọgọ́rùn-ún, wọ́n dà bí ìdílé fún mi. Ó gba akitiyan kí n tó lè máa lọ sáwọn ìpàdé nítorí orílẹ̀-èdè yìí kò ní àwọn ohun ìrìnnà tí wọ́n ṣe lákànṣe fún àwọn arúgbó àtàwọn aláàbọ̀ ara. Àmọ́, mo dúpẹ́ pé ọ̀dọ́kùnrin kan máa ń bójú tó mi tìfẹ́tìfẹ́. Lọ́jọ́ ìpàdé kọ̀ọ̀kan, á gbé mi láti inú ilé sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, á tún gbé mi látinú ọkọ̀ náà sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, lẹ́yìn náà, á gbé mi pa dà lọ sílé. Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé mo láǹfààní láti jẹ́ ara ìdílé onífẹ̀ẹ́ yìí!

Nígbà tí mo rò ó lọ́, rò ó bọ̀, mo rí i pé ìgbésí ayé mi ti yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó wù mí nígbà tí mo wà ní kékeré. Sísin Jèhófà ti jẹ́ kí n ní ayọ̀ tó pọ̀ nísinsìnyí, ó sì ti jẹ́ kí n máa retí nǹkan àgbàyanu tó ń bọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Mo mọyì ìlérí Ọlọ́run pé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, “ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.” (Aísáyà 35:6) Ọkàn mi balẹ̀ gan-an bí mo ti ń wo ọ̀nà fún ọjọ́ náà nígbà tí màá fó dìde lórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláàbọ̀ ara, tí ara mi a ti pa dà bọ̀ sípò pẹ̀lú ìlera àti okun pípé.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

“Ohun tó jẹ́ olórí ayọ̀ mi, tó sì ń fún mi ní ìṣírí ni àwọn ìpàdé ìjọ tí mo ń lọ déédéé”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]

‘Ohun tó ṣe pàtàkì sí mi ni títẹ̀ tí wọ́n tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Bulgaria’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré ìfarapitú nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún