Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ò Ní Pa Ayé Yìí Run Báyìí?”

“Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ò Ní Pa Ayé Yìí Run Báyìí?”

“Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ò Ní Pa Ayé Yìí Run Báyìí?”

● Téèyàn bá wo ayé yìí látojú òfuurufú, ó rẹwà gan-an bíi péálì iyebíye. Àmọ́ àyẹ̀wò fínnífínní fi hàn pé ayé wa yìí wà nínú ewu. Kí nìdí? Ìdí ni pé: Àwọn èèyàn tó ń gbé nínú ayé kò lò ó dáadáa. Wọ́n ti ba ayé jẹ́, yàtọ̀ sí pé wọ́n ti ba afẹ́fẹ́ jẹ́, tí wọ́n pa àwọn igi run, tí wọ́n sì ti lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ayé nílòkulò, wọ́n tún ti fi ìṣekúṣe ba ayé yìí jẹ́ nípa híhùwà ipá, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìbálòpọ̀ tí kò tọ́, tí èyí sì ti mú káwọn èèyàn jìnnà sí Ọlọ́run.

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó lágbára nípa ipò tó ń báni nínú jẹ́ tí ayé wa yìí wà. (2 Tímótì 3:1-5; Ìṣípayá 11:18) Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé, èèyàn kọ́ ló máa tún ayé yìí ṣe, àmọ́ Ọlọ́run ló máa tún un ṣe. Wọ́n máa ṣàlàyé kòkó yìí nínú àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ò Ní Pa Ayé Yìí Run Báyìí?” A máa sọ àsọyé yìí ní Àpéjọ Àgbègbè tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe, àkòrí àpéjọ náà ni, “Kí Ìjọba Ọlọ́run Dé!” Ó máa bẹ̀rẹ̀ láti oṣù May ọdún yìí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti káàkiri ayé.

A fi tayọ̀tayọ̀ pè ọ́ pé kó o lọ sí àpéjọ yìí tó wà ní ìtòsí rẹ. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀ràn yìí, lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé yìí. Wàá rí ibi tá a ti máa ṣe àwọn àpéjọ yìí lórí ìkànnì wa www.ps8318.com.