Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ IKÚ NI ÒPIN ÌGBÉSÍ AYÉ Ẹ̀DÁ?

Oró Ikú

Oró Ikú

Ọ̀rọ̀ nípa ikú kì í dùn ún sọ. Kì í tiẹ̀ wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rárá. Àmọ́, òtítọ́ kan tó korò ni pé, bó pẹ́, bó yá ikú lè kàn wá tàbí àwọn tó sún mọ́ wa. Ìbànújẹ́ tí ikú máa ń fà kì í lọ bọ̀rọ̀, oró ikú sì máa ń dunni wọnú eegun.

Kò sí béèyàn ṣe lè ṣeé tí ikú òbí ẹni tàbí ọkọ tàbí aya tàbí ti ọmọ kò fi ní dunni. Àjálù yìí lè dé láìròtẹ́lẹ̀ tàbí kó ṣẹlẹ̀ léraléra. Èyí ó wù kó jẹ́, oró tí ikú máa ń dá kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, ọgbẹ́ tó máa ń dá síni lọ́kàn kọjá àfẹnusọ, ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ kì í sì í lọ bọ̀rọ̀. Ẹni tó bá kàn ló mọ̀.

Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Antonio, tí bàbá rẹ̀ kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀, ṣàpèjúwe bó ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ilé tí ẹnì kan ń gbé, tí wọ́n sì tì í pa. Ibẹ̀ ò ṣeé wọ̀ mọ́. Ohun tó kù tí ẹni náà á kàn máa rántí ò ju àwọn àkókò tó fi gbádùn ilé náà lọ. Bó ṣe máa ń rí nìyẹn lára ẹni tí èèyàn rẹ̀ kú. Torí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ kò dùn mọ́ ọn nínú, á máa sapá láti gbé e kúrò lọ́kàn. Àmọ́ nígbà tó bá ṣe kedere sí i pé ẹni náà kò sí mọ́, á wá rí i pé kò sí nǹkan tí òun lè ṣe sí i.”

Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára obìnrin kan tó ń jẹ́ Dorothy náà nìyẹn. Olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ni obìnrin yìí, ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] ni nígbà tó di opó, kò sì gbà pé ikú lòpin ìgbésí ayé ẹ̀dá. Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kò yé òun fúnra rẹ̀, ló bá béèrè lọ́wọ́ àlùfáà ìjọ Áńgílíkà tó ń lọ pé: “Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?” Àlùfáà náà dá a lóhùn pé: “Kò sẹ́ni tó mọ̀, torí àdììtú ni, Ọlọ́run nìkan ló sì yé.”

Ṣé “àdììtú” lọ̀rọ̀ yìí lóòótọ́. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan tiẹ̀ wà tá a lè fi mọ̀ lóòótọ́ bóyá ikú lòpin ìgbésí ayé ẹ̀dá?