Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Owó?

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Owó?

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Estelle * àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèje kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ. Ó ní: “Mo sọ fún àlùfáà wa pé mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì.” Àmọ́ àlùfáà náà ò tiẹ̀ sọ pé òun máa kọ́ ọ rárá. Nígbà tó yá, obìnrin yìí pa ṣọ́ọ̀ṣì tì. Ó sọ pé: “Àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì kọ lẹ́tà sí mi, wọ́n sì dìídì sọ pé tí mi ò bá lè wá sí ṣọ́ọ̀ṣì, kí n ṣáà ti máa fowó ránṣẹ́. Ìyẹn ló jẹ́ kí n wá rí i pé, ‘gbogbo bí mo ṣe máa ń wá ò tiẹ̀ jẹ́ nǹkan kan lójú wọn, owó mi ni wọ́n ń fẹ́.’”

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Angelina kì í fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá. Ó sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń gbé igbá ọrẹ kiri nínú ṣọ́ọ̀ṣì wa nígbà tí a bá ń ṣe ìsìn lọ́wọ́, wọ́n sì retí pé ká fowó sínú rẹ̀ ní ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Owó ni wọ́n máa ń béèrè ní gbogbo ìgbà. Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Wọn kò ní ẹ̀mí Ọlọ́run rárá.’”

Ǹjẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn tó wà ládùúgbò rẹ máa ń béèrè owó ní tààràtà, àbí ṣe ni wọ́n ń fi oríṣiríṣi ọgbọ́n gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn? Ǹjẹ́ èyí bá Bíbélì mu?

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

Jésù tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀, sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì kò ṣeé fowó rà, torí náà gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí i ló yẹ kó rí i gbà lọ́fẹ̀ẹ́.

Báwo ni àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ń rí owó tí ìjọ máa ná?

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló máa ń ṣètìlẹyìn “gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Pẹ̀lú ṣíṣiṣẹ́ ní òru àti ọ̀sán ni a fi wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín, kí a má bàa gbé ẹrù ìnira tí ń wọni lọ́rùn lé ẹnikẹ́ni nínú yín lórí.” (1 Tẹsalóníkà 2:9) Pọ́ọ̀lù máa ń bá àwọn èèyàn pa àgọ́ kó lè fi owó tó bá rí nídìí iṣẹ́ yìí gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.—Ìṣe 18:2, 3.

ṢÉ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ìjọsìn wọn nínú àwọn ilé tó mọ níwọ̀n. Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n máa ń pe àwọn ilé yìí. Báwo ni wọ́n ṣe ń rí owó tí wọ́n ń ná? Wọn kì í gbé igbá ọrẹ kiri tàbí kí wọ́n máa pín àpò ìwé kiri láti fi tọrọ owó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá mọrírì ohun tó gbọ́ ní àwọn ìpàdé wọn lè fi ohun tó bá fẹ́ sínú àpótí ọrẹ tó máa ń wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn.

Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ẹlẹ́sìn máa rí owó tí wọ́n ń ná?

Owó kékeré kọ́ ló ń ná wọn láti tẹ ìwé ọwọ́ rẹ yìí, kí wọ́n sì tún kó o ránṣẹ́. Síbẹ̀, o kò lè rí i kí wọ́n máa fi àwọn ìwé náà ṣe ìpolówó ọjà tàbí kí wọ́n máa tọrọ owó kiri. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, wọ́n fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn.

Kí lo rò? Ǹjẹ́ ọ̀nà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń bójú tó ìnáwó bá ohun tí Jésù sọ mu? Ṣé ó sì bá ohun tí àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni ṣe mu?

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí.