Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Wà Ní Ipò Ọ̀wọ̀ àti Iyì Lójú Ọlọ́run

Wọ́n Wà Ní Ipò Ọ̀wọ̀ àti Iyì Lójú Ọlọ́run

NÍGBÀ tí Jésù wà ní ayé, ó fìwà jọ Baba rẹ̀ pátápátá nínú gbogbo nǹkan, títí kan ìṣe rẹ̀. Ó ní: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí . . . nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:28, 29; Kólósè 1:15) Torí náà, tí a bá wo irú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn obìnrin àti bó ṣe hùwà sí wọn, ìyẹn á jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin àti ohun tó fẹ́ kí wọ́n máa ṣe.

Ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé kan rí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere tó sọ̀rọ̀ nípa Jésù, mú kí wọ́n gbà pé ojú tí Jésù fi ń wo àwọn obìnrin yàtọ̀ pátápátá sí irú ojú tí àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn fi ń wò wọ́n. Báwo ló ṣe yàtọ̀? Ní pàtàkì, ǹjẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ni ń jẹ́ kí àwọn obìnrin lè ní òmìnira lóde òní?

Ọwọ́ Tí Jésù Fi Mú Àwọn Obìnrin

Jésù kò ka àwọn obìnrin sí àwọn tó kàn wà fún ìbálòpọ̀ lásán. Lójú àwọn aṣáájú ìsìn Júù kan, tí ọkùnrin àti obìnrin bá fara kanra lásán, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ló máa yọrí sí. Nítorí pé wọ́n ka àwọn obìnrin sí ẹni tó máa ń kóni sí àdánwò, wọn kì í jẹ́ kí wọ́n bá àwọn ọkùnrin sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kì í sì í jẹ́ kí wọ́n jáde lọ síta láìlo ìbòrí. Àmọ́ ní ti Jésù, ṣe ló fún àwọn ọkùnrin nímọ̀ràn pé ara wọn ni kí wọ́n máa kó níjàánu, kí wọ́n sì máa buyì kún àwọn obìnrin, dípò tí wọ́n á fi máa dá wọn yà sọ́tọ̀ láwùjọ.—Mátíù 5:28.

Jésù tún sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà lòdì sí i.” (Máàkù 10:11, 12) Jésù tipa báyìí fi hàn pé òun kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn rábì tó gbilẹ̀ láyé ìgbà yẹn, èyí tó fàyè gba àwọn ọkùnrin láti kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ “lórí onírúurú ìdí gbogbo.” (Mátíù 19:3, 9) Èrò pé ọkùnrin kan lè ṣe panṣágà lòdì sí aya rẹ̀ jẹ́ ohun tó ṣàjèjì sí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Júù. Ìdí ni pé ohun tí àwọn rábì, ìyẹn àwọn olùkọ́ wọn, fi kọ́ wọn ni pé ọkùnrin kò lè jẹ̀bi ẹ̀sùn panṣágà lòdì sí aya rẹ̀. Obìnrin nìkan ni wọ́n gbà pé ó lè jẹ̀bi ẹ̀sùn panṣágà! Ohun tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ ni pé, “bí Jésù ṣe fi hàn pé ìlànà ìwà híhù kan náà tó de aya ló de ọkọ rẹ̀, ṣe ló tipa bẹ́ẹ̀ buyì kún àwọn obìnrin tó sì fi wọ́n sípò iyì.”

Ipa tí ẹ̀kọ́ Jésù ní lórí àwọn èèyàn lóde òní: Nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣe ni àwọn obìnrin àti àwọn ọkùnrin jọ máa ń wà pa pọ̀ fàlàlà ní àwọn ìpàdé wa. Síbẹ̀, wọn kì í bẹ̀rù pé àwọn ọkùnrin á máa wò àwọn ní ìwòkuwò tàbí pé wọ́n á fi ìlọ̀kulọ̀ lọ àwọn, torí pé àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni máa ń rí i pé àwọn ń ṣe “àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.1 Tímótì 5:2.

Jésù rí i pé òun kọ́ àwọn obìnrin lẹ́kọ̀ọ́. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èrò àwọn rábì nípa obìnrin, èyí tó gbilẹ̀ nígbà yẹn, tó jẹ́ kí wọ́n máa fi àwọn obìnrin sípò àìmọ̀kan, ṣe ni Jésù ń kọ́ àwọn obìnrin tó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n sọ èrò ọkàn wọn. Nígbà kan, Jésù kò gbà kí Màríà kúrò nídìí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ tó sì ń dùn mọ́ ọn, ó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé kì í ṣe iṣẹ́ ilé nìkan ni obìnrin wà fún. (Lúùkù 10:38-42) Màtá tó jẹ́ arábìnrin Màríà pàápàá jàǹfààní nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù, èyí sì hàn kedere nínú ìdáhùn onílàákàyè tí ó fún Jésù nígbà tí Lásárù kú.—Jòhánù 11:21-27.

Jésù fi ojú pàtàkì wo ohun tí àwọn obìnrin rò nípa àwọn nǹkan. Nígbà ayé Jésù, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin Júù ló gbà pé ohun tó lè sọni di aláyọ̀ ni pé kéèyàn bí ọmọkùnrin tó ṣeé fi yangàn, bóyá tó tiẹ̀ jẹ́ wòlíì. Nígbà tí obìnrin kan fi ìtara sọ fún un pé: “Aláyọ̀ ni ilé ọlẹ̀ tí ó gbé ọ àti ọmú tí ìwọ mu!” Jésù lo àǹfààní yẹn láti fi jẹ́ kó mọ nǹkan míì tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ. (Lúùkù 11:27, 28) Ó fi hàn án pé ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù, ó wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó mọ nǹkan míì tó ju ohun tí àwọn èèyàn kà sí ojúṣe tí obìnrin gbọ́dọ̀ máa ṣe.—Jòhánù 8:32.

Ipa tí ẹ̀kọ́ Jésù ní lórí àwọn èèyàn lóde òní: Nínú ìjọ Kristẹni, àwọn olùkọ́ máa ń jẹ́ kí àwọn obìnrin lóhùn sí ọ̀rọ̀ nínú àwọn ìpàdé ìjọ. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà obìnrin fún jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ “olùkọ́ni ní ohun rere” nípasẹ̀ àpẹẹrẹ rere wọn ní gbangba àti níkọ̀kọ̀. (Títù 2:3) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún gbára lé wọn lẹ́nu iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn.—Sáàmù 68:11; wo àpótí náà  “Ṣé Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù Kà Á Léèwọ̀ fún Àwọn Obìnrin Láti Sọ̀rọ̀ Ni?” ní ojú ìwé 9.

Ire àwọn obìnrin jẹ Jésù lógún. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọmọkùnrin ni àwọn èèyàn máa ń kà sí pàtàkì, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ka ọmọbìnrin sí. Irú èrò yìí ni ìwé Támọ́dì gbé yọ, nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọkùnrin, ègbé ni fún ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ obìnrin.” Àwọn òbí míì ka ọmọbìnrin sí bùkátà ńlá, torí wọ́n ní láti bá a wá ọkọ, wọ́n á tún sanwó ìdána lórí rẹ̀, wọn kò sì tún ní lè gbára lé e fún ìtọ́jú nígbà tí wọ́n bá darúgbó.

Ṣùgbọ́n Jésù fi hàn pé bí ẹ̀mí ọmọkùnrin ti ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ náà ni ti ọmọbìnrin ṣe pàtàkì, torí bó ṣe jí ọmọkùnrin opó ará Náínì dìde náà ló jí ọmọbìnrin Jáírù dìde. (Máàkù 5:35, 41, 42; Lúùkù 7:11-15) Lẹ́yìn tí Jésù mú “obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìlera fún ọdún méjìdínlógún” lára dá, ó pè é ní “ọmọbìnrin Ábúráhámù,” èyí sì jẹ́ gbólóhùn kan tó ṣọ̀wọ́n nínú ìwé àwọn Júù. (Lúùkù 13:10-16) Èdè àpọ́nlé tí Jésù lò fún obìnrin yìí fi hàn pé, yàtọ̀ sí pé ó kà á sí ara àwọn èèyàn tó ṣe pàtàkì láwùjọ, ó tún gbà pé ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.—Lúùkù 19:9; Gálátíà 3:7.

Ipa tí ẹ̀kọ́ Jésù ní lórí àwọn èèyàn lóde òní: Òwe ilẹ̀ Éṣíà kan sọ pé: “Téèyàn bá ń tọ́ ọmọbìnrin, bí ìgbà téèyàn kàn ń bá ẹni ẹlẹ́ni bomi rin ọ̀gbà ni.” Àmọ́ àwọn bàbá onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni kì í jẹ́ kí irú èrò yìí nípa lórí àwọn, kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ọmọ wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni wọ́n máa ń tọ́jú dáadáa. Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń rí i dájú pé gbogbo ọmọ wọn gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó yẹ àti ìtọ́jú ara tó jíire.

Jésù fọkàn tán àwọn obìnrin. Ní ilé ẹjọ́ àwọn Júù, irú ojú tí wọ́n fi ń wo ẹ̀rí àwọn ẹrú ni wọ́n fi ń wo ẹ̀rí tí obìnrin bá jẹ́. Òpìtàn kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń jẹ́ Josephus sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba ẹ̀rí kankan láti ọ̀dọ̀ obìnrin gbọ́, nítorí pé obìnrin kì í ṣe ẹni tó ṣeé gbára lé.”

Ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí èyí ni Jésù ṣe ní tiẹ̀, torí àwọn obìnrin ló rán kí wọ́n lọ jẹ́rìí sí àjíǹde rẹ̀. (Mátíù 28:1, 8-10) Ojú àwọn obìnrin yìí ni wọ́n ti pa Jésù Olúwa wọn o, ìṣojú wọn ni wọ́n sì ti sìnkú rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ nígbà tí wọ́n wá ròyìn àjíǹde rẹ̀, àwọn àpọ́sítélì kò fẹ́ gbà wọ́n gbọ́. (Mátíù 27:55, 56, 61; Lúùkù 24:10, 11) Ṣùgbọ́n, bó ṣe jẹ́ pé àwọn obìnrin ni Kristi kọ́kọ́ fara hàn lẹ́yìn tó jíǹde, ó fi hàn pé Jésù gbà pé bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yòókù ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́rìí òun ni àwọn náà ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́rìí òun.—Ìṣe 1:8, 14.

Ipa tí ẹ̀kọ́ Jésù ní lórí àwọn èèyàn lóde òní: Nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ọkùnrin tó wà nípò àbójútó máa ń gba tí àwọn obìnrin rò ní ti pé wọn kì í kó ọ̀rọ̀ wọn dà nù. Àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni sì ‘máa ń fi ọlá’ fún aya wọn ní ti pé wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn.—1 Pétérù 3:7; Jẹ́nẹ́sísì 21:12.

Àwọn Ìlànà Bíbélì Máa Ń Mú Kí Àwọn Obìnrin Jẹ́ Aláyọ̀

Tí àwọn ọkùnrin bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, wọ́n máa ń fi ọ̀wọ̀ àwọn obìnrin wọ̀ wọ́n, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní òmìnira bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí wọ́n ní nípilẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Dípò kí àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni máa wò ó pé ìyàwó àwọn rẹlẹ̀ sí àwọn, ṣe ni wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn ìlànà Bíbélì darí àwọn, èyí sì máa ń mú kí ìyàwó wọn láyọ̀.—Éfésù 5:28, 29.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Yelena bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fojú rẹ̀ rí màbo lábẹ́lẹ̀. Ó ṣẹlẹ̀ pé ibi tí ìwà ipá ti wọ́pọ̀ gan-an ní wọ́n ti tọ́ ọkọ rẹ̀ dàgbà, àwọn ọkùnrin ibẹ̀ sì sábà máa ń jí ọmọbìnrin gbé láti fi ṣe aya, wọ́n sì tún máa ń hanni léèmọ̀ níbẹ̀. Yelena sọ pé: “Ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ni kò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Mo mọ̀ pé ẹnì kan wà tó fẹ́ràn mi gan-an, tí mo níyì lọ́wọ́ rẹ̀, tí ire mi sì jẹ lógún. Mo sì tún mọ̀ pé tí ọkọ mi bá lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwà tó ń hù sí mi lè yí pa dà.” Àdúrà obìnrin yìí gbà nígbà tí ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó wá ṣe ìrìbọmi tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yelena sọ pé: “Ọkọ mi di àpẹẹrẹ rere ní ti kéèyàn jẹ́ ẹni tó ń kó ara rẹ̀ níjàánu tó sì káwọ́ ara rẹ̀. A sì wá dẹni tó ń dárí ji ara wa fàlàlà.” Kí ló sọ pé ó ran òun lọ́wọ́? Ó ní: “Àwọn ìlànà Bíbélì ló jẹ́ kí n rí i pé mo jẹ́ ẹni tó wúlò, ó sì jẹ́ kí n ní ìbàlẹ̀ ọkàn lọ́dọ̀ ọkọ mi.”—Kólósè 3:13, 18, 19.

Yelena nìkan kọ́ ni irú àyípadà sí rere bẹ́ẹ̀ ti bá. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn obìnrin Kristẹni ló jẹ́ aláyọ̀ nítorí pé àwọn àti ọkọ wọn ń rí i pé àwọn ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú ìdílé wọn. Wọ́n máa ń rí ọ̀wọ̀, ìtùnú àti òmìnira bí wọ́n ṣe wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi ti wọn.—Jòhánù 13:34, 35.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé gbogbo àwọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló jẹ́ ẹ̀dá aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí náà àwọn wà lára ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tí ‘a tẹ̀ lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo.’ Àmọ́ bí wọ́n ṣe sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run àti Baba wọn onífẹ̀ẹ́, wọ́n ní ìrètí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn yóò di ẹni tí Ọlọ́run ‘dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,’ tí wọn yóò sì wá “ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Ìrètí àgbàyanu ni èyí mà jẹ́ o fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó wà lábẹ́ àbójútó Ọlọ́run!—Róòmù 8:20, 21.