ÀWỌN ÒǸKÀWÉ WA BÉÈRÈ PÉ . . .
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìnilára?
Bíbélì fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ nípa bí àwọn alágbára ṣe ń fi ojú àwọn tí kò ní olùgbèjà gbolẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìtàn Nábótì wá sí ọ lọ́kàn. * Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù, Ọba Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Áhábù fàyè gba Jésíbẹ́lì ìyàwó rẹ̀ láti pa ọkùnrin tó ń jẹ́ Nábótì àtàwọn ọmọ rẹ̀ torí kí ó lè gba ọgbà àjàrà rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 21:1-16; 2 Àwọn Ọba 9:26) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àṣìlò agbára tó pọ̀ lápọ̀jù bẹ́ẹ̀?
“Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.”—Títù 1:2
Ẹ jẹ́ ká wo ìdí pàtàkì kan tó fi rí bẹ́ẹ̀: Ọlọ́run kò lè purọ́. (Títù 1:2) Àmọ́ kí ni ìyẹn ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù? Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọlọ́run ti kìlọ̀ pé tí àwa èèyàn bá ṣàìgbọràn sí òun, àbájáde rẹ̀ kò ní dáa rárá, ikú ló sì máa yọrí sí. Òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ yìí já sí, torí pé láti ìgbà táwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti ṣọ̀tẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ni ikú tí ń pọ́n aráyé lójú. Kódà, ìwà ìkà ló fa ikú ẹ̀dá èèyàn tó kọ́kọ́ kú, ìyẹn nìgbà tí Kéènì pa Ébẹ́lì, àbúrò rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 4:8.
Látìgbà náà ni ìwà ìkà ti ń gbilẹ̀, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ǹjẹ́ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn lóòótọ́? Jèhófà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé àwọn tó máa jọba lé wọn lórí yóò ni wọ́n lára débi pé wọ́n á ké jáde sí òun. (1 Sámúẹ́lì 8:11-18) Kódà, Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba pàápàá fi owó orí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára. (1 Àwọn Ọba 11:43; 12:3, 4) Àwọn ọba burúkú míì bí Áhábù ni àwọn aráàlú lára dé góńgó. Rò ó wò náà, tí Ọlọ́run kò bá fàyè gba irú àwọn ìwà ìjẹgàba bẹ́ẹ̀, ṣé kò ní sọ ara rẹ̀ di òpùrọ́?
“Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9
Má gbàgbé ohun tí Sátánì sọ pé, nítorí àwọn ohun tí à ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín. (Jóòbù 1:9, 10; 2:4) Ká ní Ọlọ́run ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ onírúurú ìwà ìnilára ni, ńṣe ni ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ ì bá já sí òótọ́. Tó bá sì jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run ń dáàbò bo gbogbo èèyàn kúrò lọ́wọ́ onírúurú ìnilára, ṣé ìyẹn ò ní sọ Ọlọ́run di òpùrọ́? Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ńṣe ni àwọn èèyàn á máa rò pé, àwọn lè ṣàkóso ara àwọn láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ìyẹn kò lè ṣeé ṣe, torí pé, èèyàn ò tóótun láti ṣàkóso ara rẹ̀ rárá. (Jeremáyà 10:23) A nílò Ìjọba Ọlọ́run gan-an, torí ìgbà tó bá dé nìkan la tó máa bọ́ lọ́wọ́ ìnilára.
Ṣé ohun tí a wá ń sọ ni pé Ọlọ́run kò rí nǹkan kan ṣe sí ìwà ìnilára tí àwọn èèyàn ń hù lónìí? Rárá o. Jẹ́ ká wo ohun méjì tí Ọlọ́run máa ń ṣe. Àkọ́kọ́, gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa rẹ̀ pátá ló sọ fún wa. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo bí Jésíbẹ́lì ṣe gbìmọ̀ ìkà, tó sì pa Nábótì ni Bíbélì ṣàlàyé. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé, alágbára kan ló wà lẹ́yìn gbogbo ìwà burúkú yìí, àti pé kò fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ẹni tí òun jẹ́. (Jòhánù 14:30; 2 Kọ́ríńtì 11:14) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì Èṣù ni ọ̀daràn yìí. Bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká mọ ẹni tó wà nídìí gbogbo ìwà ìkà àti ìnilára ti jẹ́ ká lè yàgò fún àwọn ìwà burúkú. Nípa bẹ́ẹ̀, ìrètí tá a ní fún ọjọ́ iwájú kò ní ṣá.
Ìkejì ni pé, Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà ìkà máa dópin. Ìlérí tó ṣe pé òun á pa àwọn ẹni ibi run láìpẹ́ dá wa lójú torí pé ó tú àṣírí Áhábù, Jésíbẹ́lì àti àwọn ẹni ibi míì, ó dá wọn lẹ́jọ́, ó sì tún fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n. (Sáàmù 52:1-5) Bákan náà, Ọlọ́run fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní ìrètí tó ṣeé gbára lé pé láìpẹ́, gbogbo ohun tí ìwà ibi àti ìwà ìnilára ti fà ni òun máa mú kúrò pátápátá. * Tó bá dìgbà yẹn, ọkùnrin olóòótọ́ náà, Nábótì àtàwọn ọmọ rẹ̀ máa láǹfààní láti gbé nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé níbi tí ìdájọ́ òdodo ti máa gbilẹ̀ títí láé.—Sáàmù 37:34.
^ ìpínrọ̀ 3 Wo àpilẹ̀kọ náà “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” nínú ìwé yìí.
^ ìpínrọ̀ 8 Wo orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.