Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Gbèjà Ẹ̀tọ́ Ẹni Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ̀ Kò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Gbèjà Ẹ̀tọ́ Ẹni Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ̀ Kò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun

ÀWỌN èèyàn mọ̀ dáadáa pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé kì í dá sí ọ̀ràn ìṣèlú àti ogun orílẹ̀-èdè èyíkéyìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ dájú ṣáká pé àwọn gbọ́dọ̀ “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀” àti pé àwọn “kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:4) Àmọ́, wọn kì í ṣèdíwọ́ fún ẹni tó bá wù láti ṣiṣẹ́ ológun. Tí ẹ̀rí ọkàn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ò bá gbà á láyè pé kó ṣe iṣẹ́ ológun, àmọ́ tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè tó wà kàn án nípá pé dandan ni kí àwọn èèyàn wọ iṣẹ́ ológun ńkọ́? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Vahan Bayatyan nìyẹn.

Ohun Tó Fa Ẹjọ́ ní Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù

Oṣù April ọdún 1983 ni wọ́n bí Vahan ní orílẹ̀-èdè Àméníà. Ní ọdún 1996, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun àti àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó ṣe ìrìbọmi. Ohun tí Vahan kọ́ nínú Bíbélì mú kó fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi, títí kan ìtọ́ni tó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ gbé ohun ìjà láti jagun. (Mátíù 26:52) Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé láìpẹ́ sígbà tí Vahan ṣèrìbọmi, ó di dandan kó ṣe ìpinnu kan tó gbẹgẹ́.

Òfin ilẹ̀ Àméníà sọ ọ́ di dandan fún gbogbo ọ̀dọ́kùnrin tó bá ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún láti wọ iṣẹ́ ológun. Tí wọ́n bá sì kọ̀ wọ́n lè sọ wọ́n sí ẹ̀wọ̀n tó máa gùn tó ọdún mẹ́ta. Kì í ṣe pé Vahan ò fẹ́ ṣiṣẹ́ sin àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀ o. Àmọ́ kò fẹ́ ṣe ohunkóhun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́. Kí ló wá ṣe?

Gbàrà tí Vahan ti tó ẹni tí ìjọba lè pè pé kó wá wọṣẹ́ ológun lọ́dún 2001 ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà sí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Àméníà. Ó sọ fún wọn nínú lẹ́tà rẹ̀ pé irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kóun ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn òun àti ohun tí òun gbà gbọ́. Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé òun ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ míì dípò iṣẹ́ ológun láti fi sin orílẹ̀-èdè òun.

Ó ju ọdún kan lọ tí Vahan fi ń kọ lẹ́tà láti bẹ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n gba ọ̀rọ̀ òun rò lórí pé ẹ̀rí ọkàn òun kò lè jẹ́ kí òun ṣe iṣẹ́ ológun. Àmọ́ ní September 2002, wọ́n mú Vahan. Wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé ó kọ̀ láti wá wọṣẹ́ ológun. Wọ́n wá rán an lẹ́wọ̀n ọdún kan ààbọ̀. Ṣùgbọ́n ìyà tí wọ́n fẹ́ fi jẹ ẹ́ yìí kò tíì tẹ́ agbẹjọ́rò ìjọba tó pe Vahan lẹ́jọ́ lọ́rùn. Torí náà, oṣù kan péré lẹ́yìn tí wọ́n ṣèdájọ́ náà, agbẹjọ́rò náà pẹjọ́ míì sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn pé ìyà tó le jù bẹ́ẹ̀ lọ ló yẹ kí wọ́n fi jẹ ẹ́. Ó ní bí Vahan ṣe kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológún torí pé ó lòdì sí ohun tó gbà gbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ “kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ó sì léwu.” Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sì fàṣẹ sí ohun tí agbẹjọ́rò náà béèrè, wọ́n wá sọ ìgbà tó máa lò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n di ọdún méjì ààbọ̀.

Vahan kò fara mọ́ ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí, torí náà ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Àméníà. Ṣùgbọ́n ní January 2003, ilé ẹjọ́ yìí náà sọ pé ẹjọ́ tó tọ́ ni àwọn ilé ẹjọ́ yòókù dá fún Vahan, pé kí wọ́n fìyà jẹ ẹ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì gbé Vahan láti ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n míì tí àwọn apààyàn, àwọn tó ń lo oògùn olóró àti àwọn afipá-báni-lòpọ̀ wà.

Bí Nǹkan Ṣe Lọ Ní Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù

Láti ọdún 2001 ni orílẹ̀-èdè Àméníà ti di ara Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù. Fún ìdí yìí, àwọn ọmọ ilẹ̀ náà lẹ́tọ̀ọ́ láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé ẹjọ́ wọn dé gbogbo ibi tó yẹ lórílẹ̀-èdè wọn síbẹ̀ tí ìdájọ́ tí wọ́n ṣe kò tẹ́ wọn lọ́rùn. Ohun tí Vahan sì ṣe nìyẹn. Ó sọ nínú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè pé bí wọ́n ṣe dá òun lẹ́jọ́ torí pé òun kò wọṣẹ́ ológun ta ko Abala Kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ó wá bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n lo ẹ̀tọ́ tí abala yìí sọ láti fi gbèjà òun kí wọ́n má bàa fi ẹ̀tọ́ òun láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn òun fẹ́ lórí ọ̀ràn wíwọ iṣẹ́ ológun du òun. Àmọ́ ṣá o, wọn ò tíì dá ẹnikẹ́ni láre lórí irú ẹjọ́ yìí rí.

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá ẹjọ́ yẹn ní October 27, ọdún 2009. Ilé ẹjọ́ náà lo òye tí wọ́n ní nípa irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ láti fi sọ pé, ẹ̀tọ́ tí ẹnì kan ní lábẹ́ Abala Kẹsàn-án láti kọ ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò kan àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun.

Nígbà tí wọ́n fi máa ṣe ìdájọ́ tá a wí yìí, Vahan ti parí àsìkò tó yẹ kó lò ní ẹ̀wọ̀n, ó ti gbéyàwó, ó sì ti bí ọmọkùnrin kékeré kan. Ìdájọ́ tí wọ́n ṣe yìí dùn ún gan-an. Ó wá ní láti pinnu bóyá kó jáwọ́ nínú ẹjọ́ náà tàbí kó ké gbàjarè lọ sọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù pé kí wọ́n bá òun tún ẹjọ́ náà gbọ́. Ló bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ yìí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹjọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nìkan ni ìgbìmọ̀ yìí máa ń gbọ́, inú Vahan dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbà láti tún ẹjọ́ rẹ̀ gbọ́.

Nígbà tó di July 7, 2011, Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ní ìlú Strasbourg lórílẹ̀-èdè Faransé ṣe ìdájọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nínú àwọn mẹ́tàdínlógún tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí, àwọn mẹ́rìndínlógún ló dá orílẹ̀-èdè Àméníà lẹ́bi pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ Vahan Bayatyan láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò fẹ́ dù ú nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi, tí wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà á láyè pé kó ṣe iṣẹ́ ológun. Adájọ́ kan ṣoṣo tó dá a lẹ́bi ni èyí tó wá láti orílẹ̀-èdè Àméníà.

Kí nìdí tí ìdájọ́ yìí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù máa dájọ́ pé lábẹ́ Abala Kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun kò fàyè gba pé kí òun ṣe iṣẹ́ ológun. Nítorí èyí, ilé ẹjọ́ yìí kà á sí fífi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn dunni tí wọ́n bá fi ẹnì kan sẹ́wọ̀n níbi tí ìjọba tiwa-n-tiwa bá ti ń ṣàkóso torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà á láyè láti wọ iṣẹ́ ológun.

Ohun kan wà tí Ilé Ẹjọ́ náà sọ tó dùn mọ́ni nípa bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe pinnu pé a kò ní ṣe iṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wa. Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé: “Nítorí náà, Ilé Ẹjọ́ yìí kò rí ìdí láti ṣiyè méjì pé ohun tó mú kí olùpẹ̀jọ́ náà pinnu pé òun kò fẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ológun jẹ́ tìtorí ohun tó gbà gbọ́, tó gbà tọkàntọkàn, tí kò fi ṣeré rárá, tí kò sì ṣe tán láti fi báni dọ́rẹ̀ẹ́ tó bá dọ̀ràn pé kó ṣe iṣẹ́ ológun.”

Àlàyé Lórí Ìdájọ́ Tí Ilé Ẹjọ́ Yìí Ṣe

Láàárín ogún ọdún sẹ́yìn báyìí, ó ti ju irínwó ó lé láàádọ́ta [450] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti dá lẹ́jọ́ ní orílẹ̀-èdè Àméníà torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ológún. Títí di ìgbà tí à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ọmọkùnrin méjìdínlọ́gọ́ta [58] ní orílẹ̀-èdè yẹn ni wọ́n wà lẹ́wọ̀n nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wọn àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ kò fàyè gbà wọ́n láti ṣe iṣẹ́ ológun. Márùn-ún nínú wọn ló jẹ́ pé ẹ̀yìn tí ilé ẹjọ́ ti ṣe ìdájọ́ mánigbàgbé lórí ẹjọ́ tó wáyé láàárín ọ̀gbẹ́ni Bayatyan àti orílẹ̀-èdè Àméníà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rán wọn lẹ́wọ̀n. * Kódà nígbà tí ẹjọ́ ọ̀kan nínú wọn ń lọ lọ́wọ́, ó kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí adájọ́ pé kí olùpẹ̀jọ́ ìjọba jọ̀wọ́ jáwọ́ nínú ẹjọ́ tó ń bá òun ṣe lórí pé òun kò ṣe iṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn òun, àmọ́ olùpẹ̀jọ́ náà kò gbà. Nígbà tí olùpẹ̀jọ́ náà máa fèsì, ó ní: “Ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe ní July 7, ọdún 2011, lórí ẹjọ́ tó wáyé láàárín ọ̀gbẹ́ni Bayatyan àti orílẹ̀-èdè Àméníà kò kan ẹjọ́ yìí rárá, torí ó hàn gbangba pé kò sí ohun tí ẹjọ́ méjèèjì fi jọra.”

Kí ló jẹ́ kí olùpẹ̀jọ́ náà ní irú èrò yìí? Nígbà tí wọ́n pe Vahan Bayatyan lẹ́jọ́ ní Àméníà, kò tíì sí ètò pé kí èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú dípò kéèyàn ṣe iṣẹ́ ológun. Ìyẹn ni ìjọba ilẹ̀ Àméníà fi wá sọ pé, níwọ̀n bí àwọn ti ṣe òfin kan tó fàyè gba pé kéèyàn ṣe iṣẹ́ sin ìlú lẹ́yìn ìgbà yẹn, ẹni tó bá lòdì sí ṣíṣe iṣẹ́ ológun lè yàn láti ṣe ìyẹn báyìí. Àmọ́ bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, abẹ́ àṣẹ àwọn ológun ni wọ́n ṣì fi ètò ṣíṣe iṣẹ́ sin ìlú náà sí, torí náà ètò yẹn kò yanjú ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí wọ́n ń pè báyìí pé kí wọ́n wá ṣe iṣẹ́ ológun ṣùgbọ́n tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣe é.

Inú Vahan Bayatyan dùn sí ìdájọ́ pàtàkì tí Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù fi dá a láre. Ìdájọ́ yìí fi hàn pé ó ti wá di ojúṣe fún orílẹ̀-èdè Àméníà láti jáwọ́ nínú fífi ìyà jẹ àwọn tí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tọkàntọkàn kò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ológun, kí wọ́n má sì máa rán wọn lẹ́wọ̀n mọ́.

Kì í ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá fẹ́ máa yí ètò òfin orílẹ̀-èdè èyíkéyìí pa dà o. Dípò bẹ́ẹ̀, bíi ti Vahan Bayatyan, ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n bá ní lábẹ́ òfin tó ti wà nílẹ̀ lórílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ń gbé. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n máa ń fẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín àwọn àti ọmọnìkejì wọn, kí wọ́n sì ráyè máa pa àṣẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Aṣáájú wọn mọ́ láìsí ìdíwọ́.

^ Ọjọ́ July 7, 2011 kan náà tí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá Vahan láre, ni ìjọba Àméníà ju méjì lára wọn sẹ́wọ̀n.