Òótọ́ Ni Ìtàn Inú Bíbélì Kì Í Ṣe Àlọ́
Òótọ́ Ni Ìtàn Inú Bíbélì Kì Í Ṣe Àlọ́
“Mo ti tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.”—LÚÙKÙ 1:3.
KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Ìtàn àlọ́ tàbí ìtàn àròsọ máa ń dùn gbọ́ àmọ́ kì í sábà ní orúkọ ibi pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, ọjọ́ pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ àti orúkọ àwọn èèyàn tó ti gbé ayé rí tó ṣẹlẹ̀ sí, téèyàn lè fi wádìí òótọ́ rẹ̀. Àmọ́ ti Bíbélì kò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì ní ọ̀kẹ́ àìmọye kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni tó jẹ́ kó lè dá àwọn tó bá kà á lójú pé “ọ̀rọ̀” inú rẹ̀ jẹ́ “òtítọ́.”—Sáàmù 119:160.
ÀPẸẸRẸ: Bíbélì sọ pé “Nebukadinésárì ọba Bábílónì . . . mú Jèhóákínì [ọba Júdà] lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.” Àti pé lẹ́yìn náà, “Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tí ó di ọba, gbé orí Jèhóákínì ọba Júdà sókè kúrò ní àtìmọ́lé.” Ó sì sọ pé “ohun tí a yọ̀ǹda ni a ń fi fún un [ìyẹn Jèhóákínì] nígbà gbogbo láti ọ̀dọ̀ ọba, lójoojúmọ́ bí ó ti yẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.”—2 Àwọn Ọba 24:11, 15; 25:27-30.
OHUN TÍ ÀWỌN AWALẸ̀PÌTÀN ṢÀWÁRÍ: Àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn ìwé kan tó jẹ mọ́ ti àbójútó ìlú lára àwọn àwókù ìlú Bábílónì ìgbàanì. Ìgbà ìṣàkóso Nebukadinésárì Ọba Kejì ni wọ́n sì ti kọ àwọn ìwé náà. Wọ́n kọ ìwọ̀n oúnjẹ tí wọ́n ń fún ẹlẹ́wọ̀n kọ̀ọ̀kan àti àwọn míì tó ń gba oúnjẹ ní àgbàlá ọba síbẹ̀. Nínú àkọsílẹ̀ yẹn ni a ti rí “Yaukin [ìyẹn Jèhóákínì],” tó jẹ́ “ọba ilẹ̀ Yahud (ìyẹn Júdà),” àti agbo ilé rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn awalẹ̀pìtàn tiẹ̀ sọ nǹkan kan nípa ẹni tó rọ́pò Nebukadinésárì, ìyẹn Efili-méródákì? Wọ́n rí àkọlé kan tó wà lára àwo òdòdó kan tí wọ́n rí lẹ́bàá ìlú Súsà, tó sọ pé: “Ààfin Amil-Marduk [ìyẹn Efili-méródákì], Ọba Bábílónì, ọmọ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì.”
KÍ LÈRÒ RẸ? Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìtàn, ǹjẹ́ ìwé ẹ̀sìn míì tún wà tí wọ́n ti kọ tipẹ́tipẹ́, tó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé bíi ti Bíbélì? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa bí àwọn nǹkan ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra àti àkókò tí wọ́n ṣẹlẹ̀ àti bí ojú ilẹ̀ ṣe rí láyé ìgbà yẹn, péye ó sì ṣeé gbára lé ju ti ìwé àtijọ́ èyíkéyìí míì lọ.”—A SCIENTIFIC INVESTIGATION OF THE OLD TESTAMENT, LÁTI ỌWỌ́ ROBERT D. WILSON
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìwé àwọn ará Bábílónì kan tó mẹ́nu kan Jèhóákínì ọba Júdà
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
© bpk, Berlin/Vorderasiatisches Museum, SMB/Olaf M. Tessmer/Art Resource, NY