Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run?
Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run?
“Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ni bí a ṣe máa kórìíra èèyàn, àmọ́ wọn kò kọ́ni bí a ṣe máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.”—JONATHAN SWIFT, ÒǸṢÈWÉ ỌMỌ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ.
ỌGỌ́RÙN-ÚN ọdún kejìdínlógún ni ọ̀gbẹ́ni Swift sọ ọ̀rọ̀ yẹn, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló máa gbà pé òótọ́ ló sọ. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé àwọn òbí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run. Wọ́n sọ pé, àwọn ọmọ tí wọ́n bá fi ẹ̀sìn kọ́ láti kékeré kì í lè ronú dáadáa.
Kí ni èrò rẹ? Èwo lára àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí ló bọ́gbọ́n mu jù lọ?
● Kò yẹ kí wọ́n gba àwọn òbí láyè láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run.
● Àwọn òbí ní láti dúró títí dìgbà táwọn ọmọ wọn bá dàgbà kí wọ́n tó máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn.
● Ó yẹ káwọn òbí fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré. Àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ náà bá ti dàgbà, kí àwọn òbí gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ronú lórí ọ̀ràn náà fúnra wọn.
● Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ohun tí àwọn òbí wọn gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run láì ṣèwádìí.
Ṣé Ẹ̀sìn Máa Ń Ṣàkóbá fún Àwọn Ọmọdé?
Kò sí òbí onífẹ̀ẹ́ tó máa fẹ́ ṣàkóbá fún àwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́, ṣé ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà lóòótọ́ pé kò dára láti kọ́ àwọn ọmọdé nípa Ọlọ́run? Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn olùṣèwádìí ti fara balẹ̀ ṣèwádìí nípa bí ohun táwọn òbí gbà gbọ́ ṣe máa ń nípa lórí àwọn ọmọ. Kí ni àbájáde ìwádìí wọn?
Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé ẹ̀sìn kò lè ṣàkóbá fún ọmọdé, kàkà bẹ́ẹ̀, ó lè mú kí wọ́n di ọmọlúwàbí. Ní ọdún 2008, ìwé ìròyìn Social Science Research * sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé ẹ̀sìn máa ń mú kí àárín ọmọ àti òbí gún régé.” Ìròyìn náà tún sọ pé: “Ó jọ pé ẹ̀sìn àti ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ọmọdé, ó sì ṣe pàtàkì fún mímú kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan.” Kíyè sí bí ìwádìí tí wọ́n gbé jáde yìí ṣe jọ ohun tí Jésù Kristi sọ, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.
Èrò tí àwọn èèyàn ní pé àwọn ọmọ ní láti dàgbà kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti ẹ̀sìn ńkọ́? Èrò ná kò dára tó. Wo àkàwé yìí: Ńṣe ni ọkàn ọmọ kan dà bí korobá tí kò sí nǹkan kan nínú rẹ̀. Ọwọ́ àwọn òbí ló kù sí bóyá wọ́n á kó àwọn ìlànà ìwà rere àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n rí i pé ó dára sínú rẹ̀ ní ilé tàbí wọ́n á jẹ́ kí àwọn èèyàn burúkú láti ìta kó èrò búburú sínú rẹ̀.
Kí Ni Ojútùú Ọ̀ràn Náà?
Ẹ̀rí ti fi hàn pé ẹ̀sìn lè jẹ́ kéèyàn ní èrò burúkú sí àwọn èèyàn, kéèyàn sì kórìíra wọn. Nítorí náà, kí làwọn òbí lè ṣe tí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn kò fi ní dà bí ohun tí Jonathan Swift sọ? Báwo ni wọ́n ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ohun tó lè mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?
Ojútùú ọ̀ràn náà wà nínú ìdáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Kí ni àwọn ọmọdé ní láti kọ́? (2) Ta ni ó yẹ kí ó kọ́ wọn? (3) Àwọn ọ̀nà wo ló dára jù lọ tí a lè gbà kọ́ wọn?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Èyí jẹ́ látinú ìwádìí tí wọ́n ṣe lọ́dọ̀ àwọn ọmọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún [21,000] ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti lọ́dọ̀ àwọn òbí àtàwọn olùkọ́ wọn.