Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ní Àgbègbè Òkè Tó Ń Yọ Iná

Ní Àgbègbè Òkè Tó Ń Yọ Iná

Lẹ́tà Láti Congo (Kinshasa)

Ní Àgbègbè Òkè Tó Ń Yọ Iná

BÍ OÒRÙN ṣe yọ ní ìlú Goma, ni ojú ọ̀run pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Ojoojúmọ́ là ń rí ẹwà Òkè Nyiragongo, tó jẹ́ ọ̀kan lára òkè tó ń yọ iná àti èéfín jù lọ láyé. Èéfín tó pọ̀ máa ń jáde látinú ihò orí òkè náà lọ sójú sánmà. Ní alẹ́, àwọn nǹkan gbígbóná tó ń ru jáde látinú òkè ayọnáyèéfín náà máa ń pupa yòò.

Orúkọ tí wọ́n ń pe òkè yìí ní èdè Swahili ni Mulima ya Moto, ìyẹn Òkè Tó Ń Yọ Iná. Òkè Nyiragongo máa ń bú gbàù, àmọ́ ọdún 2002 ló bú gbàù lọ́nà tó kàmàmà jùlọ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn aládùúgbò àtàwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà ní Goma ló pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní. Láwọn ibì kan ní àgbègbè tí èmi àti ọkọ mi ti wàásù, a rìn lórí àwọn nǹkan tó ru jáde látinú òkè ayọnáyèéfín náà, nígbà tí àwọn nǹkan yìí gbẹ tán, ńṣe ni wọ́n le gbagidi tójú ilẹ̀ sì rí gbágungbàgun, mi ò tíì rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí. Àmọ́ ṣá o, ọkàn àwọn èèyàn ibẹ̀ kò le gbagidi bí àwọn nǹkan tó ru jáde látinú òkè ayọnáyèéfín náà. Wọ́n ní ọ̀yàyà, ọkàn rere ni wọ́n sì fi gba ìhìn rere tí a wàásù. Èyí mú kí lílọ wàásù fún àwọn èèyàn tó wà ní ibi eléwu yìí, ìyẹn àgbègbè Òkè Tó Ń Yọ Iná yìí mú inú mi dùn!

Nígbà tí mo jí ní òwúrọ̀ Sátidé tá a fẹ́ rìnrìn àjò náà, ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé ká ti bọ́ sọ́nà. Èmi àti ọkọ mi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn míṣọ́nnárì tí wọn wá sọ́dọ̀ wa fẹ́ lọ wàásù lọjọ́ náà ní Mugunga, ìyẹn ní àgọ́ àwọn tó ń wá ibi ìsádi, ní ìwọ̀ oòrùn ìlú náà. Ọ̀pọ̀ wọn ló sá wá síbẹ̀ nítorí ìjà tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú wọn.

A kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti èdè Faransé, Kiswahili àti èdè Kinyarwanda, sínú ọkọ̀ akẹ́rù tí à ń gbé lọ. Lẹ́yìn náà, a gbéra. Bí a ṣe ń já sí kòtò tí à ń já sí gegele lójú ọ̀nà kan tí wọ́n ń pè ní Route Sake, a rí ìlú náà lọ́ọ̀ọ́kán. A rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ń ti chukudus (kẹ̀kẹ́ onígi tí wọ́n fi ń ti ẹrù). Àwọn obìnrin tí wọ́n ró ìró aláràbarà ru ẹrù ńlá, wọ́n sì ń rìn lọ kánmọ́kánmọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ akérò sì ń gbé àwọn èèyàn lọ síbi iṣẹ́ àti ọjà. Àwọn ilé tí wọ́n fi igi kọ́ sì wà káàkiri, wọ́n ní àwọ̀ ilẹ̀ tí ó dà pọ̀ mọ́ dúdú, wọ́n sì fi ọ̀dà búlúù kun eteetí ilẹ̀kùn àti ojú fèrèsé.

A lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Ndosho, níbi tí àwọn kan tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a fẹ́ jọ lọ wàásù ní àgọ́ náà wà. Orí mi wú nígbà tí mo rí àwọn èwe, àwọn opó, àwọn ọmọ aláìlóbìí àtàwọn aláìlera. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni ìyà ti jẹ gan-an, àmọ́ ìgbésí ayé wọn ti dáa sí i torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la ń mú ọkàn wọn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì ń fẹ́ láti sọ nípa rẹ̀ fún àwọn èèyàn. Lẹ́yìn ìpàdé ráńpẹ́, nínú èyí tí a ti gbọ́ àbá nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a máa fi fún àwọn tí a bá rí ní ìṣírí, àwa àádóje [130] wọ ọkọ̀ bọ́ọ̀sì márùn-ún àti ọkọ̀ akẹ́rù kan, a sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà.

Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn náà, a dé àgọ́ náà. Wọ́n pa ọ̀pọ̀ àgọ́ kéékèèké tó funfun kẹnẹwẹn sórí àwọn nǹkan tó ru jáde látinú òkè ayọnáyèéfín náà lẹ́yìn tó ti le gbagidi. Àwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti ilé ìfọṣọ tó mọ́ tónítóní tí gbogbo èèyàn ń lò ló wà láàárín àgọ́ náà. Àwọn èèyàn wà káàkiri, tí wọ́n ń fọ nǹkan, wọ́n ń se oúnjẹ, wọ́n ń yọ ẹ̀wà kúrò nínú páádi rẹ̀, wọ́n sì ń gbá ilẹ̀ iwájú àgọ́ wọn.

A rí ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Papa Jacques, òun ló ń bójú tó àwọn èèyàn tó wà ní apá kan lára àwọn àgọ́ náà. Ohun tó jẹ ẹ́ lógún ni bó ṣe máa tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní àkókò wàhálà tí aráyé wà yìí. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí a fún un ní ìwé, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ó sọ pé òun máa kà á, lẹ́yìn tí òun bá kà á tán, òun á kó àwùjọ èèyàn kékeré kan jọ láti sọ ohun tí òun kà fún wọn.

Nígbà tá a rìn síwájú díẹ̀, a tún rí obìnrin kan tí wọ́n ń pè ní Mama Beatrice. Ó béèrè lọ́wọ́ wa nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Ó rò pé Ọlọ́run ló ń fi ìyà jẹ òun. Ọkọ rẹ̀ ti kú sógun, ọmọbìnrin rẹ̀ tí òun náà wà nínú àgọ́ yẹn ń dá tọ́ ọmọ kan ṣoṣo tó ní, wọ́n tún jí ọmọkùnrin Beatrice gbé ní oṣù mélòó kan sẹ́yìn. Kò sì mọ ibi tí ọmọ náà wà.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mama Beatrice mú kí n ronú lórí bí ọ̀ràn á ṣe rí lára Jóòbù nígbà tó gbọ́ ìròyìn gbogbo ohun burúkú tó dé bá a. A ṣàlàyé ìdí tí aráyé fi ń jìyà fún un, a sì jẹ́ kó dá a lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ ẹ́. (Jóòbù 34:10-12; Jákọ́bù 1:14, 15) A tún jẹ́ kó mọ àwọn àyípadà tí Ọlọ́run máa mú wá láìpẹ́ fún aráyé nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Bá a ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì sọ pé òun á máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó, òun á sì máa gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.

Gbogbo wa la gbádùn ọjọ́ yẹn, a sì mọ̀ pé Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àwọn èèyàn tá a wàásù fún mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, a sì fún wọn ní ìṣírí. Bí a ṣe ń fi àgọ́ náà sílẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ na àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a fún wọn sókè, wọ́n sì ń juwọ́ sí wa pé, ó dàbọ̀ o!

Bí a ṣe ń pa dà lọ sílé, à ń ronú lórí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà. Inú mi dùn gan-an nítorí ọjọ́ pàtàkì yìí. Mo rántí bí Papa Jacques ṣe mọrírì ohun tá a sọ fún un àti bí ìtura ṣe bá Mama Beatrice. Mo rántí bí màmá àgbàlagbà kan ṣe bọ̀ mí lọ́wọ́, tó sì di ọwọ́ mi mú, ó wá rẹ́rìn-ín músẹ́ láìsọ nǹkan kan. Mo ronú nípa àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n béèrè ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí wọn kéré. Ìwà rere àwọn èèyàn náà jọ mí lójú gan-an ni, àwọn tó jẹ́ pé ìyà tó jẹ wọ́n kì í ṣe kékeré, àmọ́ tí wọ́n ṣì ń rẹ́rìn-ín.

Níbi yìí, a rí ìsapá àtọkànwá tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe láti mú ìtura wá fún àwọn tí ìyà ń jẹ. Àmọ́ lóde òní, àǹfààní ló jẹ́ láti máa fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tó jẹ́ ojútùú sí gbogbo ìṣòro àwọn èèyàn. Inú mi dùn gan-an pé mo wà lára àwọn tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń mú ìtura bá wọn lọ́nà tí aráyé kò tíì rí irú rẹ̀ rí.