BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Bíbélì Ni Wọ́n Fi Dáhùn Gbogbo Ìbéèrè Mi!
ṢE SỌ Ọ́ ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1950
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: SÍPÉÈNÌ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MỌDÁ NÍNÚ ṢỌ́Ọ̀ṢÌ KÁTÓLÍÌKÌ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Inú oko kékeré lábúlé kan tó wà nílùú Galicia, lápá ìwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè Sípéènì ni àwọn òbí mi ti tọ́ mi dàgbà. Èmi ni mo ṣìkẹrin nínú ọmọ mẹ́jọ tí àwọn òbí mi bí. A láyọ̀ gan-an nínú ìdílé wa. Nígbà yẹn, ohun tó wọ́pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì ni kí ẹnì kan nínú ìdílé lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà. Àmọ́ nínú ìdílé wa, àwa mẹ́ta la lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yẹn.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13], mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà tí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin wà nílùú Madrid. Wọ́n ti le koko mọ́ wa jù níbẹ̀. Kò sí àyè fún wa láti ní ọ̀rẹ́ kankan, gbogbo ohun tá a máa ń ṣe ò ju pé ká ṣáà gbàdúrà, ká máa tẹ̀ lé òfin, ká sì máa fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wa nítorí pé a fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run. Láàárọ̀ kùtùkùtù, a máa péjọ sínú ṣọ́ọ̀ṣì ká lè ṣàṣàrò, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà èmi ò kì í rí nǹkan kan rò ní tèmi. Tó bá yá, àá fi èdè Látìn ṣe ààtò Máàsì, ìyẹn Gbígba Ara Olúwa, a ó sì tún fi èdè náà kọ àwọn orin ìsìn. Gbogbo ohun tá à ń ṣe kò yé mi rárá, ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé mi ò sún mọ́ Ọlọ́run rárá. Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú péré ni wọ́n máa ń fún wa láti fi bá ara wa sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí a bá jẹun tán. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni mi ò kì í bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀. Kódà, tí mo bá pàdé ẹ̀gbọ́n mi, ohun tí a máa ń sọ kò ju, “Ẹ yin Màríà mímọ́ jùlọ.” Gbogbo èyí máa ń mú kí àárò ilé sọ mí lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo sì máa ń sunkún torí pé mo dá wà, láìsí alábàárò kankan.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], mo jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di mọdá, ìyẹn àwọn tí kì í lọ́kọ nítorí iṣẹ́ Ọlọ́run. Mo kàn ń ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ kí n ṣe ni torí kì í ṣe mí bíi pé mo sún mọ́ Ọlọ́run rárá. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì bóyá lóòótọ́ ni Ọlọ́run pè mí fún iṣẹ́ yìí. Àwọn mọdá yòókù máa ń sọ pé, inú iná ọ̀run àpáàdì ni àwọn tó bá ń ṣiyè méjì bíi tèmi ń lọ! Síbẹ̀, èrò yẹn ò kúrò lọ́kàn mi. Mo mọ̀ pé Jésù ò dúró sí ibi kan, ṣùgbọ́n ńṣe ló ń lọ káàkiri kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kó sì kọ́ wọn nípa Ọlọ́run. (Mátíù 4:23-25) Nígbà tí mo pé ọmọ ogún [20] ọdún, iṣẹ́ mọdá ti wá sú mi pátápátá. Ni olórí àwọn mọdá bá sọ fún mi pé kí n tètè kó ẹrù mi tí mo bá mọ̀ pé iṣẹ́ náà ti sú mi. Mo fura pé kí n má bàa kó tèmi ran àwọn tó kù ló ṣe ní kí n máa lọ. Nítorí náà, mo kó ẹrù mi, mo sì pa dà sílé.
Nígbà tí mo pa dà sílé, àwọn òbí mí ò bínú sí mi jù torí pé ọ̀rọ̀ mi yé wọn. Àmọ́ torí pé kò sí iṣẹ́ kankan lábúlé wa, mo lọ sí orílẹ̀-èdè Jámánì níbi tí àbúrò mi ọkùnrin ń gbé. Àbúrò mi wà lára ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì tó ń gbé ní ilẹ̀ òkèèrè dá sílẹ̀. Ó wù mí láti wà pẹ̀lú àwọn tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn òṣìṣẹ́, tó sì ń ta ko bí wọ́n ṣe ń fojú kéré àwọn obìnrin. Bí èmi náà ṣe di ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì nìyẹn, tí mo sì fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà. Bí a ṣe ń wọ́de kiri, tí a sì ń pín àwọn ìwé Kọ́múníìsì fún àwọn èèyàn máa ń jẹ́ kí n rò pé ohun tó ní láárí ni mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe.
Àmọ́ kò pẹ́ tí àwọn nǹkan tí mo rí fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ mí lóminú. Mo rí i pé ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ń kọ́ àwọn èèyàn yàtọ̀ sí ohun tí àwọn fúnra wọn ń hù níwà. Èyí tó tiẹ̀ bí mi nínú jù ni pé lọ́dún 1971, àwọn kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà dáná sun Ilé Aṣojú Ìjọba Ilẹ̀ Sípéènì tó wà ní ìlú Frankfurt. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn nítorí ìwà ìrẹ́jẹ tí ìjọba apàṣẹwàá ti orílẹ̀-èdè Sípéènì ń hù, síbẹ̀ mi ò gbà pé ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nìyẹn.
Nígbà tí mo bí àkọ́bí mi, mo sọ fún ọkọ mi pé mi ò ní lọ sí ìpàdé ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì mọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń dá wà torí pé gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ti pa èmi àti ọmọ mi tì, wọn ò tiẹ̀ ṣe bí ẹni pé àwọn mọ̀ wá rárá. Èyí ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tí a wá ṣe láyé gan-an. Àti pé, ṣé èrè kankan tiẹ̀ wà nínú kí èèyàn fẹ́ tún ayé ṣe?
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Ní ọdún 1976, tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orílẹ̀-èdè Sípéènì wá sọ́dọ̀ mi, mo sì gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n fún mi. Nígbà tí wọ́n pa dà wá, mo bi wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìyà tó ń jẹ wá àti nípa ìdí tí àwọn kan fi lówó tí àwọn míì sì jẹ́ òtòṣì. Mo tún béèrè pé kí ló dé tí àwọn kan fi ń rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ. Ó yà mí lẹ́nu pé, Bíbélì ni wọ́n fi dáhùn gbogbo ìbéèrè mi! Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe máa ń sọ ojú abẹ níkòó ló máa ń gbádùn mọ́ mi, kì í ṣe nítorí pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, nǹkan yí pa dà nígbà tí èmi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ní ilé ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo ti bí ọmọ kejì nígbà yẹn. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí ló máa wá gbé wa nílé, wọ́n á tún bá wa tọ́jú àwọn ọmọ wa nígbà tí ìpàdé náà bá ń lọ lọ́wọ́. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí mú kí n nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.
Síbẹ̀, mò ṣì ń ṣiyè méjì nípa ẹ̀sìn. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn tí mo pa dà sí orílẹ̀-èdè Sípéènì láti lọ wo àwọn òbí mi. Àbúrò bàbá mi tó jẹ́ àlùfáà sapá gan-an kí n lè jáwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ mi, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Àwọn náà fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè mi báwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Jámánì ti ṣe. Mo wá pinnu láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi lọ tí mo bá ti pa dà sí Jámánì. Ọkọ mi sọ pé òun ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, ṣùgbọ́n mo sapá láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi nìṣó. Lọ́dún 1978, mo ṣèrìbọmi, èmi náà sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Bí mo ṣe lóye òtítọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n fi ayé mi ṣe, ó tún jẹ́ kí ìgbésí ayé mi dáa. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì, ìwé 1 Pétérù 3:1-4 sọ pé kí àwọn aya máa “wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ” wọn “pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” àti “ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.” Àwọn ìlànà yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ilé àti ìyá rere fún àwọn ọmọ mi.
Ó ti lé ní ọdún márùndínlógójì [35] báyìí tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo láyọ̀ pé mo wà lára àwọn èèyàn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kárí ayé. Inú mi sì dùn pé mẹ́rin nínú àwọn ọmọ márùn-ùn tí mo bí ló ń sin Jèhófà báyìí.