Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Ń Ṣàkóso Ayé Yìí?

Ta Ló Ń Ṣàkóso Ayé Yìí?

Ta Ló Ń Ṣàkóso Ayé Yìí?

Ó ṢEÉ ṢE kí o má tíì rí olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn kankan rí. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọn kò sí? Àwọn olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn mọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é tí èèyàn kò fi ní mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa darí ẹgbẹ́ wọn nígbà tí àwọn fúnra wọn wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Síbẹ̀, àwọn àkòrí díẹ̀ nínú ìwé ìròyìn tó sọ nípa bí ìjọba ṣe ń gbógun ti oògùn olóró, iṣẹ́ aṣẹ́wó àti títa àwọn èèyàn sí orílẹ̀-èdè míì láti fi wọ́n ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn wà, ó tún jẹ́ ká mọ ipa tí kò dáa tí wọ́n ń ní lórí àwọn èèyàn àti àbájáde iṣẹ́ ọwọ́ wọn tó burú jáì. Jàǹbá tí wọ́n ń ṣe fún èèyàn jẹ́ ká mọ̀ pé lóòtọ́, àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn.

Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé, Sátánì wà lóòótọ́, ó dà bí olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn tó lágbára, ó ń rí sí i pé kí àwọn èèyàn ṣe ìfẹ́ òun, ó ń lo “àwọn iṣẹ́ àmì . . . irọ́” àti “ẹ̀tàn àìṣòdodo.” Kódà, Bíbélì tiẹ̀ sọ pé, ó máa ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Tẹsalóníkà 2:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 11:14) A lè mọ̀ pé Èṣù wà lóòótọ́ nípasẹ̀ àwọn nǹkan tó ṣe. Síbẹ̀, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà pé áńgẹ́lì búburú kan wà téèyàn kò lè rí. Ká tó ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa Èṣù, ẹ jẹ́ ká sọ nípa díẹ̀ lára àwọn èrò àtàwọn ìgbàgbọ́ tí kò tọ̀nà tó mú kí ọ̀pọ̀ má gbà pé Èṣù wà lóòótọ́.

“Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kò lè dá Èṣù” Nítorí pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni rere àti ẹni pípé, ó jọ pé kò bọ́gbọ́n mu láti rò pé òun ló dá áńgẹ́lì kan tó jẹ́ ìkà, ẹni ibi àti ẹni burúkú. Òótọ́ kan ni pé, Bíbélì kò sọ pé Ọlọ́run dá irú ẹni bẹ́ẹ̀. Torí, ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run ni pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.”—Diutarónómì 32:4; Sáàmù 5:4.

Ohun tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò báyìí ni pé, bóyá ẹni pípé tí Ọlọ́run dá lè ṣe ohun tí kò dáa. Ọlọ́run kò ṣe àwọn ẹ̀dá rẹ̀ bí ẹ̀rọ, ó fún wọn ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Nítorí náà, ẹ̀dá pípé, tó jẹ́ olóye lè yàn láti ṣe nǹkan tó dáa tàbí èyí tí kò dáa. Ká sòótọ́, àwọn ẹ̀dá olóye, ìyẹn èèyàn tàbí áńgẹ́lì tí Ọlọ́run fún ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n nìkan ló lè ṣe ìpinnu lórí àwọn nǹkan.

Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀ ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n, kò ní dí wọn lọ́wọ́ pé kí wọ́n má ṣe hùwà ibi tó bá jẹ́ pé ohun tí wọ́n yàn láti ṣe nìyẹn. Jésù sọ pé, Èṣù ṣi òmìnira yẹn lò ni, ó ní: “Kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” (Jòhánù 8:44) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí i ní kedere pé, ẹni tó wá di Èṣù yìí ti fìgbà kan rí jẹ́ ẹni pípé, tó sì “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” * Ìdí tí Jèhófà Ọlọ́run fi fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀ ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n ni pé, ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì fọkàn tán wọn.—Wo àpótí náà,  “Ǹjẹ́ Ẹni Pípé Lè Di Aláìpé?” ní ojú ìwé 6.

“Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Èṣù” Èrò àwọn kan ni pé, ohun tí Bíbélì sọ nínú ìwé Jóòbù nípa Èṣù nìyẹn. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé, gbólóhùn náà pé, Èṣù ń lọ “káàkiri ní ilẹ̀ ayé” ń tọ́ka sí iṣẹ́ àwọn amí ilẹ̀ Páṣíà, tí wọ́n máa ń rìnrìn àjò tí wọ́n sì máa ń wá sọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún ọba wọn. (Jóòbù 1:7) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé, Ọlọ́run ló ran Èṣù láti lọ ṣe amí lóòótọ́, ṣé á tún ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣàlàyé fún Ọlọ́run pé, ibì kan ni òun ti ń bọ̀, ìyẹn pé òun ń lọ “káàkiri ní ilẹ̀ ayé”? Ìwé Jóòbù kò pe Èṣù ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ohun tó pè é ni Sátánì, tó túmọ̀ sí “Alátakò,” nítorí náà, èyí fi hàn pé Èṣù gan-an ni Olórí Elénìní Ọlọ́run. (Job 1:6) Ibo ni èrò náà pé, Èṣù jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti wá?

Láti ọgọ́rùn ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni làwọn ìwé àpókírífà, bíi “Book of Jubilees” àti ìwé “Common Rule” ti ẹ̀sìn Qumran, ti ń sọ pé Èṣù ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́, ó sì fi ara rẹ̀ sábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run. Òpìtàn tó ń jẹ́ J. B. Russell sọ nínú ìwé rẹ̀, Mephistopheles pé, Matin Luther tó jẹ́ Alátùn-únṣe Ẹ̀sìn sọ pé Èṣù jẹ́, irinṣẹ́ Ọlọ́run, “bí àdá kọdọrọ tàbí ọkọ́ tí Ọlọ́run fi ń ro oko rẹ̀.” Ọ̀gbẹ́ni Russell fi kún un pé, èyí túmọ̀ sí pé “ọkọ́ yìí fẹ́ràn láti máa ro àwọn èpò,” Ọlọ́run ló fi ọwọ́ agbára rẹ̀ dì í mú, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ẹ̀kọ́ Luther, tí ọ̀gbẹ́ni John Calvin tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn ọmọ ilẹ̀ Faransé tẹ́wọ́ gbà mú kí inú bí ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ nítorí pé wọ́n mọ ohun tó tọ́. Báwo ni Ọlọ́run ìfẹ́ ṣe máa fàyè gba ìwà ibi, tí á tún fẹ́ kí ìwà ibi máa ṣẹlẹ̀? (Jákọ́bù 1:13) Ẹ̀kọ́ yìí pa pọ̀ pẹ̀lú ìwà tó burú jáì tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún mú kí ọ̀pọ̀ má ṣe gbà gbọ́ pé Ọlọ́run àti Èṣù wà.

“Èrò ibi tó ń gbé inú èèyàn ni Èṣù” Tá a bá sọ pé, èrò ibi tó ń gbé inú èèyàn ni Èṣù, èyí kò ní jẹ́ kéèyàn ní òye tó kún nípa àwọn apá kan inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ìwé Jóòbù 2:3-6 ṣe sọ, ta ni Ọlọ́run ń bá sọ̀rọ̀? Ṣé èrò ibi tó ń gbé inú Jóòbù ni Ọlọ́run ń bá sọ̀rọ̀ ni àbí Ọlọ́run ń bá ara rẹ̀ sọ̀rọ̀ ni? Síwájú sí i, ǹjẹ́ Ọlọ́run lè máa yin Jóòbù nítorí ìwà tó dáa tó ní, lẹ́sẹ̀ kan náà, kó tún jẹ́ kí èrò ibi tó ń gbé inú Jóòbù dẹ ẹ́ wò lẹ́yìn náà? Tá a bá sọ pé Ọlọ́run lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ohun tá à ń sọ ni pé Ọlọ́run jẹ́ ẹlẹ́tàn, pé kì í ṣe “ẹni tí kò sí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀.” (Sáàmù 92:15) Ọlọ́run kọ́ ló ṣe Jóòbù ní jàǹbá. Èyí fi hàn pé, Èṣù kì í ṣe èrò ibi tó ń gbé inú èèyàn tàbí èrò ibi tó ń gbé inú Ọlọ́run, àmọ́ Èṣù jẹ́ ẹni gidi kan tó sọ ara rẹ̀ di Olórí Elénìní Ọlọ́run.

Ta Ló Ń Ṣàkóso Ayé Yìí?

Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé, kò bóde mu láti gbà pé Èṣù wà. Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹlòmíì tá a lè sọ pé ó wà nídìí ìwà ibi rírorò tó ń ṣẹlẹ̀ yìí bí kò ṣe Èṣù. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe kọ̀ láti gbà pé Èṣù wà ti mú kí wọ́n ṣàìgba Ọlọ́run pàápàá gbọ́, wọ́n sì ti pa àwọn ìlànà tó yẹ ní ìgbésí ayé tì.

Akéwì kan tó ń jẹ́ Charles-Pierre Baudelaire tiẹ̀ sọ ní nǹkan bí igba [200] ọdún sẹ́yìn pé: “Ọgbọ́n àrékérekè tí Èṣù máa ń lò jù lọ ni mímú káwa èèyàn gbà gbọ́ pé òun kò sí.” Bí Èṣù kò ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí òun jẹ́ yìí ti mú kí àwọn èèyàn máa ṣe iyè méjì nípa bóyá Ọlọ́run wà. Tí Èṣù kò bá sí, ṣé ìyẹn kò ní túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ló fa gbogbo ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí? Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí Èṣù ń fẹ́ kí àwọn èèyàn gbà gbọ́ náà nìyẹn?

Bíi ti àwọn olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn, Èṣù fara pa mọ́ kó bàa lè ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀. Kí lóhun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.”—2 Kọ́ríńtì 4:4.

Ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì ṣì wà nílẹ̀. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe fún ẹni àìrí tó ń pète gbogbo ìwà ibi àti ìjìyà tó ń ṣẹlẹ̀ yìí? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Láti lóye ìdí tí Ọlọ́run kò fi fòpin sí ọ̀tẹ̀ Èṣù lójú ẹsẹ̀, ka orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Ṣé ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Èṣù àbí alátakò rẹ̀?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

 Ǹjẹ́ Ẹni Pípé Lè Di Aláìpé?

Ìjẹ́pípé tí Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye ní ààlà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, Ẹlẹ́dàá dá Ádámù ní pípé, síbẹ̀ Ádámù ṣì ní láti mọ̀ pé ó lójú ohun tí òun lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, bí Ádámù bá ń jẹ ìdọ̀tí, òkúta tàbí igi, ó máa ṣe é léṣe. Ká ní ó kọ etí dídi sí òfin òòfà, tó sì wá lọ bẹ́ láti orí òkè gíga, ó dájú pé ńṣe ló máa kú tàbí kó fara pa yánnayànna.

Bákan náà, kò sí ẹ̀dá pípé náà, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí áńgẹ́lì tó lè kọjá ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tí kò ní rí àbájáde búburú tó máa gbẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀dá kan tó jẹ́ olóye bá ṣi òmìnira rẹ̀ lò, ńṣe ló máa ṣe ohun tí kò tọ́, tí á sì dẹ́ṣẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:29; Mátíù 4:4.