Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Rán Jésù Wá Sí Ayé?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.
1. Ibo ni Jésù wà kí Ọlọ́run tó rán an wá sí ayé?
Jésù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó ń gbé ní ọ̀run kí wọ́n tó wá bí i sí ayé ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Òun ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, òun nìkan sì ni Ọlọ́run fọwọ́ ara rẹ̀ dá ní tààràtà. Torí náà, ó bá a mu láti pè é ní Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí Ọlọ́run ní. Ní ọ̀run, òun ló sábà máa ń gba ọ̀rọ̀ sọ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pè é ní Ọ̀rọ̀ náà. Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún Ọlọ́run, ó kópa nínú iṣẹ́ dídá àwọn ohun mìíràn. (Jòhánù 1:2, 3, 14) Jésù ti wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ọ̀run fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún kí Ọlọ́run tó dá ènìyàn.—Ka Míkà 5:2; Jòhánù 17:5.
2. Báwo ni Ọlọ́run ṣe rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé?
Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ láti fi mú ẹ̀mí Jésù láti ọ̀run wá sínú ilé ọlẹ̀ Màríà. Bí Màríà ṣe bí Jésù nìyẹn láìjẹ́ pé ọkùnrin kankan fún un lóyún. Nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn áńgẹ́lì kéde fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà níta lóru nínú pápá tí wọ́n ti ń ṣọ́ agbo ẹran wọn pé wọ́n ti bí Kristi. (Lúùkù 2:8-12) Nítorí náà, kì í ṣe ìgbà òtútù tí yìnyín bolẹ̀ ni wọ́n bí Jésù. Ó ní láti jẹ́ pé apá ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October, tí ojú ọjọ́ ṣì móoru ni wọ́n bí i. Nígbà tó yá, Màríà àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ gbé Jésù lọ sí ilé wọn ní Násárétì, ibẹ̀ ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Jósẹ́fù tọ́jú Jésù bí ọmọ rẹ̀ tó gbà tọ́.—Ka Mátíù 1:18-23.
Nígbà tí Jésù tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún ó ṣèrìbọmi, Ọlọ́run sì kéde pé Ọmọ òun ni Jésù. Jésù wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an wá ṣe láyé.—Ka Mátíù 3:16, 17.
3. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rán Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé?
Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé kó wá kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́. Jésù kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba kan ní ọ̀run tó máa mú kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí aráyé ní ìrètí pé àwọn lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 4:14; 18:36, 37) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù tún kọ́ àwọn èèyàn nípa bí wọ́n ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀. (Mátíù 5:3; 6:19-21) Ó fi ohun tó kọ́ni ṣèwà hù kí àwọn èèyàn lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó mú kí àwọn èèyàn rí bí wọ́n ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kódà nígbà ìṣòro. Nígbà tí wọ́n ṣe àìdáa sí i, kò gbẹ̀san.—Ka 1 Pétérù 2:21-24.
Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní bí wọ́n ṣe lè ní ìfẹ́ tó lè mú kéèyàn fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn míì. Ipò àrà ọ̀tọ̀ ni Jésù wà nígbà tó wà lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ lọ́run, síbẹ̀ ó fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣègbọràn sí Baba rẹ̀, ó wá sí ayé láti gbé láàárín àwa èèyàn. Kò sí ẹni tó lè fi ìfẹ́ hàn bíi ti Jésù. Àpẹẹrẹ ìfẹ́ tirẹ̀ ló ta yọ.—Ka Jòhánù 15:12, 13; Fílípì 2:5-8.
4. Nǹkan ribiribi wo ni ikú Jésù ṣe fún wa?
Bákan náà, Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé kó lè kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Jòhánù 3:16) Gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ìyẹn ni pé a jẹ́ aláìpé, a sì máa ń dẹ́sẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a fi ń ṣàìsàn tí a sì ń kú. Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ yàtọ̀ pátápátá sí wa ní tiẹ̀, ẹ̀dá pípé ni. Kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀, torí náà, kì bá má ṣàìsàn rárá, ì bá sì máa gbé ayé títí láé láìkú. Àmọ́, ó pàdánù ipò pípé tó wà nígbà tó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. A wá jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, ikú ni ẹ̀ṣẹ̀ sì máa ń yọrí sí.—Ka Róòmù 5:12; 6:23.
Ẹni pípé ni Jésù, torí náà kì í ṣe torí pé ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ló ṣe kú. Tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa ló ṣe kú. Ikú Jésù ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ìrètí pé a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, òun ló sì jẹ́ ká lè rí ojú rere Ọlọ́run.—Ka 1 Pétérù 3:18.