Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Ta ni Ahasuwérúsì Ọba Páṣíà tí ìwé Ẹ́sítérì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

Nínú Bíbélì, ìwé Ẹ́sítérì sọ pé Ahasuwérúsì Ọba fi omidan Ẹ́sítérì tó jẹ́ Júù ṣe ayaba rẹ̀, ayaba yìí sì wá gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan tó fẹ́ pa gbogbo ẹ̀yà Júù run. Ó ti pẹ́ tí àwọn èèyàn ti ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa èwo nínú àwọn ọba Páṣíà ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹni tí Bíbélì pè ní Ahasuwérúsì. Àmọ́ ṣá o, àkọsílẹ̀ èdè mẹ́ta kan tó wà lára àwọn ohun ìrántí kan tó jẹ́ ti ilẹ̀ Páṣíà jẹ́ ká mọ ẹni tí Ahasuwérúsì jẹ́ gan-an. Àwọn àkọsílẹ̀ náà jẹ́ kó ṣe kedere pé Sásítà Kìíní, ọmọ Dáríúsì Ńlá (ìyẹn Hisitápísì) ni Ahasuwérúsì yìí. Nígbà tí wọ́n fi èdè Hébérù ṣe àdàkọ orúkọ Sásítà tó wà nínú ohun ìrántí ti èdè Páṣíà yìí, wọ́n rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá orúkọ rẹ̀ tó wà nínú ìwé Ẹ́sítérì lédè Hébérù mu.

Gbogbo ohun tí ìwé Ẹ́sítérì sọ nípa Ahasuwérúsì ló bá ohun tí wọ́n ṣàwárí nípa rẹ̀ mu. Láti olú ìlú rẹ̀ ní Súsà (ìyẹn Ṣúṣánì), tó wà ní ilẹ̀ Élámù ni ọba Páṣíà yìí ti ń ṣàkóso ilẹ̀ Mídíà, ìjọba rẹ̀ sì gbilẹ̀ láti ilẹ̀ Íńdíà dé àwọn erékùṣù tó wà ní àgbègbè òkun Mẹditaréníà. (Ẹ́sítérì 1:2, 3; 8:9; 10:1) Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Lewis Bayles Paton sọ pé: “Sásítà nìkan ni gbogbo àlàyé yìí bá mu, kò bá àwọn ọba Páṣíà yòókù mu. Ohun tí ìwé Ẹ́sítérì sọ nípa ìwà Ahasuwérúsì sì bá ohun tí òpìtàn Hẹrodótù àti àwọn òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì míì sọ nípa Sásítà mu.”

Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé wọ́n ń ṣe bíríkì nílẹ̀ Íjíbítì láyé àtijọ́?

Ìwé Ẹ́kísódù sọ pé àwọn ará Íjíbítì ń kó àwọn ẹrú wọn tó jẹ́ Hébérù ṣe iṣẹ́ mímọ bíríkì. Àti pé àwọn ẹrú yẹn máa ń fi amọ̀ àti èérún pòròpórò ṣe àpòrọ́ tí wọ́n máa fi ṣe bíríkì náà, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe iye tí wọ́n yàn fún wọn pé kí wọ́n ṣe lójúmọ́.—Ẹ́kísódù 1:14; 5:10-14.

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, iṣẹ́ pàtàkì ni iṣẹ́ ṣíṣe bíríkì tí wọ́n ń sá sóòrùn jẹ́ fáwọn tó ń gbé ní àgbègbè Àfonífojì Náílì. Àwọn ohun ìrántí tí wọ́n fi irú bíríkì bẹ́ẹ̀ kọ́ sì wà nílẹ̀ Íjíbítì títí dòní. A rí bí wọ́n ṣe ń mọ bíríkì náà nínú àwòrán kan tó wà lára ògiri ibi tí wọ́n sin Rekhmire sí ní ìlú Tíbésì láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àsìkò kan náà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ìwé Ẹ́kísódù sọ wáyé.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan ṣàlàyé ohun tó wà nínú àwòrán yẹn pé: “Wọ́n á pọn omi wá látinú adágún omi kan; wọ́n á fi ọkọ́ po iyẹ̀pẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n á sì gbé e lọ síbi tí wọ́n ti máa fi yọ bíríkì. Wọ́n á wá da àpòrọ́ náà sínú àpótí tí wọ́n fi ń yọ bíríkì, ẹni tó ń ṣe bíríkì yẹn yóò sì jàn án mọ́lẹ̀. Wọ́n á wá yọ àpótí náà kúrò, kí bíríkì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe náà lè gbẹ nínú oòrùn. Wọ́n á ṣe bíríkì náà lọ rẹpẹtẹ, tó bá sì ti gbẹ, wọ́n á wá tò ó jọ títí dìgbà tí wọ́n máa lò ó. Títí dòní, bí wọ́n ṣe ń ṣe bíríkì nìyẹn lápá Ìlà Oòrùn.”—The International Standard Bible Encyclopedia.

Onírúurú àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé tí wọ́n fi òrépèté ṣe láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni tún sọ pé àwọn ẹrú máa ń ṣe bíríkì, wọ́n máa ń lo èérún pòròpórò àti amọ̀ tí wọ́n fi ń ṣe bíríkì, àti pé wọ́n máa ń sọ iye bíríkì tí àwọn òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ ṣe lójúmọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ère Sásítà (èyí tó dúró) àti ti Dáríúsì Ńlá (èyí tó jókòó) tí wọ́n gbẹ́ sára òkúta

[Credit Line]

Werner Forman/Art Resource, NY

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwòrán tó wà níbi tí wọ́n sin Rekhmire sí

[Credit Line]

Erich Lessing/Art Resource, NY