Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọkọ Tàbí Aya Rẹ
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọkọ Tàbí Aya Rẹ
Will * sọ pé: “Nígbà tí Rachel bá bínú, ńṣe ló máa ń sunkún ṣáá. Tí a bá jókòó láti sọ̀rọ̀, ó máa ń kanra tàbí kí ó má sọ̀rọ̀ rárá. Kò sí ohun tí mo ṣe tó máa tẹ́ ẹ lọ́rùn. Gbogbo ẹ̀ ti sú mi.”
Rachel sọ pé: “Nígbà tí Will dé, ó bá mi tí mò ń sunkún. Mo gbìyànjú láti ṣàlàyé ìdí tí inú fi ń bí mi, àmọ́ ńṣe ló dá ọ̀rọ̀ mọ́ mi lẹ́nu. Ó sọ fún mi pé ọ̀ràn náà kò le tóyẹn, pé kí n gbàgbé ẹ̀. Ńṣe nìyẹn túbọ̀ múnú bí mi.”
ǸJẸ́ ohun tó ṣe Will àti Rachel yìí ń ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà? Àwọn méjèèjì máa ń fẹ́ bá ara wọn sọ̀rọ̀, àmọ́ ńṣe ni wọ́n sábà máa ń da ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú. Kí nìdí?
Ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin ń gbà sọ̀rọ̀ yàtọ̀ sí ti àwọn obìnrin, ohun tí wọ́n ń fẹ́ sì yàtọ̀ síra. Àwọn obìnrin sábà máa ń fẹ́ láti sọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára wọn. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọkùnrin máa ń fẹ́ kí àlàáfíà wà, kí ìṣòro sì yanjú kíákíá kó má bàa di gbọ́nmi sí omi ò to. Kí lo lè ṣe nípa ìyàtọ̀ yìí tí á fi ṣeé ṣe fún ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ láti máa sọ̀rọ̀ fàlàlà? Ohun tó o lè ṣe ni pé, kó o máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya rẹ.
Ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fúnni máa ń mọyì àwọn èèyàn, ó sì máa ń gbìyànjú láti lóye ohun tí wọ́n fẹ́. Ó lè jẹ́ pé láti kékeré lo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kó o máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tí wọ́n ní ìrírí, tí wọ́n sì ní àṣẹ tó ju tìrẹ lọ. Àmọ́ tó bá di ọ̀ràn lọ́kọláya, ó gba ìsapá kí àwọn méjèèjì tó lè máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn nítorí pé, ipò kan náà làwọn méjèèjì jọ wà. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Linda tó ti lọ́kọ fún ọdún mẹ́jọ sọ pé: “Mo mọ̀ pé Phil máa ń fi sùúrù àti òye gbọ́ ohun tí àwọn ẹlòmíì bá ń sọ fún un. Mo fẹ́ kí ó máa gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi náà bẹ́ẹ̀.” O ṣeé ṣe kí o máa fi sùúrù fetí sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn àlejò, kó o sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àmọ́, ṣé bí o ṣe ń ṣe sí ọkọ tàbí aya rẹ náà nìyẹn?
Ìwà àìlọ́wọ̀ máa ń fa gbúngbùngbún nínú ilé, ó sì máa ń yọrí sí ìjà. Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan tó jẹ́ olùṣàkóso sọ pé: “Okele gbigbẹ ti on ti alafia, o san jù ile ti o kun fun ẹran-pipa ti on ti ija.” (Òwe 17:1, Bibeli Mimọ) Bíbélì ní kí ọkọ máa bọlá fún aya rẹ̀ tàbí kí ó máa bọ̀wọ̀ fún un. (1 Pétérù 3:7) Bákan náà, ó ní, “kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
Báwo ni o ṣe lè bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀? Gbé àwọn ìmọ̀ràn kan tó wà nínú Bíbélì yẹ̀ wò.
Nígbà tí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Fẹ́ Sọ Ohun Kan
Ìṣòro: Ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ ju láti máa fetí sílẹ̀ lọ. Ṣé ìwọ náà wà lára wọn? Bíbélì sọ pé òmùgọ̀ ni ẹni tó bá “ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ.” (Òwe 18:13) Nítorí náà, kí o tó sọ̀rọ̀, fetí sílẹ̀. Kí nìdí? Obìnrin kan tó ń jẹ́ Kara tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí ọkọ mi yanjú ìṣòro mi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí mo ti ń sọ ọ́ fún un. Kò pọn dandan pé kó mọ bí ìṣòro náà ṣe wáyé. Ohun tí mò ń fẹ́ kó ṣe ni pé kó fetí sílẹ̀ sí mi, kó sì gbà pé ìṣòrò ni lóòótọ́.”
Àmọ́ àwọn ọkùnrin kan àtàwọn obìnrin kan kì í fẹ́ sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn, ó sì máa ń ni wọ́n lára tí ẹnì kejì wọn bá ní kí wọ́n sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Lorrie tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ti rí i pé ó máa ń pẹ́ kí ọkọ rẹ̀ tó lè sọ èrò rẹ̀ jáde. Ó sọ pé: “Mo ní láti mú sùúrù, kí n sì dúró dìgbà tó máa sọ̀rọ̀.”
Ojútùú: Bí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ bá ní láti sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí ohùn yín kò ti ṣọ̀kan, dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ nígbà tí ara ẹ̀yin méjèèjì bá balẹ̀. Bí ẹnì kejì rẹ kò bá fẹ́ sọ̀rọ̀ ńkọ́? Ó yẹ kó o mọ̀ pé, “ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yoo fà á jáde.” (Òwe 20:5) Tó o bá ń kánjú fa omi látinú kànga, ó dájú pé ọ̀pọ̀ omi ló máa dà nù nínú korobá náà kó tó dókè. Bákan náà, tó o bá ń fipá mú ẹnì kejì rẹ pé kó sọ̀rọ̀, ó lè yarí mọ́ ẹ lọ́wọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ béèrè ìbéèrè, kó o sì fi ọ̀wọ̀ hàn, mú sùúrù bí ẹnì kejì rẹ kò bá tètè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ bó o ṣe fẹ́ kó sọ ọ́.
Nígbà tí aya tàbí ọkọ rẹ bá wá sọ̀rọ̀, “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Ẹni tó mọ béèyàn ṣe ń fetí sílẹ̀ kì í fetí sí ọ̀rọ̀ tá a sọ nìkan, ó tún máa ń sapá láti mọ ohun tó mú kí ẹni náà sọ ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ẹnì kejì rẹ bá sọ̀rọ̀, sapá láti lóye ohun tó mú kó sọ ọ̀rọ̀ náà. Ẹnì kejì rẹ á mọ bí ọ̀wọ̀ tàbí àìlọ́wọ̀ tó o ní ti pọ̀ tó, látinú ọ̀nà tó ò ń gbà fetí sílẹ̀.
Jésù kọ́ wa bá a ṣe lè fetí sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin kan tó ń ṣàìsàn wá bá Jésù fún ìrànlọ́wọ́, Jésù kò yanjú ìṣòro náà lójú ẹsẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó fetí sí ohun tí ọkùnrin náà sọ. Lẹ́yìn náà, ó gbìyànjú láti mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ọkùnrin yẹn. Níkẹyìn, ó wo ọkùnrin náà sàn. (Máàkù 1:40-42) Àpẹẹrẹ yẹn ni kó o tẹ̀ lé nígbà tí ẹnì kejì rẹ bá ń sọ̀rọ̀. Rántí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ń fẹ́ ni pé kó o fara balẹ̀ fetí sí òun, kì í ṣe pé kó o sáré yanjú ìṣòro rẹ̀. Nítorí náà, máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Kí o sì sapá láti mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn lo tó lè ṣe ohun tí ẹnì kejì rẹ fẹ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Nígbà tí ọkọ tàbí aya rẹ bá tún ti fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀, gbìyànjú láti má ṣe já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀. Dúró títí dìgbà tó bá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ohun tó sọ sì yé ọ. Lẹ́yìn náà, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ọ̀dọ̀ rẹ lọ́kàn mi wà látìgbà tó o ti ń sọ̀rọ̀?”
Nígbà Tí O Bá Fẹ́ Sọ Ohun Kan
Ìṣòro: Obìnrin tó ń jẹ́ Linda tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Àwọn aláwàdà orí Tẹlifíṣọ̀n máa ń fi hàn pé kò burú láti sọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya ẹni láìdáa, kò sì burú láti pẹ̀gàn rẹ̀ àti láti bú u.” Ilé tí wọn kò ti ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu ni àwọn ẹlòmíì ti dàgbà. Nígbà tó bá yá tí wọ́n bá ṣègbéyàwó, ó máa ṣòro fún wọn láti jáwọ́ nínú ìwà burúkú yìí nínú ilé tiwọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ivy tó ń gbé ní Kánádà sọ pé: “Ibi tí wọ́n ti ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀, tí wọ́n ti máa ń pariwo lé ara wọn lórí, tí wọ́n sì ti máa ń pe ara wọn lórúkọ burúkú ni mo gbé dàgbà.”
Éfésù 4:29) Ọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya rẹ ni kó o máa sọ.
Ojútùú: Nígbà tó o bá ń bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ nípa ọkọ tàbí aya rẹ, ọ̀rọ̀ tí “ó dára fún gbígbéniró” ni kó o máa sọ, ìyẹn “bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ.” (Kódà nígbà tí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ bá dá wà, má ṣe sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí i, má sì pè é lórúkọ burúkú. Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, Míkálì bínú sí Dáfídì Ọba tó jẹ́ ọkọ rẹ̀. Ó sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí i, ó ní, ó ń ṣe bí “ọ̀kan nínú àwọn akúrí.” Ọ̀rọ̀ náà bí Dáfídì nínu, àní kò múnú Ọlọ́run pàápàá dùn. (2 Sámúẹ́lì 6:20-23) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́? Nígbà tó o bá ń bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀, máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. (Kólósè 4:6) Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Phil tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́jọ sọ pé òun àti ìyàwó òun ṣì máa ń ní èdèkòyédè. Ó ti kíyè sí i pé ohun tóun máa ń sọ nígbà míì máa ń mú kí nǹkan túbọ̀ dojú rú. Ó ní: “Mo ti wá rí i pé kì í ṣe ohun tó wúlò láti máa jiyàn ká lè mọ ẹni tó jàre. Ohun tí mo rí i pé ó ń mú ìtẹ́lọ́rùn àti àǹfààní wa ni kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ̀.”
Ní ayé àtijọ́, obìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ opó gba àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ níyànjú láti “rí ibi ìsinmi, olúkúlùkù ní ilé ọkọ rẹ̀.” (Rúùtù 1:9) Nígbà tí tọkọtaya bá buyì fún ara wọn, ilé wọn máa jẹ́ “ibi ìsinmi.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ wá àkókò láti jọ jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà níbí yìí. Béèrè lọ́wọ́ ẹni kejì rẹ pé: “Nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ níta, ṣé ọ̀rọ̀ mi máa ń bọlá fún ẹ ni àbí ó máa ń tàbùkù sí ẹ? Àwọn ohun wo ni mo lè ṣe láti ṣàtúnṣe?” Kí o fetí sílẹ̀ dáadáa bí ẹnì kejì rẹ ṣe ń sọ èrò rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn àbá tí ẹnì kejì rẹ bá sọ.
Fara Mọ́ Ìyàtọ̀ Tó Wà Nínú Ìwà Ẹnì Kejì Rẹ
Ìṣòro: Àwọn kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ní èrò kan tí kò tọ́ nípa ohun tí Bíbélì pè ní “ara kan,” wọ́n ní ó túmọ̀ sí pé tọkọtaya gbọ́dọ̀ ní èrò kan náà tàbí ìwà kan náà. (Mátíù 19:5) Àmọ́, kì í pẹ́ tí wọ́n á fi rí i pé irú èrò bẹ́ẹ̀ kò tọ̀nà. Ìgbà tó bá yá, ìyàtọ̀ àárín wọn á máa fa àríyànjiyàn. Linda sọ pé: “Ìyàtọ̀ ńlá kan tó wà láàárín wa ni pé, Phil kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàníyàn púpọ̀ bíi tèmi. Nígbà míì tí mo bá ń ṣàníyàn ńṣe ni ara tirẹ̀ máa balẹ̀, ìyẹn máa ń múnú bí mi nítorí ó jọ pé òun kì í bìkítà nípa nǹkan bíi tèmi.”
Ojútùú: Fara mọ́ ìwà ọkọ tàbí aya rẹ, kí o sì bọ̀wọ̀ fún un nítorí ìyàtọ̀ tó wà nínú ìwà rẹ̀. Àpèjúwe kan rèé: Iṣẹ́ tí ojú rẹ ń ṣe yàtọ̀ sí èyí tí etí rẹ ń ṣe, síbẹ̀ wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ìyẹn ló mú kí o lè sọ dá lójú títì láìséwu. Obìnrin tó ń jẹ́ Adrienne tó ti ṣègbéyàwó fún nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi kì í fi dandan lé e pé èrò wa gbọ́dọ̀ bára mu níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti ta ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó ṣe tán, a fẹ́ ara wa ni, kì í ṣe ọpọlọ kan náà là ń lò.”
Nígbà tí èrò ọkọ rẹ tàbí aya rẹ bá yàtọ̀ sí tìrẹ tàbí tí ìṣesí rẹ̀ yàtọ̀ sí tìrẹ, má ṣe máa wá ire ti ara rẹ. Ire ti ẹnì kejì rẹ ni kó o máa wá. (Fílípì 2:4) Kyle tó jẹ́ ọkọ Adrienne sọ pé: “Mi ò kì í fìgbà gbogbo lóye èrò ìyàwó mi tàbí kí n fara mọ́ èrò rẹ̀. Àmọ́ mo máa ń rán ara mi létí pé mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi ju èrò mi lọ. Tí inú rẹ̀ bá dùn, inú tèmi náà máa ń dùn.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀nà tí èrò ẹnì kejì rẹ tàbí ọ̀nà tó ń gbà bójú tó nǹkan ṣe dára ju tìrẹ lọ.—Fílípì 2:3.
Ọ̀wọ̀ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ń mú kí ìgbéyàwó láyọ̀ kó sì wà pẹ́ títí. Línda sọ pé “Ọ̀wọ̀ máa ń jẹ́ kí ìtẹ́lọ́rùn àti ààbò wà láàárín ọkọ àti aya. Ó dájú pé ó yẹ kéèyàn ní ọ̀wọ̀.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
BI ARA RẸ PÉ . . .
▪ Báwo ni ìyàtọ̀ nínú ìwà ọkọ tàbí aya mi ṣe túbọ̀ ń mú kí ìdílé wa láyọ̀?
▪ Kí nìdí tó fi dára kí n fara mọ́ ohun tí ọkọ tàbí aya mi bá fẹ́ nígbà tí kò bá ti ta ko ìlànà Bíbélì?