Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Ẹni Tó Bá Lóun Ní Ìgbàgbọ́ Kàn Ń Tan Ara Rẹ̀ Jẹ Ni?

Ṣé Ẹni Tó Bá Lóun Ní Ìgbàgbọ́ Kàn Ń Tan Ara Rẹ̀ Jẹ Ni?

Tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ní ìṣòro, wọn kì í fẹ́ ronú nípa rẹ̀ rárá, wọ́n máa ń fẹ́ sá fún ìṣòro wọn kí wọ́n má bàa yọ ara wọn lẹ́nu nípa bí wọ́n ṣe máa yanjú rẹ̀. Wọ́n á máa wá ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n á fi lè gbé e kúrò lọ́kàn lójú ẹsẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń mu ọtí láti fi pàrònú rẹ́. Tí wọ́n bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í mutí, ó lè dà bíi pé ó jẹ́ kí wọ́n ní ìgboyà, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n lè fara da ìṣòro wọn. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn tó máa ń fi ọtí pa ìrònú rẹ́ máa ń rí i pé ṣe ni wọ́n ń ṣàkóbá fún ara wọn. Ṣé bí ọ̀rọ̀ ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ náà ṣe rí nìyẹn?

Àwọn kan sọ pé òpònú ni ẹni tó bá sọ pé òun ní ìgbàgbọ́. Wọ́n ní àwọn tó bá gbójú lé ìgbàgbọ́ kì í fẹ́ ronú fúnra wọn, pé tí wọ́n bá tiẹ̀ rí ẹ̀rí mìíràn tó dájú ṣáká yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọn kì í yí èrò wọn pa dà. Lójú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ṣe ni àwọn tó ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ kàn ń dọ́gbọ́n sá fún ìṣòro wọn.

Lóòótọ́ o, Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé ká ní ìgbàgbọ́. Àmọ́, kò sọ pé ká kàn máa gba gbogbo nǹkan gbọ́ láìlo làákàyè. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò fàyè gba pé kí èèyàn má máa ronú jinlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló sọ pé àwọn tó bá kàn ṣáà ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́ jẹ́ aláìní ìrírí àti òmùgọ̀. (Òwe 14:15, 18) Ká sòótọ́, ìwà òmùgọ̀ gbáà ló máa jẹ́ láti kàn gba èrò ẹnì kan gbọ́ láìwádìí bóyá ó jẹ́ òótọ́! Ṣe ló máa dà bí ìgbà tí a fẹ́ sọdá títì márosẹ̀, tí a wá fi nǹkan bo ojú, torí ẹnì kan sọ pé ká ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣe ni Bíbélì sọ pé ká la ojú inú wa sílẹ̀ kedere, ká lo làákàyè wa, kí ẹnikẹ́ni má bàa tàn wá jẹ. Kò fẹ́ ká jẹ́ òpònú tó máa ń gba ọ̀rọ̀ gbọ́ láìronú. (Mátíù 16:6) Bí èèyàn ṣe ń la ojú inú rẹ̀ sílẹ̀ ni pé kó lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀. (Róòmù 12:1) Bíbélì kọ́ wa pé ká máa ronú dáadáa lórí ẹ̀rí tí a bá rí, kí a sì gbé ìpinnu wa ka ohun tó jẹ́ òtítọ́. Ẹ wo àwọn àpẹẹrẹ kan nínú àwọn ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ nínú Bíbélì.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Róòmù, kò fẹ́ kí wọ́n kàn gbà pé Ọlọ́run wà nítorí pé òun ti sọ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Ṣe ló gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ronú lórí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà lóòótọ́. Ó ní: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn [ìyẹn àwọn tí kò tẹrí ba fún Ọlọ́run] kò ní àwíjàre.” (Róòmù 1:20) Irú àlàyé tó ṣe sínú ìwé tó kọ sí àwọn Hébérù náà nìyẹn. Ó ní: “Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Tẹsalóníkà, ó sọ fún wọn pé kì í ṣe gbogbo nǹkan ló yẹ kí wọ́n máa gbà gbọ́. Ó fẹ́ kí wọ́n “máa wádìí ohun gbogbo dájú.”—1 Tẹsalóníkà 5:21.

Téèyàn bá lóun ní ìgbàgbọ́ láìrí ẹ̀rí tó dáni lójú, bí ẹni tó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, èyí sì lè múni ṣìnà tàbí kó ṣàkóbá fúnni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn onísìn kan tó wà nígbà ayé rẹ̀, ó ní: “Mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún ìjọ tó wà ní Róòmù. Ó sọ pé: “Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Tí ìgbàgbọ́ wa bá dá lórí ìmọ̀ pípéye tí a ní nípa Ọlọ́run, a jẹ́ pé kì í ṣe pé à ń tan ara wa jẹ. Ṣe ni ìgbàgbọ́ wa máa dà bí “apata ńlá” tó ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ohun tó lè máa kó wa lọ́kàn sókè tàbí ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́.—Éfésù 6:16.