“Èmi Kì Yóò Gbàgbé Rẹ”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Èmi Kì Yóò Gbàgbé Rẹ”
ǸJẸ́ Jèhófà bìkítà nípa àwọn èèyàn rẹ̀ lóòótọ́? Tó bá jẹ́ pé ó bìkítà, báwo ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe jẹ ẹ́ lógún tó? Ọ̀nà kan ṣoṣo tí a fi lè mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yẹn ni pé ká wo ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ. Jèhófà sọ bí ìmọ̀lára rẹ̀ ṣe máa ń rí fún wa nínú Bíbélì. Wo ohun tó sọ nínú ìwé Aísáyà 49:15.
Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, Jèhófà lo ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe tó wọni lọ́kàn jù lọ láti fi jẹ́ ká mọ bí ìyọ́nú tí òun ní fún àwọn èèyàn òun ṣe jinlẹ̀ tó. Ó fi Ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀?” Téèyàn bá kọ́kọ́ ka ọ̀rọ̀ náà láì ronú jinlẹ̀ lórí rẹ̀, ọwọ́ kan lèèyàn máa dáhùn rẹ̀. Àbí, ṣé ó ṣeé gbọ́ sétí pé abiyamọ kan sọ pé òun gbàgbé láti fún ọmọ òun lóúnjẹ àti ìtọ́jú. Ó ṣe tán, ìkókó kò lè dá nǹkan kan ṣe; tọ̀sán-tòru ni ọmọ ọwọ́ ń fẹ́ ìtọ́jú àti ìfẹ́ ìyá rẹ̀, kíá ló sì máa figbe ta láti pàfiyèsí ìyá rẹ̀ tó bá ń fẹ́ nǹkan kan! Àmọ́ ìbéèrè tí Jèhófà béèrè ní ìtumọ̀ ju ìyẹn lọ.
Kí nìdí tí abiyamọ kan fi máa ń ṣìkẹ́ ọmọ rẹ̀ tó sì máa ń pèsè ohun tó bá ń fẹ́ fún un? Ṣé torí pé kí ọmọ náà má bàa sunkún ni? Rárá o. Ṣe ni abiyamọ sábà máa ń fi “ojú àánú” hàn sí “ọmọ ikùn rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “àánú,” tún lè túmọ̀ sí “fi àánú hàn.” (Ẹ́kísódù 33:19; Aísáyà 54:10) Ọ̀rọ̀ Hébérù yìí jẹ́ ká mọ ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ téèyàn máa ń ní fún ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́ tàbí ẹni tí kò lágbára kankan. Ìyọ́nú tí abiyamọ máa ń ní fún ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ìyọ́nú tó lágbára jù lọ láyé yìí.
Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé kì í ṣe gbogbo abiyamọ ló máa ń fojú àánú hàn sí ọmọ inú rẹ̀. Jèhófà sọ pé “Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé.” À ń gbé nínú ayé tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn kò ti ní “ìfẹ́ni àdánidá” mọ́. (2 Tímótì 3:1-5) Nígbà míì, a máa ń gbọ́ nípa àwọn abiyamọ tí ń pa ọmọ wọn jòjòló tì, tàbí pé wọ́n fìyà jẹ ẹ́ tàbí pé wọ́n já a jù sí ibì kan. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ nípa ohun tó wà nínú Aísáyà 49:15 pé: “Ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn abiyamọ, torí náà ìfẹ́ wọn máa ń kùnà nígbà míì bí wọn kò bá ro àròjinlẹ̀. Kódà, bó ṣe wù kí ìfẹ́ ẹ̀dá èèyàn jinlẹ̀ tó, ó lè kùnà nígbà míì.”
Síbẹ̀, Jèhófà fi dá wa lójú pé, “Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.” Ní báyìí, a ti wá rí ìdí tí Jèhófà fi béèrè ìbéèrè tó wà nínú Aísáyà 49:15 yẹn. Kì í ṣe pé Jèhófà kàn ń fi nǹkan wéra, àmọ́ ó ń fi ìyàtọ̀ tó wà hàn. Jèhófà kò dà bí àwọn abiyamọ tó jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, tí wọ́n lè gbàgbé láti fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ wọn jòjòló, ìyọ́nú tí Jèhófà ní fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ tó nílò ìrànlọ́wọ́ kò lè yẹ̀ láé. Abájọ tí ìwé tí a mẹ́nu kàn ní ìṣáájú yẹn fi sọ nípa Aísáyà 49:15 pé: “Èyí ni ọ̀kan lára gbólóhùn tó tẹ̀wọ̀n jù lọ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn bí gbólóhùn mìíràn bá tiẹ̀ wà tó tẹ̀wọ̀n tó o nínú Májẹ̀mú Láéláé.”
Ǹjẹ́ kò tù wá nínú láti mọ̀ “nípa ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Ọlọ́run wa”? (Lúùkù 1:78) Ìwọ náà ò ṣe kúkú kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè sún mọ́ Jèhófà? Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yìí fi dá àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lójú pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.
Bíbélì Kíkà Tá A Dábàá Fún February: